Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ “Jẹ́ Kí Àwọn Nǹkan Tó Wà Báyìí Tẹ́ Yín Lọ́rùn”

Ẹ “Jẹ́ Kí Àwọn Nǹkan Tó Wà Báyìí Tẹ́ Yín Lọ́rùn”

Tí owó tó ń wọlé fún wa ò bá tó nǹkan, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká lọ́wọ́ sí àwọn ohun kan. Àwọn nǹkan náà sì lè mú ká jìnnà sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí iṣẹ́ tó máa mówó gọbọi wọlé àmọ́ tí kò ní jẹ́ ká ráyè fáwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Tá a bá ronú lórí Hébérù 13:​5, ó máa jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó tọ́.

“Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín”

  • Gbàdúrà, kó o wá ronú nípa bó o ṣe máa ń ṣe tó bá ti kan ọ̀rọ̀ owó. Lẹ́yìn náà, ronú nípa àpẹẹrẹ tó ò ń fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ.—g 11/15 6.

“Bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn”

  • Fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó o nílò gan-an.—w16.07 7 ¶1-2.

“Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé”

  • Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún ẹ tó o bá ń fi ire Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́.—w14 4/15 21 ¶17.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ, ỌKÀN ÀWỌN ARÁ WA BALẸ̀ BÍ WỌ́N TIẸ̀ Ń DOJÚ KỌ ÌṢÒRO ÀÌLÓWÓ LỌ́WỌ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Kí lo rí kọ́ nínú ìrírí Miguel Novoa?