Sáàmù 21:1-13

  • Ìbùkún wà lórí ọba tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

    • Ó fún ọba ní ẹ̀mí gígùn (4)

    • Ọlọ́run á ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ (8-12)

Sí olùdarí. Orin Dáfídì. 21  Jèhófà, inú agbára rẹ ni ọba ti ń yọ̀;+Wo bí ó ṣe ń yọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ!+   O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́,+Ìwọ kò sì fi ohun tó béèrè dù ú. (Sélà)   Nítorí pé o fi ọ̀pọ̀ ìbùkún pàdé rẹ̀;O fi adé wúrà tó dáa* dé e ní orí.+   Ó béèrè ẹ̀mí lọ́wọ́ rẹ, o sì fún un,+Ẹ̀mí gígùn,* títí láé àti láéláé.   Àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ fún un ní ògo ńlá.+ O fi iyì àti ọlá jíǹkí rẹ̀.   O sọ ọ́ di ẹni ìbùkún títí láé;+O mú kí ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nítorí o* wà pẹ̀lú rẹ̀.+   Ọba gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Ẹni Gíga Jù Lọ ní, mìmì kan ò ní mì í* láé.+   Ọwọ́ rẹ á tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;Ọwọ́ ọ̀tún rẹ á tẹ àwọn tó kórìíra rẹ.   Wàá ṣe wọ́n bí ohun tí a jù sínú iná ìléru ní àkókò tí o yàn láti fiyè sí wọn. Jèhófà máa gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, iná á sì jó wọn run.+ 10  Wàá pa àtọmọdọ́mọ* wọn run kúrò ní ayé,Àti ọmọ wọn kúrò láàárín àwọn ọmọ èèyàn. 11  Wọ́n fẹ́ ṣe ohun tí kò dáa sí ọ;+Wọ́n ti gbèrò ibi, àmọ́ kò ní ṣẹ.+ 12  Wàá mú kí wọ́n sá pa dà+Nígbà tí o bá dojú ọfà* rẹ kọ wọ́n.* 13  Dìde nínú agbára rẹ, Jèhófà. A ó fi orin yin* agbára ńlá rẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tí a yọ́ mọ́.”
Ní Héb., “Ọjọ́ gígùn.”
Ní Héb., “ojú rẹ.”
Tàbí “kò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n).”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “okùn ọrun.”
Ní Héb., “ojú wọn.”
Ní Héb., “kọrin, a ó sì lo ohun ìkọrin fún.”