Àkọsílẹ̀ Mátíù 20:1-34
20 “Torí Ìjọba ọ̀run dà bíi baálé ilé kan tó jáde lọ ní àárọ̀ kùtù láti gba àwọn òṣìṣẹ́ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.+
2 Lẹ́yìn tó bá àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣàdéhùn pé òun máa fún wọn ní owó dínárì* kan fún ọjọ́ kan, ó ní kí wọ́n lọ sínú ọgbà àjàrà òun.
3 Ó tún jáde ní nǹkan bíi wákàtí kẹta,* ó sì rí àwọn míì tí wọ́n dúró ní ibi ọjà, tí wọn ò ríṣẹ́ ṣe;
4 ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà, màá sì fún yín ní ohunkóhun tó bá tọ́.’
5 Torí náà, wọ́n lọ. Ó tún jáde ní nǹkan bíi wákàtí kẹfà* àti wákàtí kẹsàn-án,* ó sì ṣe ohun kan náà.
6 Níkẹyìn, ní nǹkan bíi wákàtí kọkànlá,* ó jáde lọ, ó sì rí àwọn míì tí wọ́n dúró, ó sọ fún wọn pé, ‘Kí ló dé tí ẹ dúró síbí látàárọ̀, tí ẹ ò ríṣẹ́ ṣe?’
7 Wọ́n sọ fún un pé, ‘Torí kò sẹ́ni tó gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà.’
8 “Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún ọkùnrin tó fi ṣe alábòójútó pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o sì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn,+ bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn tó dé kẹ́yìn títí dórí àwọn ẹni àkọ́kọ́.’
9 Nígbà tí àwọn ọkùnrin tó dé ní wákàtí kọkànlá wá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì* kan.
10 Nígbà tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wá dé, wọ́n rò pé àwọn máa gbà jù bẹ́ẹ̀ lọ, àmọ́ owó dínárì* kan ni wọ́n san fún àwọn náà.
11 Nígbà tí wọ́n gbà á, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé fún baálé ilé náà,
12 wọ́n sì sọ pé, ‘Iṣẹ́ wákàtí kan ni àwọn tó dé kẹ́yìn yìí ṣe; síbẹ̀ iye kan náà lo fún àwa tí a ṣiṣẹ́ kára látàárọ̀ nínú ooru tó mú gan-an!’
13 Àmọ́ ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni, mi ò hùwà àìtọ́ sí ọ. Àdéhùn owó dínárì* kan la jọ ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+
14 Gba ohun tó jẹ́ tìrẹ, kí o sì máa lọ. Iye tí mo fún ẹni tó dé kẹ́yìn yìí náà ni màá fún ọ.
15 Ṣé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi àwọn nǹkan mi ṣe ohun tó wù mí ni? Àbí ṣé ojú rẹ ń ṣe ìlara* torí mo jẹ́ ẹni rere* ni?’+
16 Lọ́nà yìí, àwọn ẹni ìkẹyìn máa di ẹni àkọ́kọ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì máa di ẹni ìkẹyìn.”+
17 Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá (12) náà sí ẹ̀gbẹ́ kan láwọn nìkan, ó sì sọ fún wọn lójú ọ̀nà pé:+
18 “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un,+
19 wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n nà án, kí wọ́n sì kàn án mọ́gi;+ a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+
20 Ìyá àwọn ọmọ Sébédè+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ wá bá a, obìnrin náà tẹrí ba* fún un, ó sì béèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀.+
21 Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Kí lo fẹ́?” Ó fèsì pé: “Pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ mi méjèèjì yìí jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú Ìjọba rẹ.”+
22 Jésù dáhùn pé: “Ẹ ò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè. Ṣé ẹ lè mu ife tí mo máa tó mu?”+ Wọ́n sọ fún un pé: “A lè mu ún.”
23 Ó sọ fún wọn pé: “Ó dájú pé ẹ máa mu ife mi,+ àmọ́ èmi kọ́ ló máa sọ ẹni tó máa jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi àti sí òsì mi, ṣùgbọ́n ó máa wà fún àwọn tí Baba mi ti ṣètò rẹ̀ fún.”+
24 Nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bínú sí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà.+
25 Àmọ́ Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, àwọn èèyàn ńlá sì máa ń lo àṣẹ lórí wọn.+
26 Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín;+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín,+
27 ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.+
28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ èèyàn ò ṣe wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kó sì fi ẹ̀mí* rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”+
29 Bí wọ́n ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, èrò rẹpẹtẹ tẹ̀ lé e.
30 Wò ó! àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tí wọ́n jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!”+
31 Àmọ́ àwọn èrò náà bá wọn wí, wọ́n ní kí wọ́n dákẹ́; àmọ́ ṣe ni wọ́n tún ń kígbe sókè pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!”
32 Torí náà, Jésù dúró, ó pè wọ́n, ó sì sọ pé: “Kí lẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?”
33 Wọ́n sọ fún un pé: “Olúwa, jẹ́ kí ojú wa là.”
34 Àánú wọn ṣe Jésù, ó sì fọwọ́ kan ojú wọn,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n pa dà ríran, wọ́n sì tẹ̀ lé e.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àfikún B14.
^ Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀.
^ Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
^ Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
^ Ìyẹn, nǹkan bí aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́.
^ Wo Àfikún B14.
^ Wo Àfikún B14.
^ Wo Àfikún B14.
^ Ní Grk., “burú.”
^ Tàbí “jẹ́ ọ̀làwọ́.”
^ Tàbí “forí balẹ̀.”
^ Tàbí “ọkàn.”