Ètò Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tó Kárí Ayé
Ètò Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tó Kárí Ayé
“Àwọn tó mọ̀wé nìkan ló dòmìnira.”—Epictetus, c. 100 C.E.
WILLIAM H. Seward, alákitiyan nídìí ọ̀ràn fífòpin sí òwò ẹrú ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún gbà gbọ́ pé “gbogbo ìrètí ẹ̀dá ènìyàn fún ìtẹ̀síwájú sinmi lé ipa tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i tí Bíbélì ń ní.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ń fi ọ̀wọ̀ tó ga fún Bíbélì. Ó dá wọn lójú gidi pé àwọn tó bá fi ìlànà rẹ̀ sílò máa ń di ọkọ, aya, àti àwọn ọmọ tó ní láárí—bẹ́ẹ̀ ni o, ó ń sọ wọ́n di èèyàn tó dára jù lọ láyé. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù Kristi náà pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn.”—Mátíù 28:19, 20.
Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń sapá láti kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí, wọ́n dáwọ́ lé ohun kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó tíì gbòòrò jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Báwo ló ti gbòòrò tó?
Iṣẹ́ Ìtẹ̀wé Kan Tó Kárí Ayé
Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń lo àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó wà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Àmọ́ o, wọ́n tún ti mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè mọ́kànlélógún àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (èyí tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun) ní èdè mẹ́rìndínlógún mìíràn. Bákan náà, wọ́n ń báṣẹ́ títú Bíbélì yìí sí èdè mọ́kànlá mìíràn lọ lọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí tún ń pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń mú kí ìmọrírì fún Bíbélì pọ̀ sí i, tó sì ń mú kí lílóye rẹ̀ túbọ̀ rọrùn sí i.
Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà yìí, Jí!, ni wọ́n ń tẹ̀ ní èdè méjìlélọ́gọ́rin, ó sì ju ìpíndọ́gba ogun mílíọ̀nù ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà okòó dín nírínwó [20,380,000] tí wọ́n ń tẹ̀ jáde nínú ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan. Ilé Ìṣọ́, tó jẹ́ èkejì rẹ̀, ni ìpíndọ́gba iye tí a ń tẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìdínnírínwó [22,398,000] ẹ̀dà, ní èdè mẹ́tàdínlógóje [137]. Èyí túmọ̀ sí títẹ ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan ẹ̀dà àwọn ìwé ìròyìn yìí lọ́dọọdún! Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n tún ń tẹ Ilé Ìṣọ́ ní èdè mẹ́rìnlélọ́gọ́fà, wọ́n sì ń tẹ Jí! ní èdè méjìdínlọ́gọ́ta nígbà kan náà tí ti èdè Gẹ̀ẹ́sì ń jáde. Nítorí náà, àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè ń ka ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà yìí nígbà kan náà ní èdè tiwọn gangan.
Láfikún sí i, láwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dà àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde. Ẹ̀dà ìwé náà, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, iye tí a tẹ̀ jáde lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàdínláàdọ̀fà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ẹ̀dà ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ni a tẹ̀ jáde ni iye tí ó lé ní mílíọ̀nù mọ́kànlélọ́gọ́rin, àti láìpẹ́ yìí, ó ti lé ní mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin ẹ̀dà ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun tí a tẹ̀ jáde ní èdè mẹ́rìndínláàádọ́jọ. Bákan náà, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàléláàádọ́fà ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tí a ti tẹ̀ jáde ní òjìlélúgba [240] èdè.
Wọ́n tún ṣe àwọn ìwé kan láti kúnjú àwọn àìní pàtàkì kan. Iwe Itan Bibeli Mi, èyí tí wọ́n ṣe fún àwọn ọmọdé, iye tí a tẹ̀ ti wọ mílíọ̀nù mọ́kànléláàádọ́ta. Àwọn ìwé méjì tí wọ́n ṣe nítorí àwọn ọ̀dọ́langba, ìyẹn Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ àti Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ni iye tí a tẹ lápapọ̀ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́tàléláàádọ́ta. Bákan náà ni Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, èyí tó ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìdílé lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro wọn kò gbẹ́yìn, a ti tẹ òun náà ní èdè márùndínlọ́gọ́fà.
Àwọn ìtẹ̀jáde mẹ́rin mìíràn táa mú jáde láti ọdún 1985, tí wọ́n ń gbé ìgbàgbọ́ ró ní pàtàkì nínú Ẹlẹ́dàá náà, Ọmọ rẹ̀, àti nínú Bíbélì ni àpapọ̀ iye tí a tẹ̀ lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàdínláàádọ́fà ẹ̀dà. Àwọn wọ̀nyí ni Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, The Bible—God’s Word or Man’s?, àti Is There a Creator Who Cares About You?
Lónìí, àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé kárí Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú jáde wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ọ̀tàlélọ́ọ̀dúnrún ó dín méje èdè [353], díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí yóò sì tún jáde láìpẹ́ ní èdè méjìdínlógójì sí i. Ní tòótọ́, ohun tó ju ogún bílíọ̀nù àwọn ìwé ńlá, ìwé kékeré, ìwé pẹlẹbẹ, àti àwọn ìwé ìròyìn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ láti ọdún 1970 wá! Kò tán síbẹ̀ o, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn olùkọ́ tí ọwọ́ wọn dí nínú mímú ìmọ̀ Bíbélì tọ àwọn èèyàn lọ ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n [230]. Àmọ́ báwo ni gbogbo èyí ti ṣeé ṣe, báwo ló sì ṣe nípa lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn?
Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Tẹ Àwọn Ìwé Náà Ní Èdè Abínibí
Bí ìwọ náà ṣe lè fojú inú wò ó, ìsapá gígọntiọ, èyí táa mójú tó dáadáa ló ń béèrè láti mú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ojúlówó jáde, lóhun tó ju ọgọ́rùn-ún èdè lọ nígbà kan náà. Àwọn ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè, tí wọ́n ti yọ̀ǹda àkókò wọn àti òye iṣẹ́ wọn, ń lo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà láti ṣe iṣẹ́ tó jẹ́ ojúlówó, tó péye, tó sì yá kánkán. Nípa bẹ́ẹ̀, a ń ṣe àwọn ìwé jáde lẹ́yẹ-ò-sọkà láwọn èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn olùtumọ̀ tó pọ̀ tó pàápàá. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ó lé ní àádọ́ta dín lẹ́gbàá [1,950] àwọn ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ kárí ayé yìí, tí kì í ṣe nítorí àtijèrè níbẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí kí ni wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí? Ṣé ó tiẹ̀ tó ohun tí a ń rúnpá rúnsẹ̀ sí ni, nígbà tó jẹ́ pé púpọ̀ àwọn tó ń sọ èdè táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ náà ló tún gbọ́ èdè gidi mìíràn?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí ohun kan náà tí William Tyndale, olùtumọ̀ Bíbélì tí òkìkí rẹ̀ kàn ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, tọ́ka sí. Ó kọ̀wé pé: “Mo ti rí i látinú ìrírí bí kò ṣe rọrùn rárá láti kọ́ àwọn èèyàn gbáàtúù ní òtítọ́ èyíkéyìí kí òtítọ́ sì fìdí múlẹ̀ nínú wọn, àyàfi bí wọ́n bá ní Ìwé Mímọ́ lédè tiwọn, kí wọ́n lè rí kókó inú rẹ̀, bí ìṣètò rẹ̀ ṣe bára jọ, àti ìtumọ̀ tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ní.”
Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń ṣeé
ṣe pé káwọn èèyàn ní àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì ni èdè ìbílẹ̀ wọn. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá ní wọn, òtítọ́ Bíbélì sábà máa ń tètè wọ̀ wọ́n lọ́kàn, ó sì máa ń fìdí múlẹ̀. A ti kíyè sí èyí ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́, níbi táwọn ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ń sọ àìmọye èdè ìbílẹ̀. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tó kọjá, púpọ̀ lára àwọn èèyàn yìí ni wọ́n sọ di ará Soviet Union, tí wọ́n kọ́ wọn ní èdè Russian—wọ́n sì sọ ọ́ di dandan fún wọn pé kí wọ́n máa sọ èdè náà. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń kàwé, wọ́n sì ń kọ̀wé lédè Russian, síbẹ̀, wọ́n ń sọ èdè àbínibí wọn.Ní pàtàkì jù lọ, látìgbà tí Soviet Union ti ṣubú ní ọdún 1991 ni púpọ̀ lára àwọn èèyàn yìí ti fẹ́ láti máa sọ èdè àbínibí wọn. Bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn fáwọn tó ń sọ èdè Adyghe, Altai, Belorussian, Georgian, Kirghiz, Komi, Ossetian, Tuvinian, tàbí èyíkéyìí lára ọ̀pọ̀ jaburata èdè tó kù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló lè fi èdè Russian báni sọ̀rọ̀, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n fi èdè Russian kọ kì í tètè wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Àmọ́ o, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá fi èdè àdúgbò wọn kọ máa ń ru wọ́n sókè gan-an. Ẹnì kan tó gba ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì ní èdè Altai sọ pé: “Ó mà dára o, pé ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí i ṣe ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde ní èdè wa.”
Àpẹẹrẹ mìíràn tún ni ìlú Greenland, erékùṣù kan tó jẹ́ ilẹ̀ Olótùútù nini, tí àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta péré. Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ni a ń tẹ̀ ní èdè Greenlandic, àwọn ìwé ìròyìn náà sì gbayì gan-an ni—bẹ́ẹ̀ sì tún làwọn ìtẹ̀jáde mìíràn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ ní èdè Greenlandic náà. Ká sòótọ́, a lè rí irú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilé tó wà láwọn abúlé tó jìnnà réré ní erékùṣù náà.
Ní Gúúsù Pàsífíìkì, èdè Nauruan ni nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje èèyàn ń sọ, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [4,500] ń sọ Tokelauan, àwọn tó sì ń sọ Rotuman jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá. Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń tẹ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì àti ìwé pẹlẹbẹ jáde báyìí ní àwọn èdè yẹn títí kan Ilé Ìṣọ́ ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù ní èdè Niuean tí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ èèyàn ń sọ, àti ní èdè Tuvaluan tí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá èèyàn ń sọ. Kì í ṣe àsọdùn rárá pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òǹṣèwé tó ń tẹ ìwé púpọ̀ gan-an jáde láwọn èdè tí kò gbajúmọ̀, tí wọ́n ń ṣe ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láwọn èdè bíi Bislama, Hiri Motu, Papiamento, Mauritian Creole, èdè New Guinea táa mú rọrùn, Creole ti Seychelles, èdè Solomon Islands táa mú rọrùn, àti ọ̀pọ̀ àwọn èdè mìíràn.
Lọ́pọ̀ ìgbà, bí àwọn tó ń sọ èdè kan bá ṣe kéré sí, bẹ́ẹ̀ ni ibi tí wọ́n ń gbé ṣe máa ń jẹ́ àdádó sí, tí wọ́n sì máa ń tòṣì tó. Síbẹ̀, àwọn tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà ládùúgbò náà lè pọ̀. Bíbélì tí wọ́n fi èdè wọn kọ sì máa ń jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé díẹ̀ tó máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn olùgbé ibẹ̀. Àní sẹ́, wọn kì í tẹ ìwé ìròyìn kankan jáde nínú díẹ̀ lára àwọn èdè wọ̀nyí, nítorí mímu un jáde á gbọ́n owó lọ.
Ìdí Táwọn Èèyàn Fi Mọyì Iṣẹ́ Náà
Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń jẹ́ kí ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà gbé ìgbésí ayé túbọ̀ sàn sí i, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti yìn wọ́n fún ìsapá wọn nínú ìtumọ̀ tí wọ́n ń ṣe. Linda Crowl, òṣìṣẹ́ kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Nípa Ilẹ̀ Pàsífíìkì, èyí tó wà ní Yunifásítì ti Gúúsù Pàsífíìkì ní Suva, Fiji, sọ nípa bí iṣẹ́ ìtumọ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ṣe jẹ́ “ohun tí ń mórí ẹni yá gan-an tó ń ṣẹlẹ̀ ní Pàsífíìkì.” Ó dámọ̀ràn àwọn ìtẹ̀jáde wọn fún lílò nítorí bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó.
Nígbà tí Jí! ẹlẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún bẹ̀rẹ̀ sí í jáde í! hàn, wọ́n sì ṣí àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé ìròyìn náà níkọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé wọn yẹ̀ wò níkọ̀ọ̀kan.
lédè Samoan, àwọn ìwé ìròyìn àdúgbò náà, títí kan ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ìjọba gbé ìròyìn nípa rẹ̀ jáde. Nígbà tí ìròyìn náà ń lọ lọ́wọ́, wọ́n fi èèpo ẹ̀yìn JNí pàtàkì jù lọ, láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn àjọ tó ń bójú tó ọ̀ràn nípa èdè àdúgbò máa ń lọ ṣèwádìí déédéé lọ́dọ̀ àwọn tó ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n máa ń wádìí nípa gírámà, àkọtọ́, ṣíṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣe kedere pé, iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́ ti nípa lórí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ju kìkì lórí ìgbésí ayé àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ wọn lọ.
Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan àwọn àgbàlagbà—iye tó kù díẹ̀ kó tó ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà àwọn olùgbé ayé—tí wọn kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Kí ni a ti ṣe láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú ìsọfúnni pàtàkì náà, èyí tó jẹ́ pé kìkì nípa kíkàwé àti kíkẹ́kọ̀ọ́ nìkan lọ́wọ́ fi lè tẹ̀ ẹ́?
Bíbójútó Àwọn Ọ̀ràn Ẹ̀kọ́ Tó Ṣe Pàtàkì
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣe ètò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà lọ́fẹ̀ẹ́, wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn láti lè kàwé kí wọ́n sì tún kọ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n tiẹ̀ tún ti ṣe àwọn ìwé atọ́nà tiwọn fúnra wọn, irú bíi ìtẹ̀jáde náà, Apply Yourself to Reading and Writing, èyí tí wọ́n ti mú jáde ní èdè méjìdínlọ́gbọ̀n. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn, títí kan àwọn obìnrin àtàwọn àgbàlagbà, ni wọ́n ti ràn lọ́wọ́ láti di ẹni tó mọ̀ọ́kọ, tó sì mọ̀ọ́kà nípasẹ̀ àwọn kíláàsì wọ̀nyí.
Ní Burundi, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti darí àwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, èyí tó ti ran ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lè kàwé kí wọn sì tún kọ̀wé. Lẹ́yìn tí Ilé Iṣẹ́ Àbójútó Ètò Ẹ̀kọ́ Àgbà ní Orílẹ̀-Èdè náà yẹ àwọn ìyọrísí rere tí ìṣètò yìí ní wò, ó fi ẹ̀bùn dá àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rin lọ́lá, àwọn tí wọ́n jẹ́ olùkọ́ ní Àyájọ́ Ọjọ́ Mọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà Lágbàáyé, ní September 8, 1999.
Ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí la rí gbà nípa àwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mòsáńbíìkì, ó sọ pé: “Láàárín ọdún mẹ́rin tó ti kọjá, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [5,089] ló ti kẹ́kọ̀ọ́ yege, ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin mìíràn sì ti forúkọ sílẹ̀.” Akẹ́kọ̀ọ́ kan kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ fi ìmọrírì àtọkànwá mi hàn fún iléèwé náà . . . N kò mọ dò tẹ́lẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ iléèwé náà, mo ti lè kàwé báyìí, mo ti lè kọ̀wé
pẹ̀lú bó tilẹ̀ jẹ́ pé mó ṣì nílò ìdánrawò sí i.”Láti 1946, tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí i ṣe àkọsílẹ̀ ní Mẹ́síkò, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógóje [143,000] ènìyàn níbẹ̀ tí wọ́n ti kọ́ báa ti ń kàwé àti báa ti ń kọ̀wé ní àwọn àkànṣe iléèwé táa dá sílẹ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn. Obìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta kọ̀wé pé: “Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n kọ́ mi báa ti ń kàwé àti báa ṣe ń kọ ọ́ sílẹ̀. Ìgbésí ayé mi ti dojú rú tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, mo lè lọ sínú Bíbélì fún ìmọ̀ràn, mo sì ti rí ayọ̀ nínú ìsọfúnni rẹ̀.”
Bákan náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láti mọ̀ọ́kọ kí wọ́n sì mọ̀ọ́kà ní orílẹ̀-èdè Brazil, ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Obìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta sọ pé: “Ńṣe ni mímọ ìwé kà dà bí ìgbà tí wọ́n tú ẹ̀wọ̀n tí wọn ti fi di èèyàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Mo ti wá láǹfààní láti ka oríṣiríṣi ìsọfúnni báyìí. Ṣùgbọ́n èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn máa ń ran olúkúlùkù àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn lọ́wọ́ láti mọ̀wé kà. Ní Philippines, Martina ti lé lọ́gọ́rin ọdún nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan kàn sí i. Martina fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, àmọ́ kò lè kàwé. Pẹ̀lú ìrànwọ́ ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Martina bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú, bó sì ti ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kún un nínú ìjọ àdúgbò náà, ó dẹni tó tóótun láti fi Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Lónìí, ó ti di olùkọ́ Bíbélì alákòókò kíkún tó mọ̀wé kà, tó sì mọ̀ọ́kọ.
A ti rí i pé gbogbo èèyàn ló ṣeé ṣe fún láti mọ̀ọ́kọ kí wọ́n sì mọ̀ọ́kà. Síbẹ̀, a wá lè béèrè pé, Ǹjẹ́ ìmọ̀ tó tinú Bíbélì wá, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn ète rẹ̀ tiẹ̀ ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní ní ti gidi? Èyí tó kẹ́yìn nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
“Ó Kọjá Nǹkan Tí Mo Lè Fẹnu Sọ . . . ”
Àwọn aláṣẹ ìjọba, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, àtàwọn mẹ̀kúnnù, gbogbo wọn ló ti kíyè sí ìsapá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bí wọ́n ti ń sapá láti kọ́ gbogbo èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ káàkiri ayé. Àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ohun táwọn èèyàn sọ rèé:
“Èmi àti ìjọba mi láyọ̀ gan-an ni, nítorí pé ìwé yìí [Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ní èdè Tuvaluan] tún ti jẹ́ àfikún tuntun tó sì ṣe pàtàkì sí ‘búrùjí’ ilẹ̀ Tuvalu. Ó yẹ kí inú yín dùn gan-an ni fún ipa tí ẹ ti kó—ipa títayọ yín nínú gbígbé àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè yìí ró nípa tẹ̀mí. Ó dá mi lójú pé a óò kọ ọ̀rọ̀ nípa ìwé yìí sínú ìtàn Tuvalu lórí ọ̀ràn tó dá lé títẹ àwọn ìwé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ jáde.”—Dókítà T. Puapua, olórí ìjọba tẹ́lẹ̀ fún Tuvalu, Gúúsù Pàsífíìkì.
“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìṣètò ìtẹ̀wé tó múná dóko, wọ́n ń lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó tíì péye jù lọ ní Gúúsù Pàsífíìkì. . . . Itú tí wọ́n ń pa nínú iṣẹ́ ìtẹ̀wé yìí tún wá kàmàmà téèyàn bá wo ọ̀pọ̀ jaburata ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ lóríṣiríṣi . . . tó kún àwọn erékùṣù Pàsífíìkì fọ́fọ́.”—Linda Crowl, Yunifásítì ti Gúúsù Pàsífíìkì, Suva, Fiji.
“Ẹ wo bí ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé ní èdè Ísókó ti jẹ́ àgbàyanu tí ó sì lágbára tó! A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtumọ̀ èdè Ísókó fún ríràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìwé náà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.”—C.O.A., Nàìjíríà.
“Bí ìmọrírì mi ṣe tó fún títú tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì [Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Serbian], lọ́nà tó rọrùn láti lóye kọjá nǹkan tí mo lè fẹnu sọ. Ìgbà kan wà tí mo gbìyànjú láti ka gbogbo Bíbélì lódindi, àmọ́, mo rí i pé kíákíá ni mo máa ń gbé e sílẹ̀ nítorí pé èdè tí wọ́n fi kọ ọ́ kò yé mi. Ó ti wá ṣeé ṣe fún mi báyìí láti ka ìtumọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ yìí, kí n sì lóye rẹ̀!”—J. A., Yugoslavia.
“Ẹ ṣe gan-an ni fún àwọn ìtẹ̀jáde àtàtà yẹn, tí wọ́n kún fún ìsọfúnni tí wọ́n sì ń gbéni ró tí ẹ túmọ̀ sí èdè Tiv. Kí ń sòótọ́, mi ò mọ bí mo ṣe lè sọ gbogbo àǹfààní àti ìṣírí tó ń wá látinú àwọn ìwé ńlá àtàwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ti tẹ̀ lọ́wọ́.”—P.T.S., Nàìjíríà.
[Àwòrán]
Mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógójì ẹ̀dà, ní èdè márùndínlọ́gọ́fà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ẹ̀dà “Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” táa ti tẹ̀ jáde ní èdè mẹ́tàdínlógójì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì èèyàn tó ń kópa nínú títúmọ̀ àwọn ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé. (àwùjọ àwọn tó ń túmọ̀ sí èdè Zulu ní Gúúsù Áfíríkà, lápá òsì; àti ẹni tó ń túmọ̀ èdè Japanese, nísàlẹ̀)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ó lé ni bílíọ̀nù kan ìwé ìròyìn “Ilé Ìṣọ́” àti “Jí!” tí a ń tẹ̀ lọ́dọọdún
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Káàkiri ayé ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń darí kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. (Mẹ́síkò, lápá ọ̀tún; àti Burundi, nísàlẹ̀)