Sáàmù 80:1-19
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Òdòdó Lílì.” Ìránnilétí. Ti Ásáfù.+ Orin.
80 Fetí sílẹ̀, ìwọ Olùṣọ́ Àgùntàn Ísírẹ́lì,Ìwọ tí ò ń darí Jósẹ́fù bí agbo ẹran.+
Ìwọ tí ò ń jókòó lórí* àwọn kérúbù,+Máa tàn yanran.*
2 Níwájú Éfúrémù àti Bẹ́ńjámínì àti Mánásè,Fi agbára ńlá rẹ hàn;+Wá gbà wá là.+
3 Ọlọ́run, mú wa bọ̀ sípò;+Jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa lára, kí a lè rí ìgbàlà.+
4 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ìgbà wo lo máa bínú* sí àdúrà àwọn èèyàn rẹ dà?+
5 O fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,O sì mú kí wọ́n mu omijé tí kò ṣeé díwọ̀n.
6 O jẹ́ kí àwọn aládùúgbò wa máa jà torí kí wọ́n lè borí wa;Àwọn ọ̀tá wa ń fi wá ṣẹ̀sín bó ṣe wù wọ́n.+
7 Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, mú wa bọ̀ sípò;Jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa lára, kí a lè rí ìgbàlà.+
8 O mú kí àjàrà+ kan kúrò ní Íjíbítì.
O lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbin àjàrà náà.+
9 O ro ilẹ̀ fún un,Ó ta gbòǹgbò, ó sì kún ilẹ̀ náà.+
10 Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì bo àwọn igi kédárì Ọlọ́run mọ́lẹ̀.
11 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà títí dé òkun,Àwọn ẹ̀tun rẹ̀ sì dé Odò.*+
12 Kí nìdí tí o fi wó ògiri olókùúta ọgbà àjàrà náà lulẹ̀,+Tí gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ fi ń ká èso rẹ̀?+
13 Àwọn ẹlẹ́dẹ̀ igbó* ń bà á jẹ́,Àwọn ẹranko inú igbó sì ń jẹ ẹ́.+
14 Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, jọ̀wọ́ pa dà.
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì rí i!
Bójú tó àjàrà yìí,+
15 Kùkùté* tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn,+Kí o sì wo ọmọ* tí o sọ di alágbára fún ògo rẹ.+
16 Wọ́n ti dáná sun ún,+ wọ́n sì gé e lulẹ̀.
Nígbà tí o bá wọn wí,* wọ́n ṣègbé.
17 Kí ọwọ́ rẹ fún ọkùnrin tó wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ lókun,Kí ọwọ́ rẹ fi okun fún ọmọ èèyàn tí o sọ di alágbára fún ara rẹ.+
18 Nígbà náà, a kò ní yí pa dà kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
Mú kí á máa wà láàyè, kí a lè máa ké pe orúkọ rẹ.
19 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, mú wa bọ̀ sípò;Jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa lára, kí a lè rí ìgbàlà.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”
^ Tàbí “Fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn.”
^ Ní Héb., “runú.”
^ Ìyẹn, odò Yúfírétì.
^ Tàbí “ìmàdò.”
^ Tàbí “Igi àjàrà.”
^ Tàbí “ẹ̀ka.”
^ Ní Héb., “Nígbà tí ojú rẹ bá wọn wí.”