Àkọsílẹ̀ Lúùkù 6:1-49
-
Jésù ni “Olúwa Sábáàtì” (1-5)
-
Ó wo ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sàn (6-11)
-
Àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12-16)
-
Jésù ń kọ́ni, ó sì ń woni sàn (17-19)
-
Àwọn aláyọ̀ àtàwọn tí a káàánú wọn (20-26)
-
Nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá (27-36)
-
Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́ mọ́ (37-42)
-
Èso igi la fi ń mọ̀ ọ́n (43-45)
-
Ilé tí wọ́n kọ́ dáadáa; ilé tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ ò lágbára (46-49)
6 Ní sábáàtì kan, ó ń gba oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń ya àwọn erín ọkà* jẹ,+ wọ́n sì ń fi ọwọ́ ra á.+
2 Ni àwọn kan nínú àwọn Farisí bá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì?”+
3 Àmọ́ Jésù fún wọn lésì pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe rí ni, nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+
4 Bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tó gba àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,* tó sì jẹ ẹ́, tó tún fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ, èyí tí kò bófin mu fún ẹnì kankan láti jẹ, àfi àwọn àlùfáà nìkan?”+
5 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ọmọ èèyàn ni Olúwa Sábáàtì.”+
6 Ní sábáàtì míì,+ ó wọ inú sínágọ́gù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni. Ọkùnrin kan sì wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ.+
7 Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá ń ṣọ́ Jésù lójú méjèèjì, wọ́n ń wò ó bóyá ó máa ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì, kí wọ́n lè rí ọ̀nà láti fẹ̀sùn kàn án.
8 Àmọ́ ó mọ ohun tí wọ́n ń rò,+ torí náà, ó sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Dìde, kí o dúró ní àárín.” Ó dìde, ó sì dúró síbẹ̀.
9 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Mò ń bi yín, Ṣé ó bófin mu ní Sábáàtì láti ṣe rere tàbí láti ṣe ibi, láti gba ẹ̀mí* là tàbí láti pa á run?”+
10 Lẹ́yìn tó wo gbogbo wọn yí ká, ó sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.
11 Àmọ́ wọ́n bínú gidigidi láìronú jinlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn sọ ohun tí wọ́n lè ṣe sí Jésù.
12 Nígbà yẹn, ó lọ sórí òkè lọ́jọ́ kan láti gbàdúrà,+ ó sì fi gbogbo òru gbàdúrà sí Ọlọ́run.+
13 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì yan méjìlá (12) lára wọn, ó tún pè wọ́n ní àpọ́sítélì,+ àwọn ni:
14 Símónì, tó tún pè ní Pétérù, Áńdérù arákùnrin rẹ̀, Jémíìsì, Jòhánù, Fílípì,+ Bátólómíù,
15 Mátíù, Tọ́másì,+ Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Símónì tí wọ́n ń pè ní “onítara,”
16 Júdásì ọmọ Jémíìsì àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó di ọ̀dàlẹ̀.
17 Wọ́n jọ sọ̀ kalẹ̀, ó wá dúró síbì kan tó tẹ́jú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì pọ̀ gan-an níbẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èèyàn láti gbogbo Jùdíà, Jerúsálẹ́mù àti agbègbè etí òkun ní Tírè àti Sídónì, tí wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì rí ìwòsàn àwọn àrùn wọn.
18 Àwọn tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú pàápàá rí ìwòsàn.
19 Gbogbo èrò náà sì fẹ́ fọwọ́ kàn án, torí pé agbára ń jáde lára rẹ̀,+ ó sì ń wo gbogbo wọn sàn.
20 Ó wá gbójú sókè wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé:
“Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ aláìní, torí pé tiyín ni Ìjọba Ọlọ́run.+
21 “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ebi ń pa báyìí, torí pé ẹ máa yó.+
“Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sunkún báyìí, torí pé ẹ máa rẹ́rìn-ín.+
22 “Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn èèyàn bá kórìíra yín+ àti nígbàkigbà tí wọ́n bá ta yín nù,+ tí wọ́n pẹ̀gàn yín, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn yín* pé * ẹni burúkú ni yín nítorí Ọmọ èèyàn.
23 Ẹ yọ̀ ní ọjọ́ yẹn, kí ẹ sì fò sókè tayọ̀tayọ̀, torí, ẹ wò ó! èrè yín pọ̀ ní ọ̀run, torí àwọn ohun yẹn kan náà ni àwọn baba ńlá wọn máa ń ṣe sí àwọn wòlíì.+
24 “Àmọ́, ó mà ṣe fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ o,+ torí pé ẹ̀ ń rí ìtùnú gbà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.+
25 “Ó mà ṣe fún ẹ̀yin tí ẹ yó báyìí o, torí ebi máa pa yín.
“Ó mà ṣe fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín báyìí o, torí ẹ máa ṣọ̀fọ̀, ẹ sì máa sunkún.+
26 “Ó mà ṣe fún yín o, nígbàkigbà tí gbogbo èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín dáadáa,+ torí ohun tí àwọn baba ńlá wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké nìyí.
27 “Àmọ́ mò ń sọ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fetí sílẹ̀ pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ máa ṣe rere sí àwọn tó kórìíra yín,+
28 ẹ máa súre fún àwọn tó ń gégùn-ún fún yín, kí ẹ máa gbàdúrà fún àwọn tó ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.+
29 Tí ẹnì kan bá gbá ọ ní etí* kan, yí ìkejì sí i; tí ẹnì kan bá sì gba aṣọ àwọ̀lékè rẹ, má ṣe lọ́ra láti fún un ní aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú.+
30 Gbogbo àwọn tó bá ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ ni kí o fún,+ ẹni tó bá sì ń mú àwọn nǹkan rẹ lọ, má sọ pé kó dá a pa dà.
31 “Bákan náà, bí ẹ ṣe fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ máa ṣe sí wọn.+
32 “Tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ yín, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín? Torí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wọn.+
33 Tí ẹ bá sì ń ṣe rere sí àwọn tó ń ṣe rere sí yín, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń ṣe bẹ́ẹ̀.
34 Bákan náà, tí ẹ bá ń yá* àwọn tí ẹ retí pé wọ́n máa san án pa dà ní nǹkan, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín?+ Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní nǹkan kí wọ́n lè rí ohun kan náà gbà pa dà.
35 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ẹ máa ṣe rere, kí ẹ sì máa yáni ní nǹkan láìretí ohunkóhun pa dà;+ èrè yín máa wá pọ̀, ẹ sì máa jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, torí ó máa ń ṣoore fún àwọn aláìmoore àti àwọn ẹni burúkú.+
36 Ẹ máa jẹ́ aláàánú, bí Baba yín ṣe jẹ́ aláàánú.+
37 “Bákan náà, ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, ó sì dájú pé a ò ní dá yín lẹ́jọ́;+ ẹ yéé dáni lẹ́bi, ó sì dájú pé a ò ní dá yín lẹ́bi. Ẹ máa dárí jini,* a sì máa dárí jì yín.*+
38 Ẹ sọ ọ́ di àṣà láti máa fúnni, àwọn èèyàn sì máa fún yín.+ Wọ́n máa da òṣùwọ̀n tó dáa, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, sórí itan yín. Torí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni la máa fi díwọ̀n pa dà fún yín.”
39 Ó tún sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Afọ́jú kò lè fi afọ́jú mọ̀nà, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa ṣubú sí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+
40 Akẹ́kọ̀ọ́* ò ga ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, àmọ́ gbogbo ẹni tí a bá kọ́ lọ́nà tó pé máa dà bí olùkọ́ rẹ̀.
41 Kí ló wá dé tí ò ń wo pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, àmọ́ tí o ò kíyè sí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ?+
42 Báwo lo ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí n bá ọ yọ pòròpórò tó wà nínú ojú rẹ,’ nígbà tó jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ ò rí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ? Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ, ìgbà yẹn lo máa wá ríran kedere láti yọ pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ.
43 “Torí kò sí igi rere tó máa ń mú èso jíjẹrà jáde, kò sì sí igi jíjẹrà tó máa ń mú èso rere jáde.+
44 Torí èso igi kọ̀ọ̀kan la fi ń mọ̀ ọ́n.+ Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn kì í kó èso ọ̀pọ̀tọ́ jọ látorí igi ẹ̀gún, wọn kì í sì í gé èso àjàrà lára igi ẹlẹ́gùn-ún.
45 Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere tó wà nínú ọkàn rẹ̀, àmọ́ ẹni burúkú máa ń mú ohun burúkú jáde látinú ìṣúra burúkú rẹ̀; torí lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.+
46 “Kí ló wá dé tí ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olúwa! Olúwa!’ àmọ́ tí ẹ ò ṣe àwọn ohun tí mo sọ?+
47 Gbogbo ẹni tó bá wá sọ́dọ̀ mi, tó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi, tó sì ń ṣe é, màá fi irú ẹni tó jẹ́ hàn yín:+
48 Ó dà bí ọkùnrin kan tó ń kọ́ ilé kan, tó walẹ̀ jìn, tó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta. Nígbà tó yá, tí àkúnya omi dé, odò ya lu ilé náà, àmọ́ kò lágbára tó láti mì í, torí wọ́n kọ́ ọ dáadáa.+
49 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́, tí kò sì ṣe nǹkan kan,+ ó dà bí ọkùnrin kan tó kọ́ ilé kan sórí ilẹ̀ láìsí ìpìlẹ̀. Odò ya lu ilé náà, ó sì wó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ilé náà sì bà jẹ́ gan-an.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, orí ọkà.
^ Tàbí “búrẹ́dì àfihàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Grk., “orúkọ yín.”
^ Tàbí “tí wọ́n ta orúkọ yín nù pé.”
^ Ní Grk., “ẹ̀rẹ̀kẹ́.”
^ Ìyẹn, láìgba èlé.
^ Tàbí “tú yín sílẹ̀.”
^ Tàbí “túni sílẹ̀.”
^ Tàbí “Ọmọ ẹ̀yìn.”