Sáàmù 128:1-6
Orin Ìgòkè.
128 Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà,+Tó ń rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀.+
2 Wàá jẹ ohun tí ọwọ́ rẹ ṣiṣẹ́ kára láti mú jáde.
Wàá láyọ̀, wàá sì láásìkí.+
3 Ìyàwó rẹ yóò dà bí igi àjàrà tó ń so nínú ilé rẹ;+Àwọn ọmọ rẹ yóò dà bí àwọn ẹ̀ka tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ lára igi ólífì, wọ́n á yí tábìlì rẹ ká.
4 Wò ó! Bí ọkùnrin tó bẹ̀rù JèhófàṢe máa rí ìbùkún gbà nìyẹn.+
5 Jèhófà yóò bù kún ọ láti Síónì.
Kí aásìkí Jerúsálẹ́mù ṣojú rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ,+
6 Kí o sì rí àwọn ọmọ ọmọ rẹ.
Kí àlàáfíà wà ní Ísírẹ́lì.