Jẹ́nẹ́sísì 26:1-35
26 Ìyàn mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ sí ìyàn tó kọ́kọ́ mú nígbà ayé Ábúráhámù.+ Ísákì lọ sọ́dọ̀ Ábímélékì ọba àwọn Filísínì, ní Gérárì.
2 Jèhófà sì fara hàn án, ó sọ pé: “Má lọ sí Íjíbítì. Máa gbé ní ilẹ̀ tí mo fún ọ.
3 Máa gbé ilẹ̀+ yìí bí àjèjì, màá wà pẹ̀lú rẹ, màá sì bù kún ọ torí pé ìwọ àti ọmọ* rẹ ni màá fún ní gbogbo ilẹ̀+ yìí, màá sì ṣe ohun tí mo búra fún Ábúráhámù+ bàbá rẹ pé:
4 ‘Màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,+ màá sì fún ọmọ* rẹ ní gbogbo ilẹ̀+ yìí; gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò sì gba ìbùkún fún ara wọn+ nípasẹ̀ ọmọ* rẹ,’
5 torí pé Ábúráhámù fetí sí ohùn mi, ó ń ṣe ohun tí mo fẹ́, ó ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà mi àti àwọn òfin mi.”+
6 Ísákì sì ń gbé ní Gérárì.+
7 Tí àwọn ọkùnrin ibẹ̀ bá ń béèrè nípa ìyàwó rẹ̀, ó máa ń sọ pé: “Àbúrò+ mi ni.” Ẹ̀rù ń bà á láti sọ pé “Ìyàwó mi ni,” nítorí ó sọ pé, “Àwọn ọkùnrin ibẹ̀ lè pa mí torí Rèbékà,” torí ó rẹwà gan-an.+
8 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Ábímélékì ọba àwọn Filísínì ń wo ìta látojú fèrèsé,* ó sì rí Ísákì tó ń bá Rèbékà ìyàwó rẹ̀ tage.*+
9 Ni Ábímélékì bá pe Ísákì, ó sì sọ pé: “Ìyàwó rẹ ni obìnrin yìí! Kí nìdí tó o fi sọ pé, ‘Àbúrò mi ni’?” Ísákì wá fèsì pé: “Ẹ̀rù ló bà mí, kí n má bàa kú torí rẹ̀+ ni mo ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”
10 Àmọ́ Ábímélékì sọ pé: “Kí lo ṣe sí wa yìí?+ Ọ̀kan nínú àwọn èèyàn yìí ì bá ti bá ìyàwó rẹ sùn, o ò bá sì ti mú ká jẹ̀bi!”+
11 Ábímélékì wá sọ fún gbogbo èèyàn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí àti ìyàwó rẹ̀, ó dájú pé ó máa kú!”
12 Ísákì bẹ̀rẹ̀ sí í dá oko ní ilẹ̀ náà. Lọ́dún yẹn, ó kórè ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) ohun tó gbìn, torí Jèhófà ń bù kún un.+
13 Ọkùnrin náà wá ní ọrọ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì ń ròkè sí i títí ọrọ̀ rẹ̀ fi pọ̀ gan-an.
14 Ó ní àwọn agbo àgùntàn, ọ̀wọ́ màlúù àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìránṣẹ́,+ àmọ́ àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara rẹ̀.
15 Torí náà, àwọn Filísínì rọ iyẹ̀pẹ̀ dí gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù+ bàbá rẹ̀ gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀.
16 Ábímélékì wá sọ fún Ísákì pé: “Kúrò ní ìlú wa, torí o ti lágbára gan-an jù wá lọ.”
17 Ísákì ṣí kúrò níbẹ̀, ó lọ pàgọ́ sí àfonífojì Gérárì,+ ó sì ń gbé ibẹ̀.
18 Ísákì tún àwọn kànga náà gbẹ́, ìyẹn àwọn kànga tí wọ́n gbẹ́ nígbà ayé Ábúráhámù bàbá rẹ̀ àmọ́ tí àwọn Filísínì dí pa lẹ́yìn ikú+ Ábúráhámù, ó sì pè wọ́n ní orúkọ tí bàbá rẹ̀ sọ wọ́n.+
19 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ísákì ń gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n rí omi tó mọ́ níbẹ̀.
20 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn Gérárì wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísákì jà, wọ́n ń sọ pé: “Omi wa ni!” Torí náà, ó pe orúkọ kànga náà ní Ésékì,* torí wọ́n bá a jà.
21 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ kànga míì, wọ́n sì tún bá wọn jà nítorí rẹ̀. Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sítínà.*
22 Nígbà tó yá, ó kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga míì, àmọ́ wọn ò bá a jà torí rẹ̀. Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Réhóbótì,* ó sì sọ pé: “Ó jẹ́ torí pé Jèhófà ti fún wa ní àyè tó fẹ̀, ó sì ti mú ká bímọ tó pọ̀ ní ilẹ̀ yìí.”+
23 Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Bíá-ṣébà.+
24 Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jèhófà fara hàn án ní òru, ó sì sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù+ bàbá rẹ. Má bẹ̀rù,+ torí mo wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò bù kún ọ, màá sì mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ torí Ábúráhámù ìránṣẹ́+ mi.”
25 Torí náà, ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì ké pe orúkọ Jèhófà.+ Ísákì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀,+ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan síbẹ̀.
26 Lẹ́yìn náà, Ábímélékì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Gérárì pẹ̀lú Áhúsátì agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun+ rẹ̀.
27 Ni Ísákì bá sọ fún wọn pé: “Kí nìdí tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi, ṣebí ẹ kórìíra mi, ẹ sì lé mi kúrò ní ìlú yín?”
28 Wọ́n fèsì pé: “Ó ti hàn kedere sí wa pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.+ Torí rẹ̀ la ṣe sọ pé, ‘Jọ̀ọ́, jẹ́ ká jọ búra, ká sì bá ọ+ dá májẹ̀mú
29 pé o ò ní ṣe ohun búburú kankan sí wa bí a ò ṣe ṣèkà sí ọ, bí o ṣe rí i pé kìkì ohun tó dáa la ṣe sí ọ torí a ní kí o máa lọ ní àlàáfíà. Jèhófà ti bù kún ọ.’”
30 Lẹ́yìn náà, ó se àsè fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.
31 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n tètè jí, wọ́n sì jọ+ búra. Lẹ́yìn ìyẹn, Ísákì ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní àlàáfíà.
32 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ìránṣẹ́ Ísákì wá ròyìn fún un nípa kànga tí wọ́n gbẹ́,+ wọ́n sì sọ fún un pé: “A ti kan omi!”
33 Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣíbà. Ìdí nìyẹn tí orúkọ ìlú náà fi ń jẹ́ Bíá-ṣébà+ títí dòní.
34 Nígbà tí Ísọ̀ pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó fi Júdítì ọmọ Béérì, ọmọ Hétì ṣe aya àti Básémátì ọmọ Ẹ́lónì, ọmọ Hétì.+
35 Wọ́n ba Ísákì àti Rèbékà+ nínú jẹ́* gidigidi.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “wíńdò.”
^ Tàbí “dì mọ́ Rèbékà ìyàwó rẹ̀.”
^ Ó túmọ̀ sí “Àríyànjiyàn.”
^ Ó túmọ̀ sí “Ẹ̀sùn.”
^ Ó túmọ̀ sí “Ibi Tó Fẹ̀.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “Wọ́n mú kí ẹ̀mí Ísákì àti Rèbékà korò.”