Sáàmù 145:1-21
Ìyìn Dáfídì.
א [Áléfì]
145 Màá gbé ọ ga, ìwọ Ọlọ́run mi Ọba,+Màá yin orúkọ rẹ títí láé àti láéláé.+
ב [Bétì]
2 Màá yìn ọ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;+Màá yin orúkọ rẹ títí láé àti láéláé.+
ג [Gímélì]
3 Jèhófà tóbi, òun sì ni ìyìn yẹ jù lọ,+Àwámáridìí ni títóbi rẹ̀.*+
ד [Dálétì]
4 Ìran dé ìran yóò máa yin àwọn iṣẹ́ rẹ;Wọ́n á máa sọ nípa iṣẹ́ ńlá rẹ.+
ה [Híì]
5 Wọ́n á máa sọ nípa ọlá ńlá ológo iyì rẹ,+Màá sì máa ṣe àṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.
ו [Wọ́ọ̀]
6 Wọ́n á máa sọ nípa àwọn iṣẹ́* àgbàyanu rẹ,Màá sì máa kéde títóbi rẹ.
ז [Sáyìn]
7 Wọ́n á máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ nípa ọ̀pọ̀ oore rẹ,+Wọ́n á sì máa kígbe ayọ̀ nítorí òdodo rẹ.+
ח [Hétì]
8 Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò* àti aláàánú,+Kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.+
ט [Tétì]
9 Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá,+Àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.
י [Yódì]
10 Jèhófà, gbogbo iṣẹ́ rẹ yóò máa yìn ọ́ lógo,+Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò sì máa yìn ọ́.+
כ [Káfì]
11 Wọ́n á máa kéde ògo ìjọba rẹ,+Wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára rẹ,+
ל [Lámédì]
12 Kí aráyé lè mọ àwọn iṣẹ́ ńlá rẹ+Àti ògo ọlá ńlá ìjọba rẹ.+
מ [Mémì]
13 Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ,Àkóso rẹ sì wà láti ìran dé ìran.+
ס [Sámékì]
14 Jèhófà ń gbé gbogbo àwọn tó ti fẹ́ ṣubú ró,+Ó sì ń gbé gbogbo àwọn tó dorí kodò dìde.+
ע [Áyìn]
15 Ojú rẹ ni gbogbo ẹ̀dá ń wò,Ò ń fún wọn ní oúnjẹ wọn lásìkò.+
פ [Péè]
16 O ṣí ọwọ́ rẹ,O sì fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.+
צ [Sádì]
17 Jèhófà jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+Ó sì jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.+
ק [Kófì]
18 Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é,+Nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.*+
ר [Réṣì]
19 Ó ń fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ní ohun tí ọkàn wọn ń fẹ́;+Ó ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́, ó sì ń gbà wọ́n.+
ש [Ṣínì]
20 Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+Àmọ́ yóò pa gbogbo ẹni burúkú run.+
ת [Tọ́ọ̀]
21 Ẹnu mi yóò kéde ìyìn Jèhófà;+Kí gbogbo ohun alààyè* máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀ títí láé àti láéláé.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Títóbi rẹ̀ kọjá òye ẹ̀dá.”
^ Tàbí “nípa agbára.”
^ Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
^ Tàbí “tó ń fòótọ́ inú ké pè é.”
^ Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”