Wíwo Ayé
Wíwo Ayé
◼ “Àwùjọ àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà kan lo awò-awọ̀nàjíjìn ti Subaru àti Keck lórí òkè Mauna Kea tó ti yọná-yèéfín nígbà kan rí ní ìpínlẹ̀ Hawaii lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ṣàwárí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onígun mẹ́ta kan tó fẹ̀ débi pé bí ìmọ́lẹ̀ bá gbéra níbi ti ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀, á tó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù ọdún kó tó débi tó parí sí.” Àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí ló para pọ̀ di ohun tó tóbi jù lọ tí wọ́n tíì ṣàwárí.—ÌKÀNNÌ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ TI AWÒ-AWỌ̀NÀJÍJÌN TI SUBARU, ORÍLẸ̀-ÈDÈ JAPAN.
◼ Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni Fáwọn Aráàlú Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ròyìn pé “iye ìgbéyàwó tó wáyé [nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Wales] lọ́dún 2006 ló kéré jù lọ láti àádọ́fà [110] ọdún sẹ́yìn. Ó tẹ́ ọ̀pọ̀ ọkùnrin àtobìnrin lọ́rùn kí wọ́n kàn máa gbé pa pọ̀ láìṣègbéyàwó.”—ÌWÉ ÌRÒYÌN GUARDIAN WEEKLY, ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ.
◼ Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìsìn àti gbogbo apá ẹ̀ka ìgbésí ayé, ìyẹn Pew Forum on Religion and Public Life, sọ pé: “Ìdá mẹ́rìnlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà ti yí ẹ̀sìn wọn pa dà, tàbí kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan, tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ ṣe ẹ̀sìn kankan mọ́.”—ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ.
Àwọn Ọmọ Iléèwé Gíga Ń Gbéra Wọn Sùn
Lẹ́yìn ìwádìí kan tí Ọ̀gbẹ́ni Donna Freitas tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì àti igbá kejì ọ̀jọ̀gbọ́n ní yunifásítì ṣe nípa ìbálòpọ̀ àti ìsìn láwọn iléèwé gíga lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sọ pé: “Yàtọ̀ sáwọn ilé ìwé gíga kan tó jẹ́ tàwọn ajíhìnrere . . . , kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn ilé ìwé ìjọba, ilé ìwé àdáni, ilé ìwé gíga táwọn Kátólíìkì dá sílẹ̀ àtàwọn yunifásítì, tó bá dọ̀rọ̀ káwọn ọmọ ilé ìwé máa gbéra wọn sùn. Èyí sì máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an láwọn ọgbà ilé ìwé gíga, níbi ti ọ̀kan-kò-jọ̀kan ọmọléèwé ti máa ń gbéra wọn sùn.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn National Catholic Reporter ṣe sọ, ọ̀gbẹ́ni Freitas sọ pé bó ṣe jẹ́ pé ìsìn ò rí nǹkan kan ṣe sí ìṣekúṣe tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ kì í ṣe pé ó jẹ́ ká mọ̀ pé “gbígbéra ẹni sùn láwọn iléèwé gíga lágbára” nìkan ni, ó tún fi hàn pé “ńṣe làwọn ìsìn gbọ̀jẹ̀gẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí.”
Wọ́n Ń Sanwó Ìgbọ́bùkátà Àwọn Ọmọbìnrin Fáwọn Òbí
Ìròyìn kan láti Ilé Iṣẹ́ Rédíò Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé ìjọba orílẹ̀-èdè Íńdíà ti ń fáwọn òbí tí wọn ò rí já jẹ níye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] owó dọ́là láti máa fi gbọ́ bùkátà àwọn ọmọbìnrin. Báwọn ìdílé kan bá bí ọmọbìnrin, ìjọba á fún wọn ní iye owó kan, wọ́n á sì tún máa fún wọn láwọn owó míì bọ́mọ náà bá ṣe ń dàgbà títí tá á fi pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18]. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lọ́dún 1994, wọ́n ti fòfin de fífi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì yan irú ọmọ téèyàn bá fẹ́ àti ṣíṣẹ́yún ọmọ kan torí pé kò láwọn ànímọ́ táwọn òbí ń fẹ́, síbẹ̀ àwọn àṣà wọ̀nyí ṣì wọ́pọ̀. Kódà, wọ́n ti fojú bù ú pé láti ogún ọdún sẹ́yìn, wọ́n ti ṣẹ́yún àwọn ọmọbìnrin tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́wàá. Èyí sì ti mú káwọn ọmọkùnrin pọ̀ ju obìnrin lọ fíìfíì láwọn ibì kan. Ètò ìkànìyàn tó wáyé lórílẹ̀-èdè náà lọ́dún 2001 fi hàn pé iye àwọn ọmọkùnrin tí kò tíì pé ọdún mẹ́fà jẹ́ ẹgbẹ̀rún [1000] kan, àwọn ọmọbìnrin sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [927], iye tí wọ́n fi pọ̀ jura lọ yìí sì túbọ̀ ń ga sí i. Kódà, ní ìpínlẹ̀ kan, táwọn ọmọkùnrin ti jẹ́ ẹgbẹ̀rún [1000] kan, àwọn ọmọbìnrin tó wà níbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rin dín méje [793].
Ohun Táwọn Ẹyẹ Máa Ń Ṣe Bí Wọ́n Bá Gbọ́ Ariwo
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Àwọn ẹyẹ kan máa ń sapá gan-an láti mú kí orin wọn bo ariwo tó máa ń wà làwọn ìlú mọ́lẹ̀. Nígbà tó jẹ́ pé ariwo tó máa ń wà láàárín ìlú lè máa yọ àwọn èèyàn lẹ́nu, àmọ́ ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ “ikú tàbí iye” fáwọn ẹyẹ, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn akọ ẹyẹ máa ń kọrin láti “fa àwọn abo mọ́ra, wọ́n sì máa ń fi pààlà síbi tí wọ́n máa ń jẹ̀ dé.” Nítorí pé ariwo máa ń pọ̀ gan-an láàárín ìlú, àwọn ẹyẹ kan máa ń kọrin lálẹ́ kí ohùn wọn lè ròkè dáadáa tàbí kí wọ́n dìídì mú kí ohùn wọn lọ sókè. Ìwé ìròyìn yẹn tún sọ pé, kì í ṣe àwọn ẹyẹ tí wọn ń gbé láàárín ìlú nìkan ni wọ́n máa ń ṣe báyìí. Àwọn ẹyẹ tó wà nítòsí àwọn “ibi tí omi ti máa ń dà yàà látorí àpáta àti ibi odò tó ń ṣàn pẹ̀lú máa ń fohùn tó ròkè lala kọrin.”