Sáàmù 43:1-5
43 Ṣe ìdájọ́ mi, Ọlọ́run,+Gbèjà mi+ níwájú orílẹ̀-èdè aláìṣòótọ́.
Gbà mí lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti aláìṣòdodo.
2 Nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi, odi ààbò mi.+
Kí nìdí tí o fi ta mí nù?
Kí nìdí tí mo fi ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́ nítorí pé ọ̀tá mi ń ni mí lára?+
3 Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde.+
Kí wọ́n máa darí mi;+Kí wọ́n ṣamọ̀nà mi sí òkè mímọ́ rẹ àti sí àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi.+
4 Nígbà náà, màá wá síbi pẹpẹ Ọlọ́run,+Sọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó jẹ́ ayọ̀ ńlá mi.
Màá sì fi háàpù yìn ọ́,+ ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.
5 Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí* mi?
Kí nìdí tí ìdààmú fi bá ọkàn mi?
Dúró de Ọlọ́run,+Nítorí mo ṣì máa yìn ín torí òun ni Olùgbàlà mi Atóbilọ́lá àti Ọlọ́run mi.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọkàn.”