Àìsáyà 63:1-19
63 Ta ló ń bọ̀ láti Édómù+ yìí,Tó ń bọ̀ láti Bósírà,+ tó wọ aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn yòò,*Tó wọ aṣọ tó dáa gan-an,Tó ń yan bọ̀ nínú agbára ńlá rẹ̀?
“Èmi ni, Ẹni tó ń fi òdodo sọ̀rọ̀,Ẹni tó lágbára gan-an láti gbani là.”
2 Kí ló dé tí aṣọ rẹ pọ́n,Kí ló sì dé tí ẹ̀wù rẹ dà bíi ti ẹni tó ń tẹ àjàrà ní ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì?+
3 “Èmi nìkan ni mo tẹ wáìnì nínú ọpọ́n.
Ìkankan nínú àwọn èèyàn náà ò sí lọ́dọ̀ mi.
Mò ń fi ìbínú tẹ̀ wọ́n ṣáá,Mo sì ń fi ìrunú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.+
Ẹ̀jẹ̀ wọn ta sára ẹ̀wù mi,Ó sì ti yí gbogbo aṣọ mi.
4 Torí pé ọjọ́ ẹ̀san wà lọ́kàn mi,+Ọdún àwọn tí mo tún rà sì ti dé.
5 Mo wò, àmọ́ kò sẹ́ni tó ṣèrànwọ́;Ẹnu yà mí pé kò sẹ́ni tó tì mí lẹ́yìn.
Apá mi wá mú ìgbàlà* wá fún mi,+Ìbínú mi sì tì mí lẹ́yìn.
6 Mo fi ìbínú tẹ àwọn èèyàn mọ́lẹ̀,Mo mú kí wọ́n mu ìrunú mi yó,+Mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sórí ilẹ̀.”
7 Màá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ ká yìn,Torí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa,+Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,Nínú àánú rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó lágbára.
8 Torí ó sọ pé: “Ó dájú pé èèyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kò ní di aláìṣòótọ́.”*+
Ó wá di Olùgbàlà wọn.+
9 Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.+
Ìránṣẹ́ òun fúnra rẹ̀* sì gbà wọ́n là.+
Ó tún wọn rà nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti ìyọ́nú rẹ̀,+Ó gbé wọn sókè, ó sì rù wọ́n ní gbogbo ìgbà àtijọ́.+
10 Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.+
Ó wá di ọ̀tá wọn,+Ó sì bá wọn jà.+
11 Wọ́n rántí àwọn ìgbà àtijọ́,Àwọn ọjọ́ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀:
“Ẹni tó mú wọn jáde látinú òkun dà,+ àwọn àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?+
Ẹni tó fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sínú rẹ̀ dà,+
12 Ẹni tó mú kí apá Rẹ̀ ológo bá ọwọ́ ọ̀tún Mósè lọ,+Ẹni tó pín omi níyà níwájú wọn,+Kó lè ṣe orúkọ tó máa wà títí láé fún ara rẹ̀,+
13 Ẹni tó mú kí wọ́n rìn gba inú omi tó ń ru gùdù,*Tó fi jẹ́ pé wọ́n rìn láìkọsẹ̀,Bí ẹṣin ní ìgbèríko?*
14 Bí ìgbà tí ẹran ọ̀sìn bá ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀,Ẹ̀mí Jèhófà mú kí wọ́n sinmi.”+
Bí o ṣe darí àwọn èèyàn rẹ nìyí,Kí o lè ṣe orúkọ tó gbayì* fún ara rẹ.+
15 Wo ilẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì rí iLáti ibùgbé rẹ mímọ́ àti ológo* tó ga.
Ìtara rẹ àti agbára rẹ dà,Ìyọ́nú rẹ tó ń ru sókè*+ àti àánú rẹ dà?+
A ti fà wọ́n sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi.
16 Torí ìwọ ni Bàbá wa;+Bí Ábúráhámù ò tiẹ̀ mọ̀ wá,Tí Ísírẹ́lì ò sì dá wa mọ̀,Ìwọ Jèhófà, ni Bàbá wa.
Olùtúnrà wa látìgbà àtijọ́ ni orúkọ rẹ.+
17 Jèhófà, kí ló dé tí o gbà ká* rìn gbéregbère kúrò ní àwọn ọ̀nà rẹ?
Kí ló dé tí o gbà kí* ọkàn wa le, tí a ò fi bẹ̀rù rẹ?+
Pa dà, torí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,Àwọn ẹ̀yà ogún rẹ.+
18 Ó jẹ́ ti àwọn èèyàn mímọ́ rẹ fúngbà díẹ̀.
Àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.+
19 Ó pẹ́ gan-an tí a ti dà bí àwọn tí o kò ṣàkóso wọn rí,Bí àwọn tí a ò fi orúkọ rẹ pè rí.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “aṣọ rẹ̀ pọ́n yòò.”
^ Tàbí “ìṣẹ́gun.”
^ Tàbí “já sí èké.”
^ Tàbí “Áńgẹ́lì iwájú rẹ̀.”
^ Tàbí “ibú omi.”
^ Tàbí “nínú aginjù?”
^ Tàbí “tó lẹ́wà.”
^ Tàbí “ẹlẹ́wà.”
^ Ní Héb., “Inú rẹ lọ́hùn-ún tó ń ru sókè.”
^ Tàbí “mú ká.”
^ Ní Héb., “mú kí.”