Sáàmù 140:1-13

  • Jèhófà, Olùgbàlà tó lágbára

    • Àwọn aṣebi dà bí ejò (3)

    • Àwọn oníwà ipá yóò ṣubú (11)

Fún olùdarí. Orin Dáfídì. 140  Jèhófà, gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi;Dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,+  Àwọn tó ń gbèrò ibi nínú ọkàn wọn,+Tí wọ́n sì ń dá ìjà sílẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀.  Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bíi ti ejò;+Oró paramọ́lẹ̀ wà lábẹ́ ètè wọn.+ (Sélà)  Jèhófà, dáàbò bò mí lọ́wọ́ ẹni burúkú;+Máa ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,Àwọn tó ń gbèrò láti mú kí n yọ̀ ṣubú.  Àwọn agbéraga dẹ pańpẹ́ pa mọ́ dè mí;Wọ́n fi okùn ta àwọ̀n sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà.+ Wọ́n dẹkùn fún mi.+ (Sélà)  Mo sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi. Jèhófà, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.”+  Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Olùgbàlà mi tó lágbára,O dáàbò bo orí mi ní ọjọ́ ogun.+  Jèhófà, má ṣe fún àwọn ẹni burúkú ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́. Má ṣe jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbèrò bọ́ sí i, kí wọ́n má bàa gbé ara wọn ga.+ (Sélà)  Kí ọ̀rọ̀ ibi tí àwọn tó yí mi ká ń fẹnu wọn sọ+Dà lé wọn lórí. 10  Kí òjò ẹyin iná rọ̀ lé wọn lórí.+ Ká jù wọ́n sínú iná,Sínú àwọn kòtò jíjìn,*+ kí wọ́n má ṣe gbérí mọ́. 11  Kí àwọn abanijẹ́ má ṣe ríbi gbé nínú ayé.*+ Kí ibi máa lépa àwọn oníwà ipá, kó sì mú wọn balẹ̀. 12  Mo mọ̀ pé Jèhófà máa gbèjà àwọn aláìníÁ sì ṣèdájọ́ òdodo fún àwọn tálákà.+ 13  Ó dájú pé àwọn olódodo yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;Àwọn adúróṣinṣin yóò máa gbé níwájú* rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “kòtò olómi.”
Tàbí “lórí ilẹ̀.”
Tàbí “lọ́dọ̀.”