Sáàmù 89:1-52
Másíkílì.* Ti Étánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì.
89 Títí ayé ni èmi yóò máa kọ orin nípa bí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn.
Màá fi ẹnu mi sọ nípa òtítọ́ rẹ̀ fún gbogbo ìran.
2 Nítorí mo sọ pé: “Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ yóò dúró* títí láé,+O ti mú kí òtítọ́ rẹ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin ní ọ̀run.”
3 “Mo ti bá àyànfẹ́ mi dá májẹ̀mú;+Mo ti búra fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé:+
4 ‘Màá fìdí ọmọ* rẹ+ múlẹ̀ títí láé,Màá gbé ìtẹ́ rẹ ró, á sì wà láti ìran dé ìran.’”+ (Sélà)
5 Àwọn ọ̀run ń yin àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ, Jèhófà,Àní, wọ́n ń yin òtítọ́ rẹ nínú ìjọ àwọn ẹni mímọ́.
6 Ta ló wà ní ọ̀run tí a lè fi wé Jèhófà?+
Èwo nínú àwọn ọmọ Ọlọ́run+ ló dà bíi Jèhófà?
7 Ọlọ́run yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù nínú ìgbìmọ̀* àwọn ẹni mímọ́;+Ó jẹ́ atóbilọ́lá àti ẹni tí ẹ̀rù rẹ̀ ń bani lójú gbogbo àwọn tó yí i ká.+
8 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Ta ló lágbára bí rẹ, ìwọ Jáà?+
Òtítọ́ rẹ yí ọ ká.+
9 Ò ń ṣàkóso ìrugùdù òkun;+Nígbà tí ìgbì rẹ̀ ru sókè, o mú kí ó pa rọ́rọ́.+
10 O ti ṣẹ́gun Ráhábù+ pátápátá bí ẹni tí wọ́n pa.+
O ti fi apá rẹ tó lágbára tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.+
11 Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé;+Ilẹ̀ tó ń méso jáde àti ohun tó kún inú rẹ̀,+ ìwọ lo fìdí wọn múlẹ̀.
12 Ìwọ lo dá àríwá àti gúúsù;Òkè Tábórì+ àti Hámónì+ ń fi ìdùnnú yin orúkọ rẹ.
13 Apá rẹ lágbára;+Ọwọ́ rẹ lókun,+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ga sókè.+
14 Òdodo àti ìdájọ́ òdodo ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;+Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ dúró níwájú rẹ.+
15 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń fi ìdùnnú yìn ọ́.+
Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn.
16 Orúkọ rẹ ń mú inú wọn dùn láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,A sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn,+A sì gbé agbára* wa ga torí pé o tẹ́wọ́ gbà wá.+
18 Apata wa jẹ́ ti Jèhófà,Ọba wa sì jẹ́ ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+
19 Ní àkókò yẹn, o bá àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sọ̀rọ̀ nínú ìran, o ní:
“Mo ti fún alágbára ní okun,+Mo sì ti gbé àyànfẹ́ ga láàárín àwọn èèyàn.+
20 Mo ti rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi;+Mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án.+
21 Ọwọ́ mi yóò tì í lẹ́yìn,+Apá mi yóò sì fún un lókun.
22 Ọ̀tá kankan kò ní gba ìṣákọ́lẹ̀* lọ́wọ́ rẹ̀,Aláìṣòdodo kankan kò sì ní fìyà jẹ ẹ́.+
23 Màá fọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ níwájú rẹ̀,+Màá sì ṣá àwọn tó kórìíra rẹ̀ balẹ̀.+
24 Òtítọ́ mi àti ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,+A ó sì gbé agbára* rẹ̀ ga nítorí orúkọ mi.
25 Màá fi òkun sábẹ́ ọwọ́* rẹ̀,Màá sì fi àwọn odò sábẹ́ ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.+
26 Yóò ké pè mí pé: ‘Ìwọ ni Bàbá mi,Ọlọ́run mi àti Àpáta ìgbàlà mi.’+
27 Èmi yóò fi í ṣe àkọ́bí,+Ẹni tó ga jù lọ nínú àwọn ọba ayé.+
28 Èmi yóò máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn sí i títí láé,+Májẹ̀mú tí mo bá a dá kò sì ní yẹ̀ láé.+
29 Màá fìdí àwọn ọmọ* rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,Màá sì mú kí ìtẹ́ rẹ̀ wà títí lọ bí ọ̀run.+
30 Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa òfin mi tì,Tí wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn àṣẹ* mi,
31 Tí wọ́n bá rú òfin mi,Tí wọn ò sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́,
32 Nígbà náà, màá fi ọ̀pá nà wọ́n nítorí àìgbọ́ràn* wọn,+Màá sì fi ẹgba nà wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
33 Àmọ́ mi ò ní mú ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kúrò lórí rẹ̀ láé,+Mi ò sì ní ṣàì mú ìlérí mi ṣẹ.*
34 Mi ò ní da májẹ̀mú mi,+Mi ò sì ní yí ohun tí ẹnu mi ti sọ pa dà.+
35 Mo ti búra nínú ìjẹ́mímọ́ mi, lẹ́ẹ̀kan láìtún ṣe é mọ́;Mi ò ní parọ́ fún Dáfídì.+
36 Àwọn ọmọ* rẹ̀ yóò wà títí láé;+Ìtẹ́ rẹ̀ yóò wà títí lọ bí oòrùn níwájú mi.+
37 Yóò fìdí múlẹ̀ títí láé bí òṣùpáBí ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé ní ojú ọ̀run.” (Sélà)
38 Àmọ́ ìwọ fúnra rẹ ti tá a nù, o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;+O ti bínú gidigidi sí ẹni àmì òróró rẹ.
39 O ti pa májẹ̀mú rẹ tì, èyí tí o bá ìránṣẹ́ rẹ dá;O ti sọ adé* rẹ̀ di aláìmọ́ bí o ṣe jù ú sílẹ̀.
40 O ti wó gbogbo àwọn ògiri* olókùúta rẹ̀ lulẹ̀;O ti sọ àwọn ibi olódi rẹ̀ di àwókù.
41 Gbogbo àwọn tó kọjá ló kó ẹrù rẹ̀ lọ;Ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.+
42 O ti mú kí àwọn elénìní rẹ̀ borí;*+O ti mú kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ máa yọ̀.
43 Bákan náà, o ò jẹ́ kí idà rẹ̀ wúlò,O ò sì jẹ́ kó rọ́wọ́ mú lójú ogun.
44 O ti mú kí ọlá ńlá rẹ̀ pa rẹ́,O sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀.
45 O ti gé ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ kúrú;O ti fi ìtìjú wọ̀ ọ́ láṣọ. (Sélà)
46 Jèhófà, ìgbà wo lo máa fi ara rẹ pa mọ́ dà? Ṣé títí láé ni?+
Ṣé ìbínú ńlá rẹ yóò máa jó lọ bí iná ni?
47 Rántí bí ọjọ́ ayé mi ṣe kúrú tó!+
Ṣé lásán lo dá gbogbo èèyàn ni?
48 Ta ló wà láàyè tí kò ní kú?+
Ṣé ó lè gba ara* rẹ̀ lọ́wọ́ agbára Isà Òkú ni?* (Sélà)
49 Jèhófà, ibo ni ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti ìgbà àtijọ́ wà,Èyí tí o búra nípa rẹ̀ fún Dáfídì nínú òtítọ́ rẹ?+
50 Jèhófà, rántí ẹ̀gàn tí wọ́n kó bá ìránṣẹ́ rẹ;Bí mo ṣe fara da ẹ̀gàn gbogbo èèyàn;*
51 Jèhófà, rántí bí àwọn ọ̀tá rẹ ṣé ń sọ̀kò ọ̀rọ̀;Bí wọ́n ṣe pẹ̀gàn gbogbo ìṣísẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.
52 Ìyìn ni fún Jèhófà títí láé. Àmín àti Àmín.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “wà.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “àpéjọ.”
^ Ní Héb., “ìwo.”
^ Tàbí “owó òde.”
^ Ní Héb., “ìwo.”
^ Ní Héb., “àṣẹ.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “àwọn ìdájọ́.”
^ Tàbí “ọ̀tẹ̀.”
^ Ní Héb., “Mi ò sì ní parọ́ ní ti òtítọ́ mi.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “dáyádémà.”
^ Tàbí “àwọn àgọ́.”
^ Ní Héb., “O ti gbé ọwọ́ ọ̀tún àwọn elénìní rẹ̀ sókè.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ní ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn, ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “gbé ẹ̀gàn gbogbo èèyàn lé àyà mi.”