Sáàmù 53:1-6

  • Irú ẹni tí òmùgọ̀ jẹ́

    • “Kò sí Jèhófà” (1)

    • “Kò sí ẹni tó ń ṣe rere” (3)

Sí olùdarí; lọ́nà ti Máhálátì.* Másíkílì.* Ti Dáfídì. 53  Òmùgọ̀* sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Kò sí Jèhófà.”+ Ìwà àìtọ́ wọn burú, ó sì jẹ́ ohun ìríra;Kò sí ẹni tó ń ṣe rere.+   Àmọ́ Ọlọ́run ń bojú wo àwọn ọmọ èèyàn láti ọ̀run+Láti rí i bóyá ẹnì kan wà tó ní ìjìnlẹ̀ òye, bóyá ẹnì kan wà tó ń wá Jèhófà.+   Gbogbo wọn ti kúrò lójú ọ̀nà;Gbogbo wọn jẹ́ oníwà ìbàjẹ́. Kò sí ẹni tó ń ṣe rere,Kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan.+   Ṣé kò yé ìkankan lára àwọn oníwà burúkú ni? Wọ́n ń ya àwọn èèyàn mi jẹ bí ẹni ń jẹ búrẹ́dì. Wọn ò ké pe Jèhófà.+   Àmọ́, jìnnìjìnnì á bò wọ́n,Irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ sí wọn rí,*Ọlọ́run yóò tú egungun àwọn tó ń gbéjà kò ọ́* ká. Wàá dójú tì wọ́n, nítorí Jèhófà ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.   Ká ní ìgbàlà Ísírẹ́lì lè wá láti Síónì ni!+ Nígbà tí Jèhófà bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà,Kí inú Jékọ́bù dùn, kí Ísírẹ́lì sì yọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Òpònú.”
Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀rù á bà wọ́n níbi tí kò sí ohun tó ń bani lẹ́rù.”
Ní Héb., “tó dó tì ọ́.”