Oníwàásù 5:1-20

  • Wá síwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ìbẹ̀rù tó yẹ (1-7)

  • Àwọn tó ga ju àwọn tó wà nípò gíga ń ṣọ́ wọn (8, 9)

  • Asán tó wà nínú ọrọ̀ (10-20)

    • Owó kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ owó (10)

    • Oorun òṣìṣẹ́ máa ń dùn (12)

5  Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́;+ ó sàn kéèyàn wá fetí sílẹ̀+ ju kó mú ẹbọ wá bí àwọn òmùgọ̀ ti ń ṣe,+ nítorí wọn ò mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò dáa.  Má ṣe yánu sọ̀rọ̀ tàbí kí ọkàn rẹ sọ̀rọ̀ láìronú níwájú Ọlọ́run tòótọ́,+ nítorí Ọlọ́run tòótọ́ wà ní ọ̀run àmọ́ ìwọ wà ní ayé. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n.+  Nítorí ọ̀pọ̀ iṣẹ́* máa ń mú kí èèyàn lá àlá,+ àpọ̀jù ọ̀rọ̀+ sì máa ń mú kí àwọn òmùgọ̀ máa wí ìrégbè.  Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má fi falẹ̀, san án,+ nítorí inú rẹ̀ kì í dùn sí àwọn òmùgọ̀.+ Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.+  Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.+  Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ* dẹ́ṣẹ̀,+ má sì sọ níwájú áńgẹ́lì* pé àṣìṣe ni.+ Kí nìdí tí wàá fi mú Ọlọ́run tòótọ́ bínú nítorí ohun tí o sọ, tí á sì pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run?+  Nítorí bí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ṣe ń mú kí èèyàn lá àlá,+ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ púpọ̀ ṣe ń já sí asán. Àmọ́, Ọlọ́run tòótọ́ ni kí o bẹ̀rù.+  Tí o bá rí i tí wọ́n ń ni àwọn aláìní lára tàbí tí wọ́n ń tẹ ìdájọ́ òdodo àti òtítọ́ lójú ní agbègbè rẹ, má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu.+ Torí ẹnì kan wà tó ń ṣọ́ ẹni tó wà nípò gíga, ẹni yẹn sì ga jù ú lọ, síbẹ̀ àwọn míì tún wà tó ga jù wọ́n lọ.  Bákan náà, wọ́n pín èrè ilẹ̀ náà láàárín ara wọn; kódà inú oko ni oúnjẹ ọba ti ń wá.+ 10  Fàdákà kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni owó kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.+ 11  Nígbà tí ohun rere bá pọ̀ sí i, àwọn tó ń jẹ ẹ́ á pọ̀ sí i.+ Àǹfààní wo ló sì jẹ́ fún ẹni tó ní in ju pé kó máa fi ojú rẹ̀ wò ó?+ 12  Oorun ẹni tó ń sìn máa ń dùn, bóyá oúnjẹ díẹ̀ ló jẹ tàbí púpọ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ọlọ́rọ̀ ní kì í jẹ́ kó rí oorun sùn. 13  Àdánù* ńlá kan wà tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run:* ọrọ̀ tí àwọn ọlọ́rọ̀ kó pa mọ́ fún ìpalára ara wọn. 14  Àwọn ọrọ̀ yẹn ṣègbé nítorí òwò* àṣedànù, nígbà tó sì bímọ, kò ní ohun ìní kankan lọ́wọ́ mọ́.+ 15  Bí èèyàn ṣe jáde wá látinú ìyá rẹ̀ ní ìhòòhò, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lọ.+ Kò lè mú ohunkóhun lọ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ti ṣe.+ 16  Èyí pẹ̀lú jẹ́ àdánù* ńlá: Bí ẹni náà ṣe wá gẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa lọ; èrè wo ló sì wà fún ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára lórí asán?+ 17  Yàtọ̀ síyẹn, ojoojúmọ́ ló ń jẹun nínú òkùnkùn pẹ̀lú ìbànújẹ́ ńlá àti àìsàn àti ìbínú.+ 18  Ohun tí mo rí pé ó dára tí ó sì tọ́ ni pé: kéèyàn máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára+ tó fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run* láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un, nítorí èrè* rẹ̀ nìyẹn.+ 19  Bákan náà, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ bá fún ẹnì kan ní ọrọ̀ àti ohun ìní,+ tó sì jẹ́ kó lè gbádùn wọn, kí ẹni náà gba èrè* rẹ̀ kó sì máa yọ̀ nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.+ 20  Torí bóyá ló fi máa mọ̀* pé ọjọ́ ayé òun ń lọ, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú kí ayọ̀ gbà á lọ́kàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àníyàn.”
Tàbí “òjíṣẹ́.”
Ní Héb., “ara rẹ.”
Tàbí “Àjálù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “iṣẹ́.”
Tàbí “àjálù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “ìpín.”
Tàbí “ìpín.”
Tàbí “rántí.”