Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Amágẹ́dọ́nì?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Amágẹ́dọ́nì?
KÍ NI “Amágẹ́dọ́nì”? Láìdéènà pẹnu, ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ báwọn alákòóso ayé ṣe ń kóra jọ láti dojú ìjà kọ Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ lábẹ́ àkóso Jésù Kristi. Bá a ṣe rí i nínú ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ Ìṣípayá, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan nípa báwọn alákòóso ayé ti kóra jọ sí ibi ìṣàpẹẹrẹ kan tó ń jẹ́ Amágẹ́dọ́nì láti bá Ọlọ́run jà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ náà, “Amágẹ́dọ́nì” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́, síbẹ̀ nínú àwọn èdè kan, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ni wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ náà perí oríṣiríṣi nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń pe ìpẹ̀yàrun ní Amágẹ́dọ́nì, wọ́n máa ń pe fáírọ́ọ̀sì tó ń da kọ̀ǹpútà láàmù bẹ́ẹ̀. Àní, wọ́n ti fi Amágẹ́dọ́nì perí àjálù ńláńlá àti kéékèèké rí. Wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ ìwé tó dá lórí ohun tí wọ́n pè ní òpin ayé tàbí àkókò tó máa ṣáájú Amágẹ́dọ́nì, wàràwàrà làwọn ìwé náà sì tà. Nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa kókó yẹn, ó lé ní ọgọ́ta mílíọ́nù ẹ̀dà táwọn èèyàn ti rà láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá.
Àwọn kan ń bẹ̀rù Amágẹ́dọ́nì. Wọ́n rò pé ó ṣeé ṣe káwọn apániláyà tàbí, àwọn orílẹ̀-èdè arógunyọ̀ fa àjálù, tàbí kí jàǹbá kan tó kọjá agbára èèyàn dédé ṣẹlẹ̀, táá sì ba ayé jẹ́ débi tí kò ti ní ṣeé ṣe fún ẹ̀dá alààyè láti wà nínú ẹ̀ mọ́. Àwọn míì gbà pé tákòókò bá tó lójú Ọlọ́run, á fìbínú pa ayé wa yìí àti gbogbo nǹkan tó wà nínú ẹ̀ run. Bó bá wá jẹ́ ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú rèé, ó tó ohun tó lè mọ́kàn èèyàn pami! Àmọ́, kí wá ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ní Amágẹ́dọ́nì?—Ìṣípayá 16:14, 16.
Ṣé Ayé Máa Pa Run àbí Kò Ní Pa Run?
Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa pa run ní Amágẹ́dọ́nì o. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Bíbélì fi dá wa lójú pé “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.” (2 Pétérù 2:9) Látàrí ọ̀rọ̀ yìí, ó yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ò ní ṣi agbára ńlá rẹ̀ lò. Kìkì àwọn tí kò gba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ láyé àti lọ́run ló máa fojú winá ìbínú Rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì. Ogun náà ò ní pa àwọn aláìṣẹ̀.—Sáàmù 2:2, 9; Jẹ́nẹ́sísì 18:23, 25.
Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) A wá lè rí i kedere báyìí pé kò sí lọ́kàn Jèhófà Ọlọ́run láti pa ilé ayé wa run. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn èèyànkéèyàn tó ń ta ko ìṣàkóso rẹ̀ láàárín àwọn ọmọ aráyé ló máa gbá kúrò. Ńṣe ló máa dà bí ohun tó ṣe nígbà Àkúnya Omi ọjọ́ Nóà.—Jẹ́nẹ́sísì 6:11-14; 7:1; Mátíù 24:37-39.
“Ọjọ́ Amúnikún-fún-Ẹ̀rù”
Ká sóòótọ́, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ìparun tó ń bọ̀ yìí tó ohun tó ń bani lẹ́rù. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Jóẹ́lì sọ bí “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” ṣe máa rí. (Jóẹ́lì 2:31) Lára nǹkan ìjà tó wà nínú àká agbára Ọlọ́run ni ìrì dídì, yìnyín, ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àgbáàràgbá òjò, òjò iná àti imí ọjọ́, ìdàrúdàpọ̀ aṣekúpani, mànàmáná àti àrùn lùkúlùkú. a (Jóòbù 38:22, 23; Ìsíkíẹ́lì 38:14-23; Hábákúkù 3:10, 11; Sekaráyà 14:12, 13) Bíbélì tún ṣàlàyé kedere nípa àkókò tí òkú èèyàn á kún orí ilẹ̀ ayé, tí ò ní sí pé à ń sin wọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n á wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ajílẹ̀ fún ilẹ̀ tàbí bí oúnjẹ fáwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko míì. (Jeremáyà 25:33, 34; Ìsíkíẹ́lì 39:17-20) Ṣòkòtò á mà ṣòdí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run nígbà tí ogun yìí bá dé o.—Ìṣípayá 6:16, 17.
Ṣé ohun tá à ń sọ níbí yìí ni pé ó yẹ káwọn onígbọràn tó ń sin Ọlọ́run máa bẹ̀rù àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì ni? Ó tì o, nítorí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò ní nípìn-ín nínú gídígbò yẹn. Bákan náà, ààbò Jèhófà lórí wọn dájú. Síbẹ̀, ẹ̀rú Ọlọ́run á ba àwọn olùjọsìn tòótọ́ nígbà tí wọ́n bá rí i tí Ọlọ́run ń lo agbára amúnikún-fún-ẹ̀rù rẹ̀.—Sáàmù 37:34; Òwe 3:25, 26.
Àmọ́ ṣá o, ẹ wo bí ohun tí Jèhófà mí sí àpọ́sítélì Jòhánù láti kọ ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ ná. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́,” tó fi mọ́ ìkìlọ̀ nípa Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 1:3; 22:7) Ṣé ìyẹn ni pé téèyàn bá ń ṣàṣàrò lórí Amágẹ́dọ́nì, ó lè máa láyọ̀? Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?
Ọlọ́run Ń Kìlọ̀
Nígbà tí ìjì líle kan bá fẹ́ jà, ìjọba tó ń ṣàkóso àdúgbò tí ìjì náà ti fẹ́ jà máa ń kìlọ̀ fáwọn ara ibẹ̀, láti lè gba ẹ̀mí wọn là. Kí gbogbo èèyàn bàa lè gbọ́ kí wọ́n sì wà lójúfò, wọ́n lè rán àwọn ọlọ́pàá láti lọ máa kìlọ̀ fáwọn èèyàn, tàbí láti máa lọ láti ojúlé dé ojúlé. Torí àtidẹ́rù ba àwọn èèyàn kọ́ ni wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo kìlọ̀kìlọ̀ yìí o, ṣe ni wọ́n ń fi ìkìlọ̀ náà rọ̀ wọ́n láti wá nǹkan ṣe kí wọ́n má bàa pàdánú ẹ̀mí wọn. Àwọn tó bá lóye nínú àwọn èèyàn yẹn á gba ìkìlọ̀ náà tayọ̀tayọ̀, inú àwọn tó bá sì gbàkìlọ̀ náà á dùn pé àwọn ò fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́.
Bọ́rọ̀ iṣẹ́ ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run ń rán sáwọn èèyàn nípa “ẹ̀fúùfù oníjì” tí ò ní pẹ́ jà mọ́ ní Amágẹ́dọ́nì náà ṣe rí nìyẹn. (Òwe 10:25) Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ogun yìí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀. Kì í ṣe pé ó fẹ́ máa fi dẹ́rù bani, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fẹ́ kìlọ̀ fáwọn èèyàn débi tí wọ́n á fi lè ronú pìwà dà tí wọ́n á sì pinnu láti máa sìn ín. (Sefanáyà 2:2, 3; 2 Pétérù 3:9) Àwọn tó bá tẹ̀ lé ìkìlọ̀ náà kò ní bógun yìí lọ. Látàrí èyí, kò yẹ ká bẹ̀rù ogun Ọlọ́run tó ń bọ̀ lọ́nà. Kàkà bẹ́ẹ̀, bá a ti ń wo ọjọ́ iwájú, ọkàn wa balẹ̀ pé “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.”—Jóẹ́lì 2:32.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ibì kan wà nínú Bíbélì tí wọ́n fi èdè ìṣàpẹẹrẹ tàbí “àmì” kọ. (Ìṣípayá 1:1) Ìdí nìyí tí a ò fi lè rin kinkin nípa bí Ọlọ́run ṣe máa lo àwọn nǹkan tí Bíbélì pè ní ohun ìjà tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Nígbà tí ìjì líle bá fẹ́ jà, ìjọba máa ń ṣe kìlọ̀kìlọ̀ láti lè gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Káwọn èèyàn bàa lè gbé ìgbésẹ̀ tí ò ní mú kí wọ́n bógun lọ ni Ọlọ́run ṣe rán iṣẹ́ ìkìlọ̀ nípa Amágẹ́dọ́nì