Sáàmù 116:1-19
116 Mo nífẹ̀ẹ́ JèhófàNítorí ó ń gbọ́* ohùn mi, ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.+
2 Nítorí ó ń tẹ́tí* sí mi,+Èmi yóò máa ké pè é ní gbogbo ìgbà tí mo bá wà láàyè.*
3 Àwọn okùn ikú yí mi ká;Isà Òkú dì mí mú.*+
Ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn bò mí mọ́lẹ̀.+
4 Àmọ́ mo ké pe orúkọ Jèhófà,+ mo ní:
“Jèhófà, gbà mí* sílẹ̀!”
5 Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò* àti olódodo;+Ọlọ́run wa jẹ́ aláàánú.+
6 Jèhófà ń ṣọ́ àwọn aláìmọ̀kan.+
Wọ́n rẹ̀ mí sílẹ̀, àmọ́ ó gbà mí.
7 Kí ọkàn* mi rí ìsinmi lẹ́ẹ̀kan sí i,Nítorí Jèhófà ti fi inú rere hàn sí mi.
8 O ti gbà mí* lọ́wọ́ ikú,O gba ojú mi lọ́wọ́ omijé, o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìkọ̀sẹ̀.+
9 Ṣe ni èmi yóò máa rìn níwájú Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè.
10 Mo nígbàgbọ́, torí náà mo sọ̀rọ̀;+Ìyà jẹ mí gan-an.
11 Ní tèmi, jìnnìjìnnì bò mí, mo sọ pé:
“Òpùrọ́ ni gbogbo èèyàn.”+
12 Kí ni màá san pa dà fún JèhófàLórí gbogbo oore tó ṣe fún mi?
13 Màá gbé ife ìgbàlà,*Màá sì ké pe orúkọ Jèhófà.
14 Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún JèhófàNíwájú gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+
15 Lójú Jèhófà, àdánù ńlá*Ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.+
16 Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà,Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni mí.
Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, ọmọ ẹrúbìnrin rẹ.
O ti tú ìdè mi.+
17 Màá rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ;+Màá ké pe orúkọ Jèhófà.
18 Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà+Níwájú gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀,+
19 Nínú àwọn àgbàlá ilé Jèhófà,+Láàárín rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.
Ẹ yin Jáà!*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “Mo nífẹ̀ẹ́ nítorí Jèhófà ń gbọ́.”
^ Tàbí “ó ń bẹ̀rẹ̀ kí ó lè fetí.”
^ Ní Héb., “ní ọjọ́ ayé mi.”
^ Ní Héb., “Àwọn ìdààmú Ṣìọ́ọ̀lù wá mi rí.”
^ Tàbí “gba ọkàn mi.”
^ Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “gba ọkàn mi.”
^ Tàbí “ìgbàlà ńlá.”
^ Ní Héb., “iyebíye.”
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.