Sáàmù 134:1-3
-
Wọ́n ń yin Ọlọ́run ní òròòru
-
“Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè nínú ìjẹ́mímọ́” (2)
-
Orin Ìgòkè.
134 Ẹ yin Jèhófà,Gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,+Ẹ̀yin tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà ní òròòru.+
2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè+ nínú ìjẹ́mímọ́,*Kí ẹ sì yin Jèhófà.
3 Kí Jèhófà, Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé,Bù kún ọ láti Síónì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “ní ibi mímọ́.”