Diutarónómì 4:1-49

  • Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn (1-14)

    • Wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe (9)

  • Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa jọ́sìn òun nìkan (15-31)

  • Kò sí Ọlọ́run míì àfi Jèhófà (32-40)

  • Àwọn ìlú ààbò ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (41-43)

  • Ó fún Ísírẹ́lì ní Òfin (44-49)

4  “Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ fetí sí àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń kọ́ yín láti pa mọ́, kí ẹ lè máa wà láàyè,+ kí ẹ lè wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín máa fún yín, kí ẹ sì gbà á.  Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi kún ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ yọ kúrò lára rẹ̀,+ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí mò ń pa láṣẹ fún yín.  “Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀rọ̀ Báálì Péórì; gbogbo ọkùnrin tó tọ Báálì Péórì+ lẹ́yìn ni Jèhófà Ọlọ́run yín pa run kúrò láàárín yín.  Àmọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ rọ̀ mọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ wà láàyè lónìí.  Ẹ wò ó, mo ti kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́,+ bí Jèhófà Ọlọ́run mi ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ máa gbà.  Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́,+ torí èyí máa fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n+ àti olóye+ lójú àwọn èèyàn tó máa gbọ́ nípa gbogbo ìlànà yìí, wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé ọlọ́gbọ́n àti olóye ni àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ńlá yìí.’+  Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni àwọn ọlọ́run rẹ̀ sún mọ́ ọn bíi ti Jèhófà Ọlọ́run wa nígbàkigbà tí a bá ké pè é?+  Orílẹ̀-èdè ńlá wo ló sì ní àwọn ìlànà òdodo àti àwọn ìdájọ́ bíi ti gbogbo Òfin yìí tí mò ń fi sí iwájú yín lónìí?+  “Ṣáà máa kíyè sára, kí o sì máa ṣọ́ra gan-an,* kí o má bàa gbàgbé àwọn ohun tí o fi ojú rẹ rí, kí wọ́n má bàa kúrò lọ́kàn rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Kí o sì tún jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ mọ̀ nípa wọn.+ 10  Ní ọjọ́ tí o dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Hórébù, Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn èèyàn náà jọ sọ́dọ̀ mi kí n lè mú kí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi,+ kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi+ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi wà láàyè lórí ilẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ àwọn ọmọ wọn.’+ 11  “Ẹ wá sún mọ́ tòsí òkè náà, ẹ sì dúró sí ìsàlẹ̀ rẹ̀, òkè náà sì ń yọ iná títí dé ọ̀run;* òkùnkùn ṣú, ìkùukùu* yọ, ojú ọjọ́ sì ṣú dùdù.+ 12  Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá yín sọ̀rọ̀ látinú iná náà.+ Ẹ̀ ń gbọ́ tí ẹnì kan ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò rí ẹnì kankan,+ ohùn nìkan lẹ̀ ń gbọ́.+ 13  Ó sì kéde májẹ̀mú rẹ̀ fún yín,+ èyí tó pa láṣẹ fún yín pé kí ẹ máa pa mọ́, ìyẹn Òfin Mẹ́wàá.*+ Lẹ́yìn náà, ó kọ ọ́ sórí wàláà òkúta méjì.+ 14  Nígbà yẹn, Jèhófà pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí ẹ ó máa pa mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà. 15  “Torí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi,* torí pé ẹ ò rí ẹnikẹ́ni lọ́jọ́ tí Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárín iná náà, 16  kí ẹ má bàa hùwàkiwà nípa gbígbẹ́ ère èyíkéyìí tó jọ ohunkóhun fún ara yín, ohun tó rí bí akọ tàbí abo,+ 17  ohun tó rí bí ẹranko èyíkéyìí ní ayé, bí ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run,+ 18  bí ohunkóhun tó ń rákò lórí ilẹ̀ tàbí tó rí bí ẹja èyíkéyìí nínú omi lábẹ́ ilẹ̀.+ 19  Tí o bá wá yíjú sókè wo ọ̀run, tí o sì rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, o ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn rẹ fà sí wọn débi pé o máa forí balẹ̀ fún wọn, tí o sì máa sìn wọ́n.+ Gbogbo èèyàn lábẹ́ ọ̀run ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi wọ́n fún. 20  Àmọ́ ẹ̀yin ni Jèhófà mú jáde nínú iná ìléru tí wọ́n ti ń yọ́ irin, kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, kí ẹ lè di ohun ìní tirẹ̀*+ bí ẹ ṣe jẹ́ lónìí. 21  “Jèhófà bínú sí mi torí yín,+ ó sì búra pé mi ò ní sọdá Jọ́dánì, mi ò sì ní wọ ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín láti jogún.+ 22  Ilẹ̀ yìí ni màá kú sí; mi ò ní sọdá Jọ́dánì,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin máa sọdá, ẹ sì máa gba ilẹ̀ dáradára náà. 23  Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa gbàgbé májẹ̀mú tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yín dá,+ ẹ má sì gbẹ́ ère fún ara yín, ohun tó rí bí ohunkóhun tí Jèhófà Ọlọ́run yín kà léèwọ̀ fún yín.+ 24  Torí iná tó ń jóni run ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ Ọlọ́run tó fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo.+ 25  “Tí ẹ bá bí àwọn ọmọ, tí ẹ sì ní àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà, àmọ́ tí ẹ wá ṣe ohun tó lè fa ìparun, tí ẹ gbẹ́ ère+ èyíkéyìí, tí ẹ sì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run yín láti mú un bínú,+ 26  mo fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí ta kò yín lónìí, pé ó dájú pé kíákíá lẹ máa pa run ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti lọ gbà. Ẹ ò ní pẹ́ níbẹ̀, ṣe lẹ máa pa run pátápátá.+ 27  Jèhófà máa tú yín ká sáàárín àwọn èèyàn,+ díẹ̀ nínú yín ló sì máa ṣẹ́ kù+ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà máa lé yín lọ. 28  Àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe lẹ máa sìn níbẹ̀, èyí tí àwọn èèyàn fi ọwọ́ ṣe,+ àwọn ọlọ́run tí kò lè ríran, tí kò lè gbọ́ràn, tí kò lè jẹun, tí kò sì lè gbóòórùn. 29  “Tí ẹ bá wá Jèhófà Ọlọ́run yín níbẹ̀, ó dájú pé ẹ máa rí i+ tí ẹ bá fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá a.+ 30  Tí wàhálà tó le gan-an bá dé bá ọ, tí gbogbo nǹkan yìí sì wá ṣẹlẹ̀ sí ọ, wàá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, wàá sì fetí sí ohùn rẹ̀.+ 31  Torí Ọlọ́run aláàánú ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ Kò ní pa ọ́ tì, kò ní pa ọ́ run, kò sì ní gbàgbé májẹ̀mú tó bá àwọn baba ńlá rẹ dá.+ 32  “Béèrè báyìí nípa ìgbà àtijọ́, ṣáájú ìgbà tìẹ, láti ọjọ́ tí Ọlọ́run ti dá èèyàn sí ayé; wádìí láti ìpẹ̀kun kan ọ̀run sí ìpẹ̀kun kejì. Ṣé irú nǹkan àgbàyanu bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí àbí ẹ ti gbọ́ ohunkóhun tó jọ ọ́ rí?+ 33  Ǹjẹ́ àwọn èèyàn míì gbọ́ ohùn Ọlọ́run tó ń sọ̀rọ̀ látinú iná bí ẹ ṣe gbọ́ ọ, tí ẹ ò sì kú?+ 34  Àbí Ọlọ́run ti gbìyànjú láti mú orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ látinú orílẹ̀-èdè míì pẹ̀lú àwọn ìdájọ́,* àmì, iṣẹ́ ìyanu,+ ogun,+ pẹ̀lú ọwọ́ agbára,+ apá tó nà jáde, tó sì ṣe àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe fún yín ní Íjíbítì níṣojú yín? 35  Ẹ̀yin fúnra yín ti rí nǹkan wọ̀nyí kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́;+ kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan.+ 36  Ó mú kí o gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run, kó lè tọ́ ọ sọ́nà, ó mú kí o rí iná ńlá rẹ̀ ní ayé, o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú iná.+ 37  “Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn baba ńlá rẹ, ó sì yan àtọmọdọ́mọ* wọn lẹ́yìn wọn,+ ó fi agbára ńlá rẹ̀ mú ọ kúrò ní Íjíbítì pẹ̀lú ojú rẹ̀ lára rẹ. 38  Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò níwájú rẹ, kó lè mú ọ wọlé, kó sì fún ọ ní ilẹ̀ wọn kí o lè jogún rẹ̀, bó ṣe rí lónìí.+ 39  Torí náà, kí o mọ̀ lónìí, kí o sì fi sọ́kàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.+ Kò sí ẹlòmíì.+ 40  Kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti àwọn àṣẹ rẹ̀, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.”+ 41  Nígbà yẹn, Mósè ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì.+ 42  Tí apààyàn èyíkéyìí bá ṣèèṣì pa ọmọnìkejì rẹ̀, tí kì í sì í ṣe pé ó kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀,+ kó sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kí wọ́n má bàa pa á.+ 43  Àwọn ìlú náà ni Bésérì+ ní aginjù, lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú,* fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì fún àwọn ọmọ Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì fún àwọn ọmọ Mánásè.+ 44  Èyí ni Òfin+ tí Mósè fi lélẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 45  Èyí ni àwọn ìrántí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì,+ 46  ní agbègbè Jọ́dánì, ní àfonífojì tó dojú kọ Bẹti-péórì,+ ní ilẹ̀ Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì,+ ẹni tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì.+ 47  Wọ́n sì gba ilẹ̀ rẹ̀ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì, àwọn ọba Ámórì méjèèjì, tí wọ́n wà ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, 48  láti Áróérì,+ èyí tó wà létí Àfonífojì Áánónì, títí dé Òkè Síónì, ìyẹn Hámónì,+ 49  àti gbogbo Árábà, ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, títí lọ dé Òkun Árábà,* ní ìsàlẹ̀ àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “kí o sì máa ṣọ́ ọkàn rẹ dáadáa.”
Ní Héb., “títí dé àárín àwọn ọ̀run.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá.”
Tàbí “ẹ ṣọ́ ọkàn yín gidigidi.”
Tàbí “ogún rẹ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ìgbẹ́jọ́.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
Ìyẹn, Òkun Iyọ̀ tàbí Òkun Òkú.