Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 13:1-18
13 Ó* sì dúró jẹ́ẹ́ lórí iyanrìn òkun.
Mo wá rí ẹranko kan+ tó ń jáde látinú òkun,+ ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje, adé dáyádémà* mẹ́wàá sì wà lórí àwọn ìwo rẹ̀, àmọ́ àwọn orúkọ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì wà ní àwọn orí rẹ̀.
2 Ẹranko tí mo rí sì dà bí àmọ̀tẹ́kùn, àmọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi ti bíárì, ẹnu rẹ̀ sì jọ ti kìnnìún. Dírágónì náà+ fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀, ó sì fún un ní àṣẹ tó pọ̀.+
3 Mo sì rí i, ó dà bíi pé ọgbẹ́ tó lè pa á wà ní ọ̀kan lára àwọn orí rẹ̀, àmọ́ ọgbẹ́ tó lè pa á náà ti jinná,+ gbogbo ayé tẹ̀ lé ẹranko náà, wọ́n sì ń kan sáárá sí i.
4 Wọ́n sì jọ́sìn dírágónì náà torí pé ó fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí jọ́sìn ẹranko yẹn pé: “Ta ló dà bí ẹranko náà, ta ló sì lè bá a jà?”
5 Ó fún un ní ẹnu tó ń sọ àwọn nǹkan ńláńlá àti ọ̀rọ̀ òdì, ó sì fún un ní àṣẹ tó máa lò fún oṣù méjìlélógójì (42).+
6 Ó la ẹnu rẹ̀, ó fi ń sọ̀rọ̀ òdì+ sí Ọlọ́run, kó lè sọ̀rọ̀ òdì nípa orúkọ rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀, títí kan àwọn tó ń gbé ní ọ̀run.+
7 A gbà á láyè láti bá àwọn ẹni mímọ́ jagun kó sì ṣẹ́gun wọn,+ a sì fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà, èèyàn, ahọ́n* àti orílẹ̀-èdè.
8 Gbogbo àwọn tó ń gbé ní ayé máa jọ́sìn rẹ̀. Látìgbà ìpìlẹ̀ ayé, a ò kọ orúkọ ẹnì kankan nínú wọn sínú àkájọ ìwé ìyè+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí wọ́n pa.+
9 Ẹnikẹ́ni tó bá ní etí, kí ó gbọ́.+
10 Tí ẹnikẹ́ni bá yẹ fún oko ẹrú, ó máa lọ sí oko ẹrú. Tí ẹnikẹ́ni bá máa fi idà pani,* a gbọ́dọ̀ fi idà pa á.+ Ibi tó ti gba pé káwọn ẹni mímọ́+ ní ìfaradà+ àti ìgbàgbọ́+ nìyí.
11 Lẹ́yìn náà, mo rí ẹranko míì tó ń jáde látinú ayé, ó ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bíi dírágónì.+
12 Ó ń lo gbogbo àṣẹ tí ẹranko àkọ́kọ́+ ní lójú rẹ̀. Ó sì ń mú kí ayé àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ jọ́sìn ẹranko àkọ́kọ́ náà, tí ọgbẹ́ rẹ̀ tó lè pani ti jinná.+
13 Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó lágbára, kódà ó ń mú kí iná wá láti ọ̀run sí ayé lójú aráyé.
14 Ó ń ṣi àwọn tó ń gbé ayé lọ́nà, torí àwọn iṣẹ́ àmì tí a gbà á láyè láti ṣe lójú ẹranko náà, bó ṣe ń sọ fún àwọn tó ń gbé ayé pé kí wọ́n ṣe ère+ ẹranko tó ní ọgbẹ́ idà, síbẹ̀ tó sọjí.+
15 A gbà á láyè pé kó fún ẹranko náà ní èémí,* kí ère ẹranko náà lè sọ̀rọ̀, kó sì mú kí wọ́n pa gbogbo àwọn tó kọ̀ láti jọ́sìn ère ẹranko náà.
16 Ó sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún gbogbo èèyàn—ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ẹni tó wà lómìnira àti ẹrú—pé kí wọ́n sàmì sí ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí iwájú orí wọn,+
17 àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àfi ẹni tó bá ní àmì náà, orúkọ+ ẹranko náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.+
18 Ibi tó ti gba ọgbọ́n nìyí: Kí ẹni tó ní òye ṣírò nọ́ńbà ẹranko náà, torí pé nọ́ńbà èèyàn ni,* nọ́ńbà rẹ̀ sì ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666).+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, dírágónì náà.
^ Tàbí “àwọn ìwérí ọba.”
^ Tàbí “èdè.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Tí a bá máa fi idà pa ẹnikẹ́ni.”
^ Tàbí “ẹ̀mí.”
^ Tàbí “nọ́ńbà aráyé.”