Sáàmù 4:1-8
Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Orin Dáfídì.
4 Nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn, ìwọ Ọlọ́run mi olódodo.+
Ṣe ọ̀nà àbáyọ* fún mi nínú wàhálà mi.
Ṣe ojú rere sí mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
2 Ẹ̀yin ọmọ èèyàn, ìgbà wo lẹ máa ṣíwọ́ sísọ iyì mi di àbùkù?
Ìgbà wo lẹ máa ṣíwọ́ nínífẹ̀ẹ́ ohun tí kò ní láárí, tí ẹ ó sì ṣíwọ́ wíwá ohun tí ó jẹ́ èké? (Sélà)
3 Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà máa ṣìkẹ́ ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀;*Jèhófà máa gbọ́ nígbà tí mo bá ké pè é.
4 Tí inú bá bí yín, ẹ má ṣẹ̀.+
Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ nínú ọkàn yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. (Sélà)
5 Ẹ rú ẹbọ òdodo,Kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.+
6 Ọ̀pọ̀ ló ń sọ pé: “Ta ló máa jẹ́ ká rí ohun rere?”
Jèhófà, jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ tàn sí wa lára.+
7 O ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn miJu ti àwọn tó ní ọ̀pọ̀ ọkà àti wáìnì tuntun nígbà ìkórè.
8 Màá dùbúlẹ̀, màá sì sùn ní àlàáfíà,+Nítorí ìwọ nìkan, Jèhófà, ló ń mú kí n máa gbé láìséwu.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “àyè fífẹ̀.”
^ Tàbí “mú kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ yàtọ̀; ya ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀.”