Sáàmù 56:1-13
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Àdàbà Tó Dákẹ́ Tó Jìnnà Réré.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tí àwọn Filísínì mú un ní Gátì.+
56 Ṣojú rere sí mi, Ọlọ́run, nítorí ẹni kíkú ń gbéjà kò mí.*
Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọ́n ń bá mi jà, wọ́n sì ń ni mí lára.
2 Àwọn ọ̀tá mi ń kù gìrì mọ́ mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbéra ga sí mi, tí wọ́n sì ń bá mi jà.
3 Nígbà tí ẹ̀rù ń bà mí,+ mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+
4 Ìwọ Ọlọ́run, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,Ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀rù ò bà mí.
Kí ni èèyàn* lásánlàsàn lè fi mí ṣe?+
5 Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọn ò jẹ́ kí n gbádùn ayé mi;Bí wọ́n ṣe máa ṣe mí léṣe ni wọ́n ń rò ṣáá.+
6 Wọ́n fara pa mọ́ láti gbéjà kò mí;Wọ́n ń ṣọ́ gbogbo ìrìn ẹsẹ̀ mi,+
Kí wọ́n lè gba ẹ̀mí mi.*+
7 Kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ìwà ìkà wọn.
Mú àwọn orílẹ̀-èdè balẹ̀ nínú ìbínú rẹ, Ọlọ́run.+
8 Ò ń kíyè sí bí mo ṣe ń rìn kiri.+
Gba omijé mi sínú ìgò awọ rẹ.+
Ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ?+
9 Àwọn ọ̀tá mi á sá pa dà ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.+
Ó dá mi lójú pé: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.+
10 Ìwọ Ọlọ́run, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,Ìwọ Jèhófà, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,
11 Ìwọ Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀rù ò bà mí.+
Kí ni èèyàn lásánlàsàn lè fi mí ṣe?+
12 Ọlọ́run, ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún ọ dè mí;+Màá rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ.+
13 Nítorí pé o ti gbà mí* lọ́wọ́ ikú,+O ò sì jẹ́ kí n fẹsẹ̀ kọ,+
Kí n lè máa rìn níwájú Ọlọ́run nínú ìmọ́lẹ̀ alààyè.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ń kù gìrì mọ́ mi.”
^ Ní Héb., “ẹran ara.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”