Émọ́sì 6:1-14

  • Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ kò mikàn (1-14)

    • Ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe; abọ́ wáìnì (4, 6)

6  “Àwọn tó dá ara wọn lójú* ní Síónì gbé! Àwọn tí ọkàn wọn balẹ̀ lórí òkè Samáríà,+Àwọn olókìkí èèyàn nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó gba iwájú,Àwọn tí ilé Ísírẹ́lì ń lọ sọ́dọ̀ wọn!   Ẹ ré kọjá sí Kálínè, kí ẹ sì wò. Ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hámátì Ńlá,+Kí ẹ sì lọ sí Gátì ti àwọn Filísínì. Ṣé wọ́n sàn ju àwọn ìjọba yìí,*Tàbí ṣé ilẹ̀ wọn tóbi ju tiyín lọ ni?   Ṣé ẹ̀ ń mú ọjọ́ àjálù kúrò lọ́kàn yín+Tí ẹ sì ń mú kí ìwà ipá jọba* láàárín yín?+   Wọ́n ń dùbúlẹ̀ sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe,+ wọ́n sì ń nà gbalaja sórí àga tìmùtìmù,+Wọ́n ń jẹ àwọn àgbò inú agbo ẹran àti àwọn ọmọ màlúù* tí wọ́n bọ́ sanra;+   Wọ́n ń kọ orin sí ìró háàpù,*+Bíi Dáfídì, wọ́n ṣe àwọn ohun èlò ìkọrin;+   Wọ́n ń fi abọ́ mu wáìnì+Wọ́n sì ń fi òróró tó dára jù lọ para. Àmọ́ àjálù tó dé bá Jósẹ́fù kò dùn wọ́n.*+   Nítorí náà, àwọn ló máa kọ́kọ́ lọ sí ìgbèkùn,+Àríyá aláriwo àwọn tó nà gbalaja sì máa dópin.   ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fi ara* rẹ̀ búra,’+ àní Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé,‘“Mo kórìíra ìgbéraga Jékọ́bù,+Mo sì kórìíra àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,+Màá sì fa ìlú náà àti ohun tó wà nínú rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.+  “‘“Bí ó bá sì ṣẹ́ ku ọkùnrin mẹ́wàá sínú ilé kan, àwọn náà máa kú. 10  Mọ̀lẹ́bí* kan á wá gbé wọn jáde, á sì sun wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan. Á kó egungun wọn jáde kúrò nínú ilé; á sì béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá wà ní àwọn yàrá inú pé, ‘Ṣé wọ́n ṣì kù lọ́dọ̀ rẹ?’ Ẹni náà á fèsì pé, ‘Kò sí ẹnì kankan!’ Nígbà náà, á sọ pé, ‘Dákẹ́! Nítorí kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká máa pe Jèhófà.’” 11  Nítorí Jèhófà ló ń pàṣẹ,+Á wó ilé ńlá lulẹ̀ di àlàpà,Á sì fọ́ ilé kékeré túútúú.+ 12  Ǹjẹ́ àwọn ẹṣin máa ń sáré lórí àpáta,Àbí ẹnikẹ́ni lè fi màlúù túlẹ̀ lórí rẹ̀? Nítorí ẹ ti sọ ìdájọ́ òdodo di igi onímájèlé,Ẹ sì ti sọ èso òdodo di iwọ.*+ 13  Ẹ̀ ń yọ̀ lórí nǹkan tí kò ní láárí,Ẹ sì ń sọ pé, “Ǹjẹ́ kì í ṣe okun wa ló mú ká di alágbára?”*+ 14  Nítorí náà, ẹ̀yin èèyàn ilé Ísírẹ́lì, màá gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí yín’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,‘Wọ́n á sì ni yín lára láti Lebo-hámátì*+ títí dé Àfonífojì Árábà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tí kò mikàn.”
Ó ṣe kedere pé àwọn ìjọba ilẹ̀ Júdà àti ti Ísírẹ́lì ló ń tọ́ka sí.
Ní Héb., “jókòó.”
Tàbí “àwọn akọ ọmọ màlúù.”
Tàbí “ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín.”
Ní Héb., “kò mú wọn ṣàìsàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Arákùnrin bàbá rẹ̀.”
Tàbí “ìkorò.”
Ní Héb., “la fi gba àwọn ìwo fún ara wa.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”