“Ìlù Onígba-Ohùn”
“Ìlù Onígba-Ohùn”
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SENEGAL
“ÓLÈ fọhùn bíi màlúù, ó lè dún kangó-kangó, ó sì tún lè ké rara. Ó máa ń dún kangẹ̀-kangẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì tún ń kọrin. . . . Ìlù onígba-ohùn là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀.” Kí lohun náà gan-an tó ń jọ òǹkọ̀wé yìí lójú? Ìlù àfọwọ́lù ilẹ̀ Áfíríkà tó ń jẹ́ djembe ni o.
Ìlù djembe ṣe pàtàkì gan-an nínú àṣà ìlù lílù àwọn ẹ̀yà kan ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń lu ìlú djembe níbi onírúurú ayẹyẹ tó jẹ mọ́ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, irú bí ìgbéyàwó, ìsìnkú, ọmọ bíbí, àjọ̀dún, ìkórè, àti nígbà téèyàn bá ra aṣọ tuntun pàápàá.
Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ń gba ṣe ìlù djembe. Àní, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè bíi Burkina Faso, Guinea, Málì, àti Senegal ló ní ìlù djembe tiwọn, tí ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe wọ́n sì yàtọ̀ síra wọn. Igi tí a gbẹ́ inú rẹ̀ ni a fi ń ṣe ìlú yìí. Iṣẹ́ ọ̀nà tí wọ́n ń ṣe sára àwọn kan kì í pọ̀ nígbà tí àwọn mìíràn sì máa ń ní iṣẹ́ ọ̀nà rẹpẹtẹ.
Tí wọ́n bá ti gbẹ́ inú igi náà jáde tán, ẹnì kan tó mọ ìlù ṣe dáadáa yóò wá sọ ohun tó jẹ́ igi lásán yìí di ohun èlò ìkọrin aláìlẹ́gbẹ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹni tó ń ṣe ìlù náà yóò gbẹ́ igi náà dáadáa, yóò fá a, yóò sì máa fi nǹkan dán an títí tí yóò fi lè mú irú ohùn tó fẹ́ jáde. Oníṣẹ́ ọnà yìí tún lè fi epo pupa pa inú ìlù náà, yóò sì wá sá a sóòrùn. Èyí ló máa jẹ́ kí ẹ̀mí igi tí wọ́n fi ṣe é tọ́jọ́.
Ara ewúrẹ́ ni wọ́n ti máa ń rí awọ tí wọ́n ń fi ṣe ìlù djembe. Wọ́n á fi irin sí etí awọ náà, kí wọ́n tóó fi bo orí ìlù náà. Ohun tó máa ń jẹ́ kó dúró dáadáa ni pé wọ́n máa ń to àwọn awọ tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, èyí tó ń jẹ́ ọṣán, yí ìlù náà ká, wọ́n á sì wá fi wọ́n kọ́ àwọn irin méjì mìíràn. Báwo ni ẹni tó ń ṣe ìlù náà ṣe máa wá fa àwọn okùn náà le tó? Ó sinmi lórí irú ohùn tó bá fẹ́ kó máa mú jáde. Bí oníṣẹ́ ọnà náà ṣe ń fa awọ náà le, bẹ́ẹ̀ ni yóò máa lu ìlù náà wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti mọ̀ bóyá ó ti ń mú irú ohùn tó fẹ́ jáde.
Ìlù djembe máa ń gbádùn mọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ Áfíríkà àtàwọn àlejò tó ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ gan-an. Àní, tó o bá ṣe kòńgẹ́ àkókò tí àwọn òṣèré tó mọwọ́ ìlù yìí bá ń ṣeré níbì kan, o ò ní gbà gbé “ìlù onígba-ohùn” yìí.