Àwọn Onídàájọ́ 9:1-57
9 Nígbà tó yá, Ábímélékì+ ọmọ Jerubáálì lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣékémù, ó sì sọ fún àwọn àti gbogbo ìdílé bàbá rẹ̀ àgbà* pé:
2 “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ bi gbogbo àwọn olórí* ní Ṣékémù pé, ‘Èwo ló dáa jù fún yín, pé kí gbogbo àádọ́rin (70) ọmọkùnrin Jerubáálì+ máa jọba lé yín lórí àbí kí ọkùnrin kan ṣoṣo máa jọba lé yín lórí? Ẹ má gbàgbé pé ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá.’”*
3 Àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ wá bá a sọ ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn olórí Ṣékémù, ọkàn wọn sì fẹ́ láti tẹ̀ lé Ábímélékì, torí wọ́n sọ pé: “Ọmọ ìyá wa ni.”
4 Wọ́n wá fún un ní àádọ́rin (70) ẹyọ fàdákà látinú ilé* Baali-bérítì,+ Ábímélékì sì fi gba àwọn ọkùnrin tí kò níṣẹ́ tí wọ́n sì ya aláfojúdi, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé e kiri.
5 Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé bàbá rẹ̀ ní Ọ́fírà,+ ó sì pa àwọn arákùnrin rẹ̀,+ àwọn ọmọ Jerubáálì, àádọ́rin (70) ọkùnrin, lórí òkúta kan. Jótámù, ọmọ Jerubáálì tó kéré jù nìkan ló ṣẹ́ kù, torí pé ó sá pa mọ́.
6 Gbogbo àwọn olórí Ṣékémù àti gbogbo Bẹti-mílò wá kóra jọ, wọ́n sì fi Ábímélékì jọba,+ nítòsí igi ńlá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó* tó wà ní Ṣékémù.
7 Nígbà tí wọ́n sọ fún Jótámù, ojú ẹsẹ̀ ló lọ dúró sórí Òkè Gérísímù,+ ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin olórí Ṣékémù kí Ọlọ́run lè fetí sí yín.
8 “Ìgbà kan wà tí àwọn igi fẹ́ lọ yan ọba tó máa jẹ lórí wọn. Wọ́n wá sọ fún igi ólífì pé, ‘Jọba lórí wa.’+
9 Ṣùgbọ́n igi ólífì sọ fún wọn pé, ‘Ṣé kí n wá fi òróró mi sílẹ̀,* èyí tí wọ́n fi ń yin Ọlọ́run àti èèyàn, kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi yòókù?’
10 Àwọn igi tún sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jọba lórí wa.’
11 Àmọ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ sọ fún wọn pé, ‘Ṣé kí n wá fi adùn mi àti èso dáadáa mi sílẹ̀, kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi yòókù?’
12 Lẹ́yìn náà, àwọn igi sọ fún igi àjàrà pé, ‘Wá jọba lórí wa.’
13 Igi àjàrà fún wọn lésì pé, ‘Ṣé kí n wá fi wáìnì tuntun mi tó ń mú kí Ọlọ́run àti èèyàn máa yọ̀ sílẹ̀, kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi?’
14 Níkẹyìn, gbogbo igi yòókù sọ fún igi ẹlẹ́gùn-ún pé, ‘Wá jọba lórí wa.’+
15 Ni igi ẹlẹ́gùn-ún bá sọ fún àwọn igi pé, ‘Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lẹ fẹ́ fi mí jọba lórí yín, ẹ wá sábẹ́ òjìji mi kí n lè dáàbò bò yín. Àmọ́ tí ẹ bá kọ̀, kí iná jáde látara igi ẹlẹ́gùn-ún kó sì jó àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì run.’
16 “Ṣé òótọ́ inú lẹ wá fi hùwà yìí, ṣé ohun tó tọ́ lẹ sì ṣe bí ẹ ṣe fi Ábímélékì jọba,+ ṣé ìwà rere lẹ hù sí Jerubáálì àti agbo ilé rẹ̀, ṣé ohun tó sì yẹ ẹ́ lẹ ṣe fún un?
17 Nígbà tí bàbá mi jà fún yín,+ ó fi ẹ̀mí* ara rẹ wewu, kó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ Mídíánì.+
18 Àmọ́ lónìí, ẹ ti dìde sí agbo ilé bàbá mi, ẹ sì pa àwọn ọmọ rẹ̀, àádọ́rin (70) ọkùnrin, lórí òkúta kan.+ Ẹ wá fi Ábímélékì, ọmọ ẹrúbìnrin rẹ̀,+ jọba lórí àwọn olórí Ṣékémù, torí pé arákùnrin yín ni.
19 Àní, tó bá jẹ́ pé òótọ́ inú lẹ fi hùwà yìí, tó sì jẹ́ ohun tó tọ́ lẹ ṣe sí Jerubáálì àti agbo ilé rẹ̀ lónìí, ẹ jẹ́ kí inú yín máa dùn torí Ábímélékì, kí inú tiẹ̀ náà sì máa dùn torí yín.
20 Àmọ́ tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí iná jáde wá látọ̀dọ̀ Ábímélékì, kó sì jó àwọn olórí Ṣékémù àti Bẹti-mílò+ run, kí iná sì jáde wá látọ̀dọ̀ àwọn olórí Ṣékémù àti Bẹti-mílò, kó sì jó Ábímélékì run.”+
21 Jótámù+ wá sá lọ sí Bíà, ó sì ń gbé ibẹ̀ torí Ábímélékì arákùnrin rẹ̀.
22 Ọdún mẹ́ta ni Ábímélékì fi jọba* lórí Ísírẹ́lì.
23 Ọlọ́run wá jẹ́ kí Ábímélékì àti àwọn olórí Ṣékémù bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ̀yìn síra wọn,* wọ́n sì dalẹ̀ Ábímélékì.
24 Èyí á jẹ́ kí ẹ̀san ké torí ìwà ìkà tí wọ́n hù sí àádọ́rin (70) ọmọ Jerubáálì, kí Ábímélékì arákùnrin wọn sì lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn torí pé ó pa wọ́n,+ kí àwọn olórí Ṣékémù náà lè jẹ̀bi torí pé wọ́n ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀.
25 Àwọn olórí Ṣékémù wá ní kí àwọn ọkùnrin lọ lúgọ dè é lórí àwọn òkè, gbogbo ẹni tó bá gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá ni wọ́n sì máa ń jà lólè. Nígbà tó yá, Ábímélékì gbọ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀.
26 Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sọdá sí Ṣékémù,+ àwọn olórí Ṣékémù sì fọkàn tán an.
27 Wọ́n jáde lọ sóko, wọ́n sì kórè èso inú àwọn ọgbà àjàrà wọn, wọ́n tẹ̀ ẹ́, wọ́n sì ṣe àjọyọ̀, lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sínú ilé ọlọ́run wọn,+ wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì gégùn-ún fún Ábímélékì.
28 Gáálì ọmọ Ébédì wá sọ pé: “Ta ni Ábímélékì, ta sì ni Ṣékémù tí a fi máa sìn ín? Ṣebí òun ni ọmọ Jerubáálì?+ Ṣebí Sébúlù ni kọmíṣọ́nnà rẹ̀? Ẹ máa sin àwọn ọkùnrin Hámórì, bàbá Ṣékémù! Àmọ́ kí ló dé tí a fi máa sin òun?
29 Ká ní àwọn èèyàn yìí wà lábẹ́ àṣẹ mi ni, ṣe ni ǹ bá yọ Ábímélékì nípò.” Ó wá sọ fún Ábímélékì pé: “Kó ọmọ ogun jọ sí i, kí o sì jáde wá.”
30 Nígbà tí Sébúlù ìjòyè ìlú náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Gáálì ọmọ Ébédì, inú bí i gidigidi.
31 Ó wá dọ́gbọ́n* ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé: “Wò ó! Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ti wà ní Ṣékémù báyìí, wọ́n sì fẹ́ kẹ̀yìn àwọn ará ìlú náà sí ọ.
32 Kí ìwọ àti àwọn ọkùnrin rẹ wá ní òru, kí ẹ sì lúgọ sínú oko.
33 Gbàrà tí oòrùn bá ti yọ ní àárọ̀, kí o tètè dìde, kí o sì gbógun ja ìlú náà; tí òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ bá sì wá bá ọ jà, ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe láti ṣẹ́gun rẹ̀.”*
34 Ábímélékì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá gbéra ní òru, wọ́n pínra sí àwùjọ mẹ́rin, wọ́n sì lúgọ láti gbógun ja Ṣékémù.
35 Nígbà tí Gáálì ọmọ Ébédì jáde lọ, tó sì dúró sí àbáwọ ẹnubodè ìlú náà, Ábímélékì àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde níbi tí wọ́n lúgọ sí.
36 Nígbà tí Gáálì rí àwọn èèyàn náà, ó sọ fún Sébúlù pé: “Wò ó! Àwọn èèyàn ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látorí àwọn òkè.” Àmọ́ Sébúlù sọ fún un pé: “Òjìji àwọn òkè lò ń rí tí wọ́n dà bí èèyàn.”
37 Lẹ́yìn náà, Gáálì sọ pé: “Wò ó! Àwọn èèyàn ń bọ̀ láti àárín ilẹ̀ náà, àwùjọ ọmọ ogun kan sì ń gba ọ̀nà igi ńlá Méónẹ́nímù bọ̀.”
38 Sébúlù fún un lésì pé: “Ṣebí ò ń fọ́nnu pé, ‘Ta ni Ábímélékì tí a fi máa sìn ín?’+ Ṣebí àwọn èèyàn tí o kọ̀ nìyí? Jáde lọ báyìí, kí o lọ bá wọn jà.”
39 Gáálì wá ṣáájú àwọn olórí Ṣékémù lọ, ó sì bá Ábímélékì jà.
40 Ábímélékì lé e, Gáálì sì sá fún un, òkú wá sùn lọ bẹẹrẹbẹ títí dé ibi àbáwọ ẹnubodè ìlú náà.
41 Ábímélékì wá ń gbé ní Árúmà, Sébúlù+ sì lé Gáálì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ní Ṣékémù.
42 Lọ́jọ́ kejì àwọn èèyàn náà jáde lọ sí oko, Ábímélékì sì gbọ́ nípa rẹ̀.
43 Ó wá kó àwọn èèyàn, ó sì pín wọn sí àwùjọ mẹ́ta, wọ́n sì lúgọ sínú oko. Nígbà tó rí àwọn èèyàn tó ń jáde látinú ìlú náà, ó gbéjà kò wọ́n, ó sì ṣá wọn balẹ̀.
44 Ábímélékì àti àwọn àwùjọ tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ bá lọ síwájú, wọ́n sì dúró síbi àbáwọ ẹnubodè ìlú ńlá náà, àmọ́ àwùjọ méjèèjì gbógun ja gbogbo àwọn tó wà nínú oko, wọ́n sì ṣá wọn balẹ̀.
45 Gbogbo ọjọ́ yẹn ni Ábímélékì fi bá ìlú náà jà, ó sì gbà á. Ó pa àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀, ó bi ìlú náà wó,+ ó sì da iyọ̀ síbẹ̀.
46 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ilé gogoro Ṣékémù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n lọ sínú ibi ààbò* ní ilé* Eli-bérítì.+
47 Gbàrà tí wọ́n sọ fún Ábímélékì pé gbogbo àwọn olórí ilé gogoro Ṣékémù ti kóra jọ,
48 Ábímélékì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gun Òkè Sálímónì lọ. Ábímélékì mú àáké kan dání, ó gé ẹ̀ka igi kan, ó sì gbé e lé èjìká rẹ̀, ó wá sọ fún àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ yára ṣe ohun tí ẹ rí i tí mo ṣe!”
49 Ni gbogbo àwọn èèyàn náà bá gé ẹ̀ka igi, wọ́n sì tẹ̀ lé Ábímélékì. Wọ́n wá kó àwọn ẹ̀ka igi náà ti ibi ààbò náà, wọ́n sì dáná sun ún. Bí gbogbo èèyàn ilé gogoro Ṣékémù ṣe kú nìyẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin àti obìnrin.
50 Ábímélékì wá lọ sí Tébésì; ó pàgọ́ ti Tébésì, ó sì gbà á.
51 Ilé gogoro kan tó ní ààbò wà ní àárín ìlú náà, ibẹ̀ ni gbogbo ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn olórí ìlú náà sá lọ. Wọ́n ti ara wọn mọ́ inú rẹ̀, wọ́n sì gun orí òrùlé ilé gogoro náà lọ.
52 Ábímélékì dé ilé gogoro náà, ó sì gbógun tì í. Ó sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé gogoro náà kó lè dáná sun ún.
53 Obìnrin kan wá ju ọmọ ọlọ lu Ábímélékì lórí, ó sì fọ́ agbárí rẹ̀.+
54 Ó bá yára pe ìránṣẹ́ rẹ̀ tó gbé àwọn ohun ìjà rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Fa idà rẹ yọ kí o sì pa mí, kí wọ́n má bàa sọ nípa mi pé, ‘Obìnrin ló pa á.’” Ìránṣẹ́ rẹ̀ wá gún un ní àgúnyọ, ó sì kú.
55 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì rí i pé Ábímélékì ti kú, gbogbo wọn pa dà sílé.
56 Bí Ọlọ́run ṣe mú ẹ̀san wá sórí Ábímélékì nìyẹn torí ìwà ibi tó hù sí bàbá rẹ̀ nígbà tó pa àwọn àádọ́rin (70) arákùnrin rẹ̀.+
57 Ọlọ́run tún mú kí gbogbo ibi tí àwọn ọkùnrin Ṣékémù ṣe pa dà sórí wọn. Bí ègún Jótámù+ ọmọ Jerubáálì+ ṣe wá sórí wọn nìyẹn.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “agbo ilé bàbá ìyá rẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “àwọn onílẹ̀.”
^ Ní Héb., “egungun àti ẹran ara yín ni mí.”
^ Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
^ Tàbí “ọwọ̀n.”
^ Tàbí “Ṣé kí n má so èso mọ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “fi ṣe olórí.”
^ Ní Héb., “rán ẹ̀mí burúkú sí àárín Ábímélékì àti àwọn olórí Ṣékémù.”
^ Tàbí “fi ọgbọ́n àrékérekè.”
^ Tàbí “ṣe ohun tí ọwọ́ rẹ bá ká sí i.”
^ Tàbí “ilé agbára.”
^ Tàbí “tẹ́ńpìlì.”