Àkọsílẹ̀ Mátíù 1:1-25

  • Ìlà ìdílé Jésù Kristi (1-17)

  • Ìbí Jésù (18-25)

1  Ìwé ìtàn* nípa Jésù Kristi,* ọmọ Dáfídì,+ ọmọ Ábúráhámù:+   Ábúráhámù bí Ísákì;+Ísákì bí Jékọ́bù;+Jékọ́bù bí Júdà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀;   Támárì bí Pérésì àti Síírà+ fún Júdà;Pérésì bí Hésírónì;+Hésírónì bí Rámù;+   Rámù bí Ámínádábù;Ámínádábù bí Náṣónì;+Náṣónì bí Sálímọ́nì;   Ráhábù+ bí Bóásì fún Sálímọ́nì;Rúùtù bí Óbédì fún Bóásì;+Óbédì bí Jésè;+   Jésè bí Dáfídì+ ọba. Ìyàwó Ùráyà bí Sólómọ́nì+ fún Dáfídì;   Sólómọ́nì bí Rèhóbóámù;+Rèhóbóámù bí Ábíjà;Ábíjà bí Ásà;+   Ásà bí Jèhóṣáfátì;+Jèhóṣáfátì bí Jèhórámù;+Jèhórámù bí Ùsáyà;   Ùsáyà bí Jótámù;+Jótámù bí Áhásì;+Áhásì bí Hẹsikáyà;+ 10  Hẹsikáyà bí Mánásè;+Mánásè bí Ámọ́nì;+Ámọ́nì bí Jòsáyà;+ 11  Jòsáyà+ bí Jekonáyà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nígbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì.+ 12  Lẹ́yìn tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì, Jekonáyà bí Ṣéálítíẹ́lì;Ṣéálítíẹ́lì bí Serubábélì;+ 13  Serubábélì bí Ábíúdù;Ábíúdù bí Élíákímù;Élíákímù bí Ásórì; 14  Ásórì bí Sádókù;Sádókù bí Ákímù;Ákímù bí Élíúdù; 15  Élíúdù bí Élíásárì;Élíásárì bí Mátáánì;Mátáánì bí Jékọ́bù; 16  Jékọ́bù bí Jósẹ́fù ọkọ Màríà, ẹni tó bí Jésù,+ tí à ń pè ní Kristi.+ 17  Torí náà, gbogbo ìran náà látọ̀dọ̀ Ábúráhámù dórí Dáfídì jẹ́ ìran mẹ́rìnlá (14); látọ̀dọ̀ Dáfídì di ìgbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì, ìran mẹ́rìnlá (14); látìgbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì di ìgbà Kristi, ìran mẹ́rìnlá (14). 18  Àmọ́ bí wọ́n ṣe bí Jésù Kristi nìyí. Nígbà tí Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù ń fẹ́ra wọn sọ́nà, ó ṣẹlẹ̀ pé ó lóyún nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́*+ kí wọ́n tó so wọ́n pọ̀. 19  Àmọ́ torí pé olódodo ni Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀, tí kò sì fẹ́ dójú tì í ní gbangba, ó pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́.+ 20  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó fara balẹ̀ ro ọ̀rọ̀ yìí, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà* fara hàn án lójú àlá, ó sọ pé: “Jósẹ́fù, ọmọ Dáfídì, má bẹ̀rù láti mú Màríà ìyàwó rẹ lọ sílé, torí oyún inú rẹ̀* jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+ 21  Ó máa bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù,*+ torí ó máa gba àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”+ 22  Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun tí Jèhófà* sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ lè ṣẹ, pé: 23  “Wò ó! Wúńdíá náà máa lóyún, ó sì máa bí ọmọkùnrin kan, wọ́n máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì,”+ tó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.”+ 24  Jósẹ́fù wá jí lójú oorun, ó sì ṣe ohun tí áńgẹ́lì Jèhófà* ní kó ṣe, ó mú ìyàwó rẹ̀ lọ sílé. 25  Àmọ́ kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ títí ó fi bí ọmọkùnrin kan,+ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìlà ìdílé.”
Tàbí “Mèsáyà; Ẹni Àmì Òróró.”
Tàbí “ipá ìṣiṣẹ́.”
Nínú ìgbà 237 tí a lo orúkọ náà, Jèhófà, nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ibi àkọ́kọ́ nìyí tó ti fara hàn nínú ìtumọ̀ yìí. Wo Àfikún A5.
Tàbí “èyí tí o lóyún rẹ̀.”
Ìtumọ̀ kan náà ló ní pẹ̀lú orúkọ Hébérù náà, Jéṣúà tàbí Jóṣúà, tó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”