Àkọsílẹ̀ Jòhánù 9:1-41

  • Jésù wo ọkùnrin tí wọ́n bí ní afọ́jú sàn (1-12)

  • Àwọn Farisí ń bi ọkùnrin tó wò sàn ní ìbéèrè (13-34)

  • Àwọn Farisí fọ́jú (35-41)

9  Bó ṣe ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní afọ́jú.  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá bi í pé: “Rábì,+ ta ló ṣẹ̀ tí wọ́n fi bí ọkùnrin yìí ní afọ́jú, ṣé òun ni àbí àwọn òbí rẹ̀?”  Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe ọkùnrin yìí ló ṣẹ̀, kì í sì í ṣe àwọn òbí rẹ̀, àmọ́ ó rí bẹ́ẹ̀ ká lè fi àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.+  A gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ Ẹni tó rán mi ní ojúmọmọ;+ òru ń bọ̀ nígbà tí èèyàn kankan ò ní lè ṣiṣẹ́.  Tí mo bá ṣì wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”+  Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó tutọ́ sílẹ̀, ó pò ó mọ́ iyẹ̀pẹ̀, ó sì fi pa ojú ọkùnrin náà,+  ó wá sọ fún un pé: “Lọ wẹ̀ nínú odò Sílóámù” (èyí tó túmọ̀ sí “Rán Jáde”). Torí náà, ó lọ wẹ̀, nígbà tó máa pa dà wá, ó ti ríran.+  Àwọn aládùúgbò àti àwọn tí wọ́n ti máa ń rí i tẹ́lẹ̀ pé alágbe ni wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ṣebí ọkùnrin tó máa ń jókòó ṣagbe nìyí, àbí òun kọ́?”  Àwọn kan ń sọ pé: “Òun ni.” Àwọn míì ń sọ pé: “Rárá o, àmọ́ ó jọ ọ́.” Ọkùnrin náà ń sọ ṣáá pé: “Èmi ni.” 10  Torí náà, wọ́n bi í pé: “Báwo wá ni ojú rẹ ṣe là?” 11  Ó dáhùn pé: “Ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní Jésù ló po nǹkan kan, ó sì fi pa ojú mi, ó wá sọ fún mi pé, ‘Lọ wẹ̀ ní Sílóámù.’+ Mo wá lọ wẹ̀, mo sì ríran.” 12  Ni wọ́n bá sọ fún un pé: “Ibo ni ọkùnrin náà wà?” Ó sọ pé: “Mi ò mọ̀.” 13  Wọ́n mú ọkùnrin tó fìgbà kan jẹ́ afọ́jú náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí. 14  Ó ṣẹlẹ̀ pé Sábáàtì+ ni ọjọ́ tí Jésù po itọ́ mọ́ iyẹ̀pẹ̀, tó sì la ojú rẹ̀.+ 15  Torí náà, lọ́tẹ̀ yìí, àwọn Farisí tún bẹ̀rẹ̀ sí í bi ọkùnrin náà nípa bó ṣe ríran. Ó sọ fún wọn pé: “Ó po nǹkan kan, ó sì fi sí ojú mi, mo wá lọ wẹ̀, mo sì ríran.” 16  Àwọn kan lára àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ ni ọkùnrin yìí ti wá, torí kì í pa Sábáàtì mọ́.”+ Àwọn míì sọ pé: “Báwo ni ọkùnrin tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú àwọn iṣẹ́ àmì bẹ́ẹ̀?”+ Bí wọ́n ṣe pínyà síra wọn nìyẹn.+ 17  Wọ́n tún sọ fún ọkùnrin afọ́jú náà pé: “Nígbà tó jẹ́ pé ojú rẹ ni ọkùnrin náà là, kí lo máa sọ nípa rẹ̀?” Ọkùnrin náà sọ pé: “Wòlíì ni.” 18  Àmọ́ àwọn Júù ò gbà gbọ́ pé ó ti fọ́jú rí, pé ó sì ti pa dà ríran, àfìgbà tí wọ́n pe àwọn òbí ọkùnrin tó ti ń ríran náà. 19  Wọ́n bi wọ́n pé: “Ṣé ọmọ yín tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú nìyí? Báwo ló ṣe wá ń ríran?” 20  Àwọn òbí rẹ̀ dáhùn pé: “A mọ̀ pé ọmọ wa nìyí, afọ́jú la sì bí i. 21  Àmọ́ bó ṣe wá di pé ó ń ríran báyìí, àwa ò mọ̀; a ò sì mọ ẹni tó la ojú rẹ̀. Ẹ bi í. Kì í ṣe ọmọdé. Ẹ jẹ́ kó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.” 22  Ohun tó mú kí àwọn òbí rẹ̀ sọ àwọn nǹkan yìí ni pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù,+ torí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan tẹ́lẹ̀ pé, tí ẹnikẹ́ni bá gbà pé òun ni Kristi, wọ́n máa lé ẹni yẹn kúrò nínú sínágọ́gù.+ 23  Ìdí nìyí tí àwọn òbí rẹ̀ fi sọ pé: “Kì í ṣe ọmọdé. Ẹ bi í léèrè.” 24  Torí náà, wọ́n pe ọkùnrin tó fọ́jú tẹ́lẹ̀ náà lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì sọ fún un pé: “Fi ògo fún Ọlọ́run; a mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí.” 25  Ó sọ pé: “Èmi ò mọ̀ bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ ni o. Ohun kan tí mo mọ̀ ni pé, afọ́jú ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ mo ti ń ríran báyìí.” 26  Wọ́n wá bi í pé: “Kí ló ṣe fún ọ? Báwo ló ṣe la ojú rẹ?” 27  Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, àmọ́ ẹ ò fetí sílẹ̀. Kí lẹ tún fẹ́ gbọ́ ọ fún? Àbí ẹ̀yin náà fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni?” 28  Wọ́n wá sọ̀rọ̀ sí i tẹ̀gàntẹ̀gàn pé: “Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yẹn, ọmọ ẹ̀yìn Mósè ni àwa. 29  A mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀, àmọ́ ní ti ọkùnrin yìí, a ò mọ ibi tó ti wá.” 30  Ọkùnrin náà sọ fún wọn pé: “Ọ̀rọ̀ yìí yà mí lẹ́nu o, pé ẹ ò mọ ibi tó ti wá, síbẹ̀ ó la ojú mi. 31  Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í tẹ́tí sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń bẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó máa ń tẹ́tí sí ẹni yìí.+ 32  Látìgbà láéláé, a ò gbọ́ ọ rí pé ẹnì kankan la ojú ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú. 33  Ká ní kì í ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí ti wá ni, kò ní lè ṣe nǹkan kan rárá.”+ 34  Wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ tí wọ́n bí sínú ẹ̀ṣẹ̀ lódindi yìí lo tún fẹ́ máa kọ́ wa?” Ni wọ́n bá jù ú síta!+ 35  Jésù gbọ́ pé wọ́n ti jù ú síta, nígbà tó sì rí i, ó sọ pé: “Ṣé o ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ èèyàn?” 36  Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ọ̀gá, ta ni onítọ̀hún, kí n lè ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?” 37  Jésù sọ fún un pé: “O ti rí i, kódà, òun ló ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.” 38  Ó sọ pé: “Mo ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, Olúwa.” Ó sì tẹrí ba* fún un. 39  Jésù wá sọ pé: “Torí ìdájọ́ yìí ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran,+ kí àwọn tó ríran sì lè di afọ́jú.”+ 40  Àwọn Farisí tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ àwọn nǹkan yìí, wọ́n sì sọ fún un pé: “Àwa náà ò fọ́jú, àbí a fọ́jú?” 41  Jésù sọ fún wọn pé: “Ká ní ẹ fọ́jú ni, ẹ ò ní dẹ́ṣẹ̀ kankan. Àmọ́ ní báyìí, ẹ sọ pé: ‘Àwa ríran.’ Ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣì ni yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “forí balẹ̀.”