Àìsáyà 50:1-11
50 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀+ ìyá yín tí mo lé lọ dà?
Àbí èwo nínú àwọn tí mo jẹ ní gbèsè ni mo tà yín fún?
Ẹ wò ó! Torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín+ ni mo ṣe tà yín,Mo sì lé ìyá yín lọ torí àwọn àṣìṣe yín.+
2 Kí ló wá dé tí kò sí ẹnì kankan níbí nígbà tí mo dé?
Kí ló dé tí ẹnì kankan ò dáhùn nígbà tí mo pè?+
Ṣé ọwọ́ mi kúrú jù láti rani pa dà ni,Àbí mi ò lágbára láti gbani sílẹ̀ ni?+
Wò ó! Mo bá òkun wí, ó sì gbẹ táútáú;+Mo sọ àwọn odò di aṣálẹ̀.+
Ẹja wọn jẹrà torí kò sí omi,Wọ́n sì kú torí òùngbẹ.
3 Mo fi ìṣúdùdù bo ọ̀run,+Mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀* wọ̀ wọ́n.”
4 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́,*+Kí n lè mọ bó ṣe yẹ kí n fi ọ̀rọ̀ tó yẹ* dá ẹni tó ti rẹ̀ lóhùn.*+
Ó ń jí mi ní àràárọ̀;Ó ń jí etí mi kí n lè fetí sílẹ̀ bí àwọn tí a kọ́.+
5 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti ṣí etí mi,Mi ò sì ya ọlọ̀tẹ̀.+
Mi ò yíjú sí òdìkejì.+
6 Mo tẹ́ ẹ̀yìn mi fún àwọn tó ń lù mí,Mo sì gbé ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tó fa irun tu títí ó fi dán.*
Mi ò fi ojú mi pa mọ́ fún àwọn ohun tó ń dójú tini àti itọ́.+
7 Àmọ́ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa ràn mí lọ́wọ́.+
Ìdí nìyẹn tí ìtìjú ò fi ní bá mi.
Ìdí nìyẹn tí mo fi ṣe ojú mi bí akọ òkúta,+Mo sì mọ̀ pé ojú ò ní tì mí.
8 Ẹni tó ń pè mí ní olódodo wà nítòsí.
Ta ló lè fẹ̀sùn kàn mí?*+
Jẹ́ ká jọ dìde dúró.*
Ta ló fẹ́ bá mi ṣe ẹjọ́?
Kó sún mọ́ mi.
9 Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa ràn mí lọ́wọ́.
Ta ló máa sọ pé mo jẹ̀bi?
Wò ó! Gbogbo wọn máa gbó bí aṣọ.
Òólá* ló máa jẹ wọ́n run.
10 Ta ló bẹ̀rù Jèhófà nínú yín,Tó sì ń fetí sí ohùn ìránṣẹ́ rẹ̀?+
Ta ló ti rìn nínú òkùnkùn biribiri láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan?
Kó gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Jèhófà, kó sì fara ti* Ọlọ́run rẹ̀.
11 “Ẹ wò ó! Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dá iná,Tí ẹ̀ ń mú kí iná ta pàrà,Ẹ máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín,Láàárín iná tí ẹ̀ ń mú kó ta pàrà.
Ohun tí ẹ máa gbà lọ́wọ́ mi nìyí:
Inú ìroragógó lẹ máa dùbúlẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Ní Héb., “fi ọ̀rọ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “fún ẹni tó ti rẹ̀ lókun.”
^ Tàbí “ahọ́n tí a kọ́ dáadáa.”
^ Tàbí “àwọn tó fa irùngbọ̀n tu.”
^ Tàbí “bá mi fà á.”
^ Tàbí “dojú kọ ara wa.”
^ Tàbí “Kòkòrò.”
^ Tàbí “gbára lé.”