Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 18:1-24

  • “Bábílónì Ńlá” ṣubú (1-8)

    • “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi” (4)

  • Wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ìṣubú Bábílónì (9-19)

  • Wọ́n ń yọ̀ ní ọ̀run torí Bábílónì ṣubú (20)

  • A máa ju Bábílónì sínú òkun bí òkúta (21-24)

18  Lẹ́yìn èyí, mo rí áńgẹ́lì míì tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó ní àṣẹ tó pọ̀, ògo rẹ̀ sì mú kí ayé mọ́lẹ̀ kedere.  Ó sì fi ohùn tó le ké jáde pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú,+ ó sì ti di ibi tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbé àti ibi tí gbogbo ẹ̀mí àìmọ́* àti gbogbo ẹyẹ àìmọ́ tí a kórìíra ń lúgọ sí!+  Gbogbo orílẹ̀-èdè ti kó sọ́wọ́ rẹ̀ torí wáìnì ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* ti ìṣekúṣe* rẹ̀,+ àwọn ọba ayé sì bá a ṣe ìṣekúṣe,+ àwọn oníṣòwò* ayé sì di ọlọ́rọ̀ torí ó ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ lọ́nà tó bùáyà, kò sì nítìjú.”  Mo gbọ́ ohùn míì láti ọ̀run, ó sọ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi,+ tí ẹ kò bá fẹ́ pín nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu rẹ̀.+  Torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ga dé ọ̀run,+ Ọlọ́run sì ti rántí àwọn ìwà àìṣòdodo tó hù.*+  Bó ṣe ṣe sí àwọn míì ni kí ẹ ṣe sí i,+ àní ìlọ́po méjì ohun tó ṣe ni kí ẹ san fún un;+ nínú ife+ tó fi po àdàlù, kí ẹ po ìlọ́po méjì àdàlù náà fún un.+  Bó ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo tó àti bó ṣe gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ láìnítìjú tó, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ jẹ́ kó joró, kó sì ṣọ̀fọ̀ tó. Torí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì í ṣe opó, mi ò sì ní ṣọ̀fọ̀ láé.’+  Ìdí nìyẹn tí àwọn ìyọnu rẹ̀ fi máa dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, a sì máa fi iná sun ún pátápátá,+ torí pé Jèhófà* Ọlọ́run, ẹni tó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.+  “Àwọn ọba ayé tó bá a ṣe ìṣekúṣe,* tí wọ́n sì jọ gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ láìnítìjú máa sunkún, ìbànújẹ́ nítorí rẹ̀ sì máa mú kí wọ́n lu ara wọn, tí wọ́n bá rí èéfín rẹ̀ nígbà tó ń jóná. 10  Wọ́n máa dúró ní òkèèrè torí bó ṣe ń joró bà wọ́n lẹ́rù, wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o, Bábílónì, ìwọ ìlú ńlá,+ ìwọ ìlú tó lágbára, torí ìdájọ́ rẹ dé ní wákàtí kan!’ 11  “Bákan náà, àwọn oníṣòwò ayé ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, torí kò sí ẹni tó máa ra ọjà wọn tó kún fọ́fọ́ mọ́, 12  ọjà tó kún fún wúrà, fàdákà, àwọn òkúta iyebíye, péálì, aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* aṣọ aláwọ̀ pọ́pù, sílíìkì àti aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò; àti gbogbo ohun tí wọ́n fi igi tó ń ta sánsán ṣe; àti oríṣiríṣi àwọn ohun tí wọ́n fi eyín erin ṣe àtàwọn èyí tí wọ́n fi oríṣiríṣi igi iyebíye ṣe àti bàbà, irin pẹ̀lú òkúta mábù; 13  àti igi sínámónì, èròjà tó ń ta sánsán ti Íńdíà, tùràrí, òróró onílọ́fínńdà, oje igi tùràrí, wáìnì, òróró ólífì, ìyẹ̀fun tó kúnná, àlìkámà,* màlúù, àgùntàn, àwọn ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ẹrù, àwọn ẹrú àti ẹ̀mí* àwọn èèyàn. 14  Àní èso tó dáa tó wù ọ́* ti kúrò lọ́wọ́ rẹ pẹ̀lú gbogbo nǹkan aládùn, bẹ́ẹ̀ náà làwọn nǹkan tó dáa gan-an ti lọ mọ́ ẹ lọ́wọ́, o ò sì ní rí wọn mọ́ láé. 15  “Àwọn oníṣòwò tó ta àwọn nǹkan yìí, tí wọ́n di ọlọ́rọ̀ láti ara rẹ̀, máa dúró ní òkèèrè torí bó ṣe ń joró bà wọ́n lẹ́rù, wọ́n máa sunkún, wọ́n sì máa ṣọ̀fọ̀, 16  wọ́n á sọ pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe fún ìlú ńlá náà o, tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* tó ní àwọ̀ pọ́pù àti àwọ̀ pupa, tí wọ́n sì fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ oníwúrà ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ dáadáa, pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye àti péálì,+ 17  torí pé ọrọ̀ tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ti pa run ní wákàtí kan!’ “Gbogbo ọ̀gá àwọn atukọ̀ àti gbogbo àwọn tó máa ń wọkọ̀ òkun àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ àti gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lórí òkun, dúró ní òkèèrè, 18  wọ́n ké jáde bí wọ́n ṣe rí èéfín rẹ̀ nígbà tó jóná, wọ́n sọ pé: ‘Ìlú wo ló dà bí ìlú ńlá náà?’ 19  Wọ́n da eruku sórí ara wọn, wọ́n ké jáde, wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọ pé: ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe fún ìlú ńlá náà o, ìlú tí gbogbo àwọn tó ní ọkọ̀ òkun di ọlọ́rọ̀ látinú ọrọ̀ rẹ̀, torí pé ó ti pa run ní wákàtí kan!’+ 20  “Máa yọ̀ nítorí rẹ̀, ìwọ ọ̀run+ àti ẹ̀yin ẹni mímọ́,+ ẹ̀yin àpọ́sítélì àti wòlíì, torí pé Ọlọ́run ti kéde ìdájọ́ sórí rẹ̀ nítorí yín!”+ 21  Áńgẹ́lì kan tó lágbára wá gbé òkúta kan tó dà bí ọlọ ńlá sókè, ó sì jù ú sínú òkun, ó ní: “Báyìí la ṣe máa yára ju Bábílónì ìlú ńlá náà sísàlẹ̀, a ò sì ní rí i mọ́ láé.+ 22  A ò sì ní gbọ́ ìró àwọn akọrin tí wọ́n ń ta háàpù sí orin tí wọ́n ń kọ nínú rẹ mọ́ àti ìró àwọn olórin, àwọn tó ń fun fèrè àti àwọn tó ń fun kàkàkí. A ò sì ní rí oníṣẹ́ ọnà kankan tó ń ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí nínú rẹ mọ́ láé, bẹ́ẹ̀ la ò ní gbọ́ ìró ọlọ kankan nínú rẹ mọ́ láé. 23  Iná fìtílà kankan ò ní tàn nínú rẹ mọ́ láé, a ò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé; torí àwọn ọkùnrin tó wà nípò gíga ní ayé ni àwọn oníṣòwò rẹ, ìwà ìbẹ́mìílò+ rẹ sì ṣi gbogbo orílẹ̀-èdè lọ́nà. 24  Àní inú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́+ àti ti gbogbo àwọn tí wọ́n pa ní ayé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “èémí; èémí àmíjáde; ọ̀rọ̀ onímìísí.”
Tàbí “ìbínú.”
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àwọn oníṣòwò tó ń rìnrìn àjò.”
Tàbí “àwọn ọ̀ràn tó dá.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “tí ọkàn rẹ fẹ́.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”