Sáàmù 107:1-43

  • Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀

    • Ó darí wọn gba ọ̀nà tí ó tọ́ (7)

    • Ó tẹ́ ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ àti ẹni tí ebi ń pa lọ́rùn (9)

    • Ó mú wọn jáde látinú òkùnkùn (14)

    • Ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ránṣẹ́ láti mú wọn lára dá (20)

    • Ó ń dáàbò bo aláìní lọ́wọ́ ìnilára (41)

(Sáàmù 107-150) 107  Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+   Kí àwọn tí Jèhófà gbà* pa dà sọ bẹ́ẹ̀,Àwọn tó gbà pa dà lọ́wọ́* ọ̀tá,+   Àwọn tó kó jọ láti àwọn ilẹ̀,+Láti ìlà oòrùn àti láti ìwọ̀ oòrùn,*Láti àríwá àti láti gúúsù.+   Wọ́n rìn kiri ní aginjù, ní aṣálẹ̀;Wọn ò rí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé.   Ebi pa wọ́n, òùngbẹ sì gbẹ wọ́n;Àárẹ̀ mú wọn* torí wọn ò lókun mọ́.   Wọ́n ń ké pe Jèhófà nínú wàhálà tó bá wọn,+Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.+   Ó mú wọn gba ọ̀nà tí ó tọ́+Kí wọ́n lè dé ìlú tí wọ́n á lè máa gbé.+   Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà+ nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.+   Nítorí ó mú kí àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ mu àmutẹ́rùn,Ó sì mú kí àwọn* tí ebi ń pa jẹ ohun rere ní àjẹtẹ́rùn.+ 10  Àwọn kan ń gbé inú òkùnkùn biribiri,Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ìyà ń jẹ, tí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sì wà lọ́wọ́ wọn. 11  Nítorí wọ́n ta ko ọ̀rọ̀ Ọlọ́run;Wọn ò ka ìmọ̀ràn Ẹni Gíga Jù Lọ sí.+ 12  Torí náà, ó fi ìnira rẹ ọkàn wọn sílẹ̀;+Wọ́n kọsẹ̀, kò sì sí ẹni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. 13  Wọ́n ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí wàhálà tó bá wọn,Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn. 14  Ó mú wọn jáde nínú òkùnkùn biribiri,Ó sì fa ìdè wọn já.+ 15  Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀+Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn. 16  Nítorí ó ti fọ́ àwọn ilẹ̀kùn bàbà,Ó sì ti gé àwọn ọ̀pá ìdábùú onírin.+ 17  Wọ́n ya òmùgọ̀, wọ́n sì jìyà+Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àṣìṣe wọn.+ 18  Oúnjẹ kankan ò lọ lẹ́nu wọn;*Wọ́n sún mọ́ àwọn ẹnubodè ikú. 19  Wọ́n á ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí wàhálà tó bá wọn;Á sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn. 20  Á fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn, á mú wọn lára dá,+Á sì yọ wọ́n nínú kòtò tí wọ́n há sí. 21  Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn. 22  Kí wọ́n rú ẹbọ ọpẹ́,+Kí wọ́n sì máa fi igbe ayọ̀ kéde àwọn iṣẹ́ rẹ̀. 23  Àwọn tó ń fi ọkọ̀ rìnrìn àjò lórí òkun,Tí wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,+  24  Wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ JèhófàÀti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ nínú ibú;+  25  Bó ṣe fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kí ìjì máa jà,+Tó sì ń ru ìgbì òkun sókè. 26  Wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run;Wọ́n já wálẹ̀ ṣòòròṣò sínú ibú. Ọkàn wọn domi nítorí àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. 27  Wọ́n ń rìn tàgétàgé, wọ́n sì ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ọ̀mùtí,Gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ní já sí pàbó.+ 28  Ni wọ́n bá ké pe Jèhófà nínú wàhálà tó bá wọn,+Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn. 29  Ó mú kí ìjì náà rọlẹ̀,Ìgbì òkun sì pa rọ́rọ́.+ 30  Inú wọn dùn nígbà tí gbogbo rẹ̀ pa rọ́rọ́,Ó sì ṣamọ̀nà wọn dé èbúté tí wọ́n fẹ́. 31  Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.+ 32  Kí wọ́n máa gbé e ga nínú ìjọ àwọn èèyàn,+Kí wọ́n sì máa yìn ín nínú ìgbìmọ̀* àwọn àgbààgbà. 33  Ó ń sọ àwọn odò di aṣálẹ̀,Ó sì ń sọ ìṣàn omi di ilẹ̀ tó gbẹ táútáú,+  34  Ó ń sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀,+Nítorí ìwà burúkú àwọn tó ń gbé orí rẹ̀. 35  Ó ń sọ aṣálẹ̀ di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,Ó sì ń sọ ilẹ̀ gbígbẹ di ìṣàn omi.+ 36  Ó ń mú kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,+Kí wọ́n lè tẹ ìlú dó láti máa gbé.+ 37  Wọ́n dáko, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà+Tí irè oko rẹ̀ pọ̀ dáadáa.+ 38  Ó bù kún wọn, wọ́n sì pọ̀ gidigidi;Kò jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn pẹ̀dín.+ 39  Àmọ́ wọ́n tún dín kù, ẹ̀tẹ́ sì bá wọnNítorí ìnilára, àjálù àti ẹ̀dùn ọkàn. 40  Ó rọ̀jò àbùkù sórí àwọn èèyàn pàtàkì,Ó sì mú kí wọ́n rìn kiri ní ilẹ̀ tó ti di ahoro, tí kò sì lójú ọ̀nà.+ 41  Àmọ́ ó dáàbò bo àwọn aláìní* lọ́wọ́ ìnilára,+Ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran. 42  Àwọn adúróṣinṣin rí èyí, wọ́n sì yọ̀;+Àmọ́ gbogbo àwọn aláìṣòdodo pa ẹnu wọn mọ́.+ 43  Ẹni tó bá gbọ́n yóò kíyè sí àwọn nǹkan yìí,+Yóò sì fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “rà.”
Tàbí “gbà kúrò ní ìkáwọ́.”
Tàbí “Láti yíyọ oòrùn àti láti wíwọ̀ oòrùn.”
Tàbí “ọkàn wọn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Ọkàn wọn kọ gbogbo oúnjẹ.”
Ní Héb., “ní ìjókòó.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Tàbí “ó gbé àwọn aláìní ga,” ìyẹn, kí ọwọ́ má bàa tó wọn.