Sáàmù 144:1-15
Ti Dáfídì.
144 Ìyìn ni fún Jèhófà, Àpáta mi,+Ẹni tó ń kọ́ ọwọ́ mi ní ìjàÀti ìka mi ní ogun.+
2 Òun ni ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ àti ibi ààbò mi,Ibi gíga mi tó láàbò àti olùgbàlà mi,Apata mi àti Ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò,+Ẹni tó ń tẹ àwọn èèyàn lórí ba sábẹ́ mi.+
3 Jèhófà, kí ni èèyàn jẹ́, tí o fi ń kíyè sí iÀti ọmọ ẹni kíkú, tí o fi ń fiyè sí i?+
4 Èèyàn dà bí èémí lásán;+Àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bí òjìji tó ń kọjá lọ.+
5 Jèhófà, tẹ àwọn ọ̀run rẹ wálẹ̀ kí o sì sọ̀ kalẹ̀;+Fọwọ́ kan àwọn òkè, kí o sì mú kí wọ́n rú èéfín.+
6 Mú kí mànàmáná kọ, kí o sì tú àwọn ọ̀tá ká;+Ta àwọn ọfà rẹ, kí o sì mú kí wọ́n wà nínú ìdàrúdàpọ̀.+
7 Na ọwọ́ rẹ jáde látòkè;Dá mi sílẹ̀, kí o sì gbà mí lọ́wọ́ omi tó ń ru gùdù,Lọ́wọ́* àwọn àjèjì,+
8 Àwọn tí ẹnu wọn ń parọ́,Tí wọ́n sì ń gbé ọwọ́ ọ̀tún wọn sókè láti búra èké.*
9 Ọlọ́run, màá kọ orin tuntun sí ọ.+
Màá kọ orin ìyìn* sí ọ, pẹ̀lú ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá,
10 Sí Ẹni tó ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,*+Ẹni tó ń gba Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ idà tó ń pani.+
11 Dá mi sílẹ̀, kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,Àwọn tí ẹnu wọn ń parọ́,Tí wọ́n sì ń gbé ọwọ́ ọ̀tún wọn sókè láti búra èké.
12 Nígbà náà, àwọn ọmọ wa yóò dà bí irúgbìn kékeré tó máa ń tètè dàgbà,Àwọn ọmọbìnrin wa yóò dà bí àwọn òpó igun tí wọ́n ṣe fún ààfin.
13 Oríṣiríṣi irè oko yóò kún àwọn ilé ìkẹ́rùsí wa;Àwọn agbo ẹran wa yóò di ìlọ́po ẹgbẹ̀rún, wọn yóò sì di ìlọ́po ẹgbẹẹgbàárùn-ún.
14 Àwọn ẹran ọ̀sìn wa tó lóyún kò ní fara pa,* oyún ò sì ní bà jẹ́ lára wọn;Kò ní sí igbe wàhálà ní gbàgede ìlú wa.
15 Aláyọ̀ ni àwọn tó rí bẹ́ẹ̀ fún!
Aláyọ̀ ni àwọn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ní ìkáwọ́.”
^ Ní Héb., “Tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún ẹ̀tàn.”
^ Tàbí “kọrin.”
^ Tàbí “ìgbàlà.”
^ Tàbí “bẹ́ níkùn.”