Àkọsílẹ̀ Máàkù 16:1-8

  • Jésù jíǹde (1-8)

16  Torí náà, nígbà tí Sábáàtì+ ti kọjá, Màríà Magidalénì, Màríà+ ìyá Jémíìsì àti Sàlómẹ̀ ra àwọn èròjà tó ń ta sánsán kí wọ́n lè wá fi pa á lára.+  Ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, nígbà tí oòrùn ti yọ, wọ́n wá síbi ibojì* náà.+  Wọ́n ń sọ fún ara wọn pé: “Ta ló máa bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ọ̀nà ibojì náà?”  Àmọ́ nígbà tí wọ́n gbójú sókè, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta náà kúrò, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó tóbi gan-an.+  Nígbà tí wọ́n wọnú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́kùnrin kan tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún, ó wọ aṣọ funfun, ẹnu sì yà wọ́n.  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kó yà yín lẹ́nu.+ Jésù ará Násárẹ́tì tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ̀ ń wá. A ti jí i dìde.+ Kò sí níbí. Ẹ wò ó, ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí.+  Àmọ́ ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti Pétérù pé, ‘Ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín.+ Ẹ máa rí i níbẹ̀, bó ṣe sọ fún yín.’”+  Torí náà, nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n sá kúrò ní ibojì náà, jìnnìjìnnì bò wọ́n, wọn ò sì mọ ohun tí wọn ì bá ṣe. Wọn ò bá ẹnì kankan sọ nǹkan kan, torí ẹ̀rù ń bà wọ́n.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ibojì ìrántí.”
Ẹsẹ kẹjọ ni ìwé Ìhìn Rere Máàkù parí sí, bó ṣe wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó kọ́kọ́ wà, tó sì ṣeé gbára lé. Wo Àfikún A3.