Jóòbù 33:1-33
33 “Àmọ́ ní báyìí, Jóòbù, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi;Fetí sí gbogbo ohun tí mo fẹ́ sọ.
2 Jọ̀ọ́, wò ó! Mo gbọ́dọ̀ la ẹnu mi;Ahọ́n mi* gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀.
3 Àwọn ọ̀rọ̀ mi fi òótọ́ ọkàn+ mi hàn,Ètè mi sì ń fi òótọ́ inú sọ ohun tí mo mọ̀.
4 Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá mi,+Èémí Olódùmarè fúnra rẹ̀ ló sì fún mi ní ìyè.+
5 Dá mi lóhùn tí o bá lè ṣe bẹ́ẹ̀;Gbèjà ara rẹ níwájú mi; mú ìdúró rẹ.
6 Wò ó! Bákan náà ni èmi àti ìwọ rí níwájú Ọlọ́run tòótọ́;Amọ̀ ni ó fi mọ+ èmi náà.
7 Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́ rárá,Má sì jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò ọ́ mọ́lẹ̀ nítorí mi.
8 Àmọ́, o sọ ọ́ létí mi,Àní mo ṣáà ń gbọ́ tí ò ń sọ pé,
9 ‘Mo mọ́, mi ò ní ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn;+Mo mọ́, mi ò ní àṣìṣe.+
10 Àmọ́ Ọlọ́run rí ìdí tó fi yẹ kó ta kò mí;Ó kà mí sí ọ̀tá rẹ̀.+
11 Ó ti ẹsẹ̀ mi mọ́ inú àbà;Ó ń ṣọ́ gbogbo ọ̀nà mi lójú méjèèjì.’+
12 Àmọ́ ohun tí o sọ yìí ò tọ́, torí náà, màá dá ọ lóhùn:
Ọlọ́run tóbi ju ẹni kíkú+ lọ fíìfíì.
13 Kí nìdí tí o fi ń ṣàròyé nípa Rẹ̀?+
Ṣé torí pé kò fèsì gbogbo ọ̀rọ̀ tí o sọ ni?+
14 Torí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kejì,Àmọ́ kò sẹ́ni tó ń fiyè sí i,
15 Lójú àlá, nínú ìran òru,+Nígbà tí àwọn èèyàn ti sùn lọ fọnfọn,Bí wọ́n ṣe ń sùn lórí ibùsùn wọn.
16 Lẹ́yìn náà, ó máa ṣí etí wọn,+Ó sì máa tẹ* ìtọ́ni rẹ̀ mọ́ wọn lọ́kàn,
17 Láti yí èèyàn kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,+Kó sì gba èèyàn lọ́wọ́ ìgbéraga.+
18 Ọlọ́run ò jẹ́ kí ọkàn* rẹ̀ wọnú kòtò,*+Kò jẹ́ kí idà* gba ẹ̀mí rẹ̀.
19 Ìrora téèyàn ń ní lórí ibùsùn rẹ̀ máa ń bá a wí,Bẹ́ẹ̀ sì ni ìnira tó ń bá egungun rẹ̀ léraléra,
20 Tí òun fúnra rẹ̀* fi kórìíra búrẹ́dì gidigidi,Tó* sì kọ oúnjẹ tó dáa + pàápàá.
21 Ẹran ara rẹ̀ ń joro lọ lójú,Egungun rẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ti wá yọ síta.*
22 Ọkàn* rẹ̀ ti sún mọ́ kòtò;*Ẹ̀mí rẹ̀ sì ti sún mọ́ àwọn tó ń pani.
23 Tí ìránṣẹ́* kan bá wá jíṣẹ́ fún un,Agbẹnusọ kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000),Láti sọ ohun tó tọ́ fún èèyàn,
24 Ọlọ́run máa wá ṣe ojúure sí i, á sì sọ pé,‘Dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, kó má bàa lọ sínú kòtò!*+
Mo ti rí ìràpadà!+
25 Kí ara rẹ̀ jọ̀lọ̀* ju ti ìgbà ọ̀dọ́;+Kó pa dà sí àwọn ọjọ́ tó lókun nígbà ọ̀dọ́.’+
26 Ó máa bẹ Ọlọ́run,+ ẹni tó máa gbà á,Ó máa rí ojú Rẹ̀ tòun ti igbe ayọ̀,Ó sì máa dá òdodo Rẹ̀ pa dà fún ẹni kíkú.
27 Ẹni yẹn máa kéde* fún àwọn èèyàn pé,‘Mo ti ṣẹ̀,+ mo sì ti yí ohun tó tọ́ po,Àmọ́ mi ò rí ohun tó tọ́ sí mi gbà.*
28 Ó ti ra ọkàn* mi pa dà kó má bàa lọ sínú kòtò,*+Ẹ̀mí mi sì máa rí ìmọ́lẹ̀.’
29 Lóòótọ́, Ọlọ́run máa ń ṣe gbogbo nǹkan yìíFún èèyàn, lẹ́ẹ̀mejì, lẹ́ẹ̀mẹta,
30 Láti mú un* pa dà kúrò nínú kòtò,*Kí ìmọ́lẹ̀ ìyè+ lè là á lóye.
31 Fiyè sílẹ̀, Jóòbù! Fetí sí mi!
Dákẹ́, kí n sì máa sọ̀rọ̀ lọ.
32 Tí o bá ní nǹkan sọ, fún mi lésì.
Sọ̀rọ̀, torí mo fẹ́ fi hàn pé o jàre.
33 Tí kò bá sí ohun tí o fẹ́ sọ, kí o fetí sí mi;Dákẹ́, màá sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Ahọ́n mi pẹ̀lú òkè ẹnu mi.”
^ Ní Héb., “gbé èdìdì lé.”
^ Tàbí “ẹ̀mí.”
^ Tàbí “sàréè.”
^ Tàbí “ohun ìjà (ohun ọṣẹ́).”
^ Tàbí “Tí ọkàn rẹ̀.”
^ Ní Héb., “ẹ̀mí rẹ̀.”
^ Tàbí “hàn síta.”
^ Tàbí “Ẹ̀mí.”
^ Tàbí “sàréè.”
^ Tàbí “áńgẹ́lì.”
^ Tàbí “sàréè.”
^ Tàbí “le.”
^ Ní Héb., “kọrin.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Mi ò sì jèrè.”
^ Tàbí “ẹ̀mí.”
^ Tàbí “sàréè.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ̀.”
^ Tàbí “sàréè.”