Ṣé Ìwòràwọ̀ Ló Máa Jẹ́ Kó o Mọ Ọjọ́ Ọ̀la rẹ?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ìwòràwọ̀ Ló Máa Jẹ́ Kó o Mọ Ọjọ́ Ọ̀la rẹ?
BÁWO lo ṣe lè mú kí ìgbé ayé rẹ sunwọ̀n sí i, kó o rẹ́ni tó wù ọ́ fẹ́, kó o sì dolówó? Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé ìwòràwọ̀ láá fọ̀nà han àwọn. Lójoojúmọ́, àìmọye èèyàn ló ń wo àwọn ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí nínú ìwé ìròyìn kí wọ́n bàa lè mọ̀ bóyá ọjọ́ ọ̀la àwọn á dára. Kódà, kò jẹ́ tuntun mọ́ pé àwọn aṣáájú ayé ń gbé ìpinnu wọn ka orí ohun tí ìràwọ̀ bá sọ.
Ṣé ohun tó ṣeé gbará lé ni ìwòràwọ̀? Báwo làwọn awòràwọ̀ ṣe ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn? Ṣó yẹ káwọn Kristẹni jẹ́ káwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sójú sánmà máa darí ìgbésí ayé àwọn?
Kí Ni Ìwòràwọ̀?
Bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣe sọ, ìwòràwọ̀ “dá lórí ìgbàgbọ́ pé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sójú sánmà máa ń fara hàn lọ́nà tó lè jẹ́ kéèyàn mọ ohun tó máa dì àti bọ́jọ́ iwájú rẹ̀ ṣe máa rí.” Àwọn awòràwọ̀ máa ń sọ pé ọ̀gangan ibi tí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì bá wà àtàwọn àmì tó dúró fún ìràwọ̀ tí ẹ̀dá bá wáyé ló máa ń pinnu bí ayé ẹ̀dá á ṣe rí. a Ọ̀gangan ibi táwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sójú sánmà wọ̀nyí bá wà nígbàkigbà ni wọ́n ń pè ní ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí.
Látìgbà láéláé làwọn èèyàn ti ní ìgbàgbọ́ nínú ìwòràwọ̀. Ní nǹkan bí ẹgbàajì [4,000] ọdún sẹ́yìn, àwọn ará Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí fi ibi tí oòrùn, òṣùpá àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì márùn-ún tó fara hàn jù lọ bá wà sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí. Wọ́n sọ pé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sójú sánmà wọ̀nyí ní àwọn agbára kan lórí ìwà ẹ̀dá. Nígbà tó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn àmì tó dúró fún ìràwọ̀ tẹ́dàá bá wáyé láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.
Ọjọ́ Pẹ́ Tí Àsọtẹ́lẹ̀ Wọn Ti Ń Kùnà
Bíbélì pàfiyèsí sí ohun tí ìlú Bábílónì àti ìwòràwọ̀ fi jọra, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn awòràwọ̀ ará Bábílónì. (Dáníẹ́lì 4:7; 5:7, 11) Láyé wòlíì Dáníẹ́lì, ìwòràwọ̀ gbilẹ̀ gan-an ní gbogbo ẹkùn Kálídíà (ní Babilóníà) débi pé béèyàn bá ń sọ̀rọ̀ “àwọn ará Kálídíà,” bí ìgbà téèyàn ń sọ̀rọ̀ àwọn awòràwọ̀ ni.
Ipa tí ìwòràwọ̀ ní lórí ìlú Bábílónì ṣojú Dáníẹ́lì kòró, kò sì tún ṣaláì mọ̀ báwọn awòràwọ̀ náà ṣe kùnà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ìlú náà. (Dáníẹ́lì 2:27) Láti igba ọdún sẹ́yìn ni wòlíì Áísáyà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Bábílónì, àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ní ìmúṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó fi wọ́n ṣẹlẹ́yà pé: “Jẹ ki awọn awoye-ọrun, awọn awoye-irawọ, awọn afi-oṣupasọ-asọtẹlẹ, dide duro nisisiyi, ki nwọn si gbà ọ lọwọ nkan wọnyi ti yio ba ọ. . . . Nwọn ki yio gba ara wọn.”—Áísáyà 47:13, 14, Bíbélì Mímọ́.
Ó dájú pé àwọn awòràwọ̀ ìlú Bábílónì ò lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìlú wọn máa ṣubú, kódà nígbà tó tiẹ̀ ku wákàtí díẹ̀ kí wọ́n ṣẹ́gun ìlú náà. Nígbà tí ìkéde ìdájọ́ mímúná Ọlọ́run sì fara hàn lára ògiri ààfin Bẹliṣásárì Ọba, àwọn awòràwọ̀ ò lè sọ ìtumọ̀ àdìtú ìkọ̀wé náà.—Dáníẹ́lì 5:7, 8.
Títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ibi pẹlẹbẹ náà ṣì lọ̀bẹ àwọn awòràwọ̀ ń fi lélẹ̀ bó bá di pé kí wọ́n sàsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. Lẹ́yìn táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó ń ṣèwádìí, R. Culver àti Philip Ianna, ti ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ tó lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] táwọn àwòràwọ̀ sọ, wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ jóná pé ìdá mẹ́wàá péré lára àsọtẹ́lẹ̀ náà ló rí bí wọ́n ṣe sọ. Tí olùṣàrúnkúnná èyíkéyìí bá sì rí ìsọfúnni tó pọ̀ tó, á sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó péye ju tàwọn awòràwọ̀ wọ̀nyẹn lọ.
Kò Bá Ẹ̀kọ́ Bíbélì Mu
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe nítorí pé ìwòràwọ̀ ò lè sọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí gẹ́lẹ́ nìkan làwọn wòlíì Hébérù kì í fi í lọ́wọ́ nínú rẹ̀ o. Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní tààrà pé kí wọ́n má ṣe máa wá àmì ìṣẹ̀lẹ̀. Òfin náà sọ fún wọn pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ . . . ẹnikẹ́ni tí ń woṣẹ́ . . . tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀. . . . Gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”—Diutarónómì 18:10, 12.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin Mósè kò dárúkọ ìwòràwọ̀, síbẹ̀ ohun tó sọ kan kéèyàn máa fi ìwòràwọ̀ sàsọtẹ́lẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé ìwòràwọ̀ jẹ́ “irú ìwoṣẹ́ kan tó jẹ mọ́ sísọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan tó ń lọ lórí ilẹ̀ ayé àtàwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sẹ́dàá nípa kíkíyèsí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Oòrùn, Òṣùpá àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì àti sísọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí.” Onírúurú iṣẹ́ wíwò, yálà èyí tó jẹ mọ́ àwọn ìràwọ̀ tàbí àwọn nǹkan mìíràn, tako àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Kó bàa lè dára náà ni.
Dípò ká máa sọ pé àṣeyọrí tàbí ìkùnà wa dọwọ́ àwọn ìràwọ̀, Bíbélì sọ ní kedere pé “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Níwọ̀n bá a ti jẹ́ ẹ̀dá tó lómìnira àtiyan ohun tó wù wá, olúkúlùkù wa ni yóò dáhùn fún ohun tó bá ṣe níwájú Ọlọ́run. (Diutarónómì 30:19, 20; Róòmù 14:12) Lóòótọ́, jàǹbá lè ṣẹlẹ̀ sí èèyàn, èèyàn sì lè ṣàìsàn nítorí àwọn ipò kan tó kọjá agbára rẹ̀. Ṣùgbọ́n, Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé ohun tó ń fa irú àjálù bẹ́ẹ̀ ni “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀,” kì í ṣe ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí.—Oníwàásù 9:11.
Bíbélì rọ̀ wá pé ká fi àwọn ànímọ́ bí ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, ìpamọ́ra àti ìfẹ́ wọ ara wa láṣọ bá a bá ń bá ara wa lò. (Kólósè 3:12-14) Àwọn ànímọ́ yìí ló máa ń fìdí ìgbéyàwó múlẹ̀ tó sì ń jẹ́ kí tọkọtaya jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn kalẹ́. Kò dáa kẹ́ni méjì fẹ́ra bí wọ́n bá ṣáà ti sọ pé “ìràwọ̀ wọn dọ́gba.” Afìṣemọ̀rọ̀nú, Bernard Silverman, fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí nǹkan bí ẹ̀ẹ́dégbèjìdínlógún [3,500] tọkọtaya, ó sì wá rí i pé nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ló ti kọra wọn sílẹ̀. Ohun tó rí ò yàtọ̀ nígbà tó ṣàyẹ̀wò àwọn tọkọtaya tí ‘ìràwọ̀ wọn dọ́gba.’
Ó wá ṣe kedere nígbà náà pé, ìwòràwọ̀ ò ṣeé gbára lé, ó sì lè ṣini lọ́nà. Dípò tá ò bá fi máa gba ẹ̀bi wa bá a bá ṣàṣìṣe, ó lè mú ká máa dá àwọn ìràwọ̀ lẹ́bi. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ní tààràtà pé kò dáa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn àmì tó dúró fún ìràwọ̀ tí ẹ̀dá bá wáyé ni àwọn àgbájọ ìràwọ̀ méjìlá tó yàtọ̀ síra táwọn awòràwọ̀ máa ń lò yẹn.