Ìsíkíẹ́lì 18:1-32
18 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2 “Kí ni òwe tí ẹ̀ ń pa ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì yìí túmọ̀ sí, pé, ‘Àwọn bàbá ti jẹ èso àjàrà tí kò pọ́n, àmọ́ àwọn ọmọ ni eyín ń kan’?+
3 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘ẹ ò ní pa òwe yìí mọ́ ní Ísírẹ́lì.
4 Wò ó! Gbogbo ọkàn,* tèmi ni wọ́n. Bí ọkàn bàbá ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ. Ọkàn* tó bá ṣẹ̀ ni yóò kú.
5 “‘Ká ní ọkùnrin kan wà tó jẹ́ olódodo, tó sì máa ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ.
6 Kì í jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òrìṣà lórí àwọn òkè;+ kò gbójú lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* ilé Ísírẹ́lì, kì í bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn+ tàbí kó bá obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù ní àṣepọ̀;+
7 kì í ni ẹnikẹ́ni lára,+ àmọ́ ó máa ń dá ohun tí ẹni tó jẹ ẹ́ ní gbèsè fi ṣe ìdúró pa dà fún un;+ kì í ja ẹnikẹ́ni lólè,+ àmọ́ ó máa ń gbé oúnjẹ rẹ̀ fún ẹni tí ebi ń pa,+ ó sì máa ń da aṣọ bo ẹni tó wà níhòòhò;+
8 kì í yáni lówó èlé, kì í sì í gba èlé gọbọi lórí owó tó yáni,+ kì í rẹ́ni jẹ;+ ẹjọ́ òdodo ló máa ń dá láàárín ẹni méjì;+
9 ó ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ó sì ń tẹ̀ lé ìdájọ́ mi kó lè jẹ́ olóòótọ́. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ olódodo, ó sì dájú pé yóò máa wà láàyè,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
10 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ó ní ọmọ kan tó ń jalè+ tàbí tó jẹ́ apààyàn*+ tàbí tó ń ṣe èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí
11 (bí bàbá rẹ̀ ò bá tiẹ̀ lọ́wọ́ nínú nǹkan wọ̀nyí), tó ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òrìṣà lórí àwọn òkè, tó ń bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn,
12 tó ń ni aláìní àti tálákà lára,+ tó ń jalè, tí kì í dá ohun tí wọ́n fi ṣe ìdúró pa dà, tó gbójú lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin,+ tó ń ṣe àwọn ohun ìríra,+
13 tó ń gba èlé gọbọi lórí owó tó yáni, tó sì ń yáni lówó èlé,+ ọmọ náà kò ní wà láàyè. Ṣe ni wọ́n máa pa á, torí gbogbo ohun ìríra tó ti ṣe. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní ọrùn rẹ̀.
14 “Àmọ́ ká ní bàbá kan ní ọmọ, tó ń rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí bàbá rẹ̀ ti dá, àmọ́ tí kò ṣe bíi bàbá rẹ̀, bó tiẹ̀ ń rí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà.
15 Kì í jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òrìṣà lórí àwọn òkè; kò gbójú lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin ilé Ísírẹ́lì, kì í bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn;
16 kì í ni ẹnikẹ́ni lára, kì í gbẹ́sẹ̀ lé ohun tí wọ́n fi ṣe ìdúró; kì í jalè rárá; ó máa ń gbé oúnjẹ rẹ̀ fún ẹni tí ebi ń pa, ó sì máa ń da aṣọ bo ẹni tó wà níhòòhò;
17 kì í ni àwọn aláìní lára; kì í gba èlé gọbọi lórí owó tó yáni, kì í sì í yáni lówó èlé; ó ń tẹ̀ lé ìdájọ́ mi; ó sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀. Ó dájú pé yóò máa wà láàyè.
18 Àmọ́ torí pé oníjìbìtì ni bàbá rẹ̀, tó ja arákùnrin rẹ̀ lólè, tó sì ṣe ohun tí kò dáa láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, bàbá náà yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
19 “‘Àmọ́ ìwọ á sọ pé: “Kí nìdí tí ọmọ ò fi ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀?” Nítorí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó jẹ́ òdodo, tó pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tó sì ń tẹ̀ lé e, ó dájú pé yóò máa wà láàyè.+
20 Ọkàn* tó bá ṣẹ̀ ni yóò kú.+ Ọmọ ò ní ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀, bàbá ò sì ní ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ rẹ. Olódodo máa jèrè òdodo rẹ̀, ẹni burúkú sì máa jèrè ìwà burúkú rẹ̀.+
21 “‘Àmọ́, bí ẹni burúkú bá yí pa dà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, tó ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tó ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo, ó dájú pé yóò máa wà láàyè. Kò ní kú.+
22 Mi ò ní ka* gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sí i lọ́rùn.+ Yóò máa wà láàyè torí ó ń ṣe òdodo.’+
23 “‘Ǹjẹ́ inú mi máa ń dùn sí ikú ẹni burúkú?’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà kó sì máa wà láàyè?’+
24 “‘Àmọ́ tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa,* tó ń ṣe gbogbo ohun ìríra tí àwọn ẹni burúkú ń ṣe, ǹjẹ́ ó máa wà láàyè? Mi ò ní rántí ìkankan nínú gbogbo iṣẹ́ òdodo rẹ̀.+ Yóò kú torí ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀ àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá.+
25 “‘Àmọ́ ẹ̀yin á sọ pé: “Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́.”+ Jọ̀ọ́ fetí sílẹ̀, ìwọ ilé Ísírẹ́lì! Ṣé ọ̀nà mi ni ò tọ́?+ Ṣebí ọ̀nà tiyín ni kò tọ́?+
26 “‘Tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa, tó sì kú nítorí àìdáa tó ṣe, ikú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló kú.
27 “‘Àmọ́ tí ẹni burúkú bá yí pa dà kúrò nínú iṣẹ́ ibi tó ti ṣe, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo, ó máa dá ẹ̀mí* rẹ̀ sí.+
28 Tó bá sì wá mọ̀, tó sì yí pa dà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, ó dájú pé yóò máa wà láàyè. Kò ní kú.
29 “‘Àmọ́ ilé Ísírẹ́lì á sọ pé: “Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́.” Ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ṣé òótọ́ ni pé ọ̀nà mi ni ò tọ́?+ Ṣebí ọ̀nà tiyín ni kò tọ́?’
30 “‘Torí náà, màá fi ìwà yín dá kálukú yín lẹ́jọ́,+ ilé Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ẹ yí pa dà, àní ẹ yí pa dà pátápátá kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí wọ́n má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó máa mú kí ẹ jẹ̀bi.
31 Ẹ jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín,+ kí ẹ sì ní* ọkàn tuntun àti ẹ̀mí tuntun.+ Ṣé ó wá yẹ kí ẹ kú,+ ilé Ísírẹ́lì?’
32 “‘Inú mi ò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Torí náà, ẹ yí pa dà, kí ẹ sì máa wà láàyè.’”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Ẹni; Èèyàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
^ Ní Héb., “tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.”
^ Tàbí “Ẹni; Èèyàn.”
^ Ní Héb., “rántí.”
^ Tàbí “tí kò sì ṣe òdodo.”
^ Tàbí “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “ṣe ọkàn tuntun àti ẹ̀mí tuntun fún ara yín.”