Àìsáyà 11:1-16
11 Ẹ̀ka igi+ kan máa yọ látinú kùkùté Jésè,+Èéhù+ kan látinú gbòǹgbò rẹ̀ sì máa so èso.
2 Ẹ̀mí Jèhófà máa bà lé e,+Ẹ̀mí ọgbọ́n+ àti ti òye,Ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára,+Ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà.
3 Ìbẹ̀rù Jèhófà máa jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.+
Kò ní gbé ìdájọ́ rẹ̀ ka ohun tó fojú rí,Kò sì ní gbé ìbáwí rẹ̀ ka ohun tó fetí gbọ́ lásán.+
4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé.
Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+Ó sì máa fi èémí* ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+
5 Òdodo ló máa jẹ́ àmùrè ìgbáròkó rẹ̀,Òtítọ́ ló sì máa jẹ́ àmùrè ìbàdí rẹ̀.+
6 Ìkookò máa bá ọ̀dọ́ àgùntàn gbé fúngbà díẹ̀,+Àmọ̀tẹ́kùn máa dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́,Ọmọ màlúù, kìnnìún* àti ẹran tó sanra á jọ wà pa pọ̀;*+Ọmọ kékeré á sì máa dà wọ́n.
7 Màlúù àti bíárì á jọ máa jẹun,Àwọn ọmọ wọn á sì jọ dùbúlẹ̀.
Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù.+
8 Ọmọ ẹnu ọmú máa ṣeré lórí ihò ṣèbé,Ọmọ tí wọ́n ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ sì máa fọwọ́ sí ihò ejò olóró.
9 Wọn ò ní fa ìpalára kankan,+Tàbí ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi,+Torí ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé,Bí omi ṣe ń bo òkun.+
10 Ní ọjọ́ yẹn, gbòǹgbò Jésè+ máa dúró bí àmì* fún àwọn èèyàn.+
Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè máa yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà,*+Ibi ìsinmi rẹ̀ sì máa di ológo.
11 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tún máa na ọwọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà, àwọn tó ṣẹ́ kù láti Ásíríà,+ Íjíbítì,+ Pátírọ́sì,+ Kúṣì,+ Élámù,+ Ṣínárì,* Hámátì àti àwọn erékùṣù òkun.+
12 Ó máa gbé àmì* kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ ó máa kó àwọn tó tú ká lára Júdà jọ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.+
13 Owú Éfúrémù máa pòórá,+Àwọn tó sì ń fi ẹ̀tanú hàn sí Júdà máa pa run.
Éfúrémù ò ní jowú Júdà,Júdà ò sì ní fi ẹ̀tanú hàn sí Éfúrémù.+
14 Wọ́n máa já ṣòòrò wálẹ̀ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́* àwọn Filísínì lápá ìwọ̀ oòrùn;Wọ́n jọ máa kó ẹrù àwọn ará Ìlà Oòrùn.
Wọ́n máa na ọwọ́ wọn sí* Édómù+ àti Móábù,+Àwọn ọmọ Ámónì sì máa di ọmọ abẹ́ wọn.+
15 Jèhófà máa pín* ibi tí òkun Íjíbítì ti ya wọ ilẹ̀,*+Ó sì máa fi ọwọ́ rẹ̀ lórí Odò.*+
Ó máa fi èémí* rẹ̀ tó ń jó nǹkan gbẹ kọ lu ọ̀gbàrá rẹ̀ méjèèje,*Ó sì máa mú kí àwọn èèyàn fi bàtà wọn rìn kọjá.
16 Ọ̀nà kan sì máa jáde+ láti Ásíríà fún àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ yòókù,+Bó ṣe rí fún Ísírẹ́lì ní ọjọ́ tó kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ẹ̀mí.”
^ Tàbí “Ó máa fi òdodo dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀.”
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Tàbí kó jẹ́, “Ọmọ màlúù àti kìnnìún á jọ máa jẹun.”
^ Tàbí “Àwọn orílẹ̀-èdè máa wá a.”
^ Tàbí “òpó tí a fi ṣe àmì.”
^ Ìyẹn, Babilóníà.
^ Tàbí “òpó tí a fi ṣe àmì.”
^ Ní Héb., “èjìká.”
^ Tàbí “Wọ́n máa mú kí agbára wọn dé.”
^ Tàbí kó jẹ́, “gbẹ.”
^ Ní Héb., “pín ahọ́n òkun Íjíbítì.”
^ Ìyẹn, odò Yúfírétì.
^ Tàbí “ẹ̀mí.”
^ Tàbí kó jẹ́, “pín in sí ọ̀gbàrá méje.”