May 27–June 2
SÁÀMÙ 42-44
Orin 86 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Máa Fi Ohun Tí Jèhófà Ń Kọ́ Wa Sílò
(10 min.)
Máa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará lójúkojú tó bá ti lè ṣeé ṣe tó (Sm 42:4, 5; w06 6/1 9 ¶4)
Kọ́kọ́ gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (Sm 42:8; w12 1/15 15 ¶2)
Máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe (Sm 43:3)
Ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa, ká sì dúró lórí ìpinnu tá a ṣe nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà.—1Pe 5:10; w16.09 5 ¶11-12.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 44:19—Kí ló ṣeé ṣe kí onísáàmù náà ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “níbi tí àwọn ajáko ń gbé”? (it-1 1242)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 44:1-26 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(5 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Pe ẹni náà wá sí àsọyé fún gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ máa gbọ́ lọ́sẹ̀ yẹn. Fi fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀ (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 5)
6. Àsọyé
(3 min.) lmd àfikún A kókó 4—Àkòrí: Ara Gbogbo Èèyàn Máa Jí Pépé. (th ẹ̀kọ́ 2)
Orin 21
7. Bó O Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Dáa Tó Bá Dọ̀rọ̀ Iṣẹ́ àti Ilé Ẹ̀kọ́
(15 min.) Ìjíròrò.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ẹ ti ń ronú ohun tẹ́ ẹ máa ṣe tẹ́ ẹ bá parí ilé ìwé? Ó ṣeé ṣe kó o ti ní iṣẹ́ kan lọ́kàn tó máa jẹ́ kó o lè ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó sì ṣeé ṣe kó o ti máa ronú irú iṣẹ́ tó wù ẹ́ láti kọ́, tàbí àfikún ẹ̀kọ́ tó o lè gbà tí wọ́n á sì fún ẹ ní ìwé ẹ̀rí tó o fi máa rí irú iṣẹ́ tó wù ẹ́ láti ṣe. Ká sòótọ́, inú ẹ lè máa dùn bó o ṣe ń fojú sọ́nà fún àkókò yẹn. Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti ṣèpinnu, àwọn èèyàn sì lè máa rọ̀ ẹ́ lọ́tùn-ún lósì pé kó o yan ohun tí wọ́n ronú pé ó dáa jù fún ẹ. Kí lá jẹ́ kó o ṣèpinnu tó dáa?
Ka Mátíù 6:32, 33. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí nìdí tó fi yẹ kó o kọ́kọ́ pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kó o tó yan irú iṣẹ́ tó o máa ṣe tàbí tó o máa kọ́?
-
Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn inú Mátíù 6:32, 33 sílò?—Sm 78:4-7
Ṣọ́ra kó má lọ jẹ́ torí àti ríṣẹ́ táá máa mówó ńlá wọlé tàbí torí àtidi gbajúmọ̀ lo fi máa pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe. (1Jo 2:15, 17) Má gbàgbé pé, téèyàn bá lówó rẹpẹtẹ, ìyẹn lè mú kó ṣòro fún un láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. (Lk 18:24-27) Tẹ́nì kan bá ń lé bó ṣe máa di olówó, á ṣòro fún un láti pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn Jèhófà, kó sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Mt 6:24; Mk 8:36.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Má Ṣe Gbọ́kàn Lé Àwọn Nǹkan Tó Máa Dópin!—Ọrọ̀. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí ni Òwe 23:4, 5 sọ táá jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó dáa?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 10 ¶5-12