Ohun Mẹ́rin Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
Ohun Mẹ́rin Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
Bí àwọn tó nilé bá yẹ ilé náà wò láti mọ bó ṣe bà jẹ́ tó, wọ́n lè yàn láti wó o palẹ̀ tàbí kí wọ́n tún un ṣe.
ǸJẸ́ ìwọ náà ń ronú nípa ohun tí wàá ṣe sí ìgbéyàwó rẹ? Bóyá ọkọ tàbí aya rẹ ti dalẹ̀ àdéhùn yín tàbí kó jẹ́ pé ẹjọ́ lónìí, ìjà lọ́la ni kò jẹ́ kẹ́ ẹ láyọ̀ mọ́ nínú ìgbéyàwó yín. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí èyí mú kó o sọ pé, ‘Kò sí ìfẹ́ mọ́ láàárín wa’ tàbí ‘Kò yẹ ká fẹ́ra wa rárá’ tàbí ‘A ò mọ ohun tá à ń ṣe rárá nígbà tá a ṣègbéyàwó, ojú wa ṣẹ̀ṣẹ̀ là báyìí ni.’ O tiẹ̀ lè máa ronú pé, ‘Bóyá ká kúkú kọra wa sílẹ̀.’
Ronú dáadáa kó o tó fi ìwàǹwára fòpin sí ìgbéyàwó rẹ. Ìkọ̀sílẹ̀ kì í fìgbà gbogbo jẹ́ ojútùú sáwọn ìṣòro téèyàn ní nínú ìgbéyàwó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kàn máa fi àwọn ìṣòro míì rọ́pò ti tẹ́lẹ̀. Nínú ìwé kan tí Ọ̀mọ̀wé Brad Sachs kọ, tó pe àkọlé rẹ̀ ní The Good Enough Teen, ó sọ pé: “Àwọn tọkọtaya tí wọ́n fẹ́ kọra wọn sílẹ̀ máa ń ronú pé èyí á jẹ́ káwọn bọ́ nínú wàhálà ẹjọ́ lónìí, ìjà lọ́la, àwọn á sì wá ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti àlàáfíà, ara á sì tu àwọn. Àmọ́, ńṣe làwọn tó bá rò pé èyí máa yanjú ìṣòro wọn ń tan ara wọn jẹ, torí pé kò sí ìgbéyàwó náà láyé yìí tí kì í ní ìṣòro tiẹ̀.” Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé káwọn tó bá fẹ́ kọra wọn sílẹ̀ ro àròjinlẹ̀ kí wọ́n sì mọ ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ kí wọ́n tó ṣe bẹ́ẹ̀.
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
Ọwọ́ kékeré kọ́ ni Bíbélì fi mú ìkọ̀sílẹ̀. Bíbélì sọ pé ó jẹ́ àdàkàdekè àti ohun ìkórìíra lójú Jèhófà Ọlọ́run pé kéèyàn fi ọkọ tàbí aya rẹ̀ sílẹ̀, bóyá nítorí kó bàa lè fẹ́ ẹlòmíì. (Málákì 2:13-16) Ìdè tó wà pẹ́ títí ni ìgbéyàwó, kì í ṣohun téèyàn lè tú ká nígbà tó bá wù ú. (Mátíù 19:6) Ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó ti tú ká nítorí ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan ì bá ṣì máa gbé pọ̀, ká ní wọ́n máa ń dárí ji ara wọn fàlàlà.—Mátíù 18:21, 22.
Síbẹ̀, Bíbélì fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀ bí ọkọ tàbí aya bá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì. (Mátíù 19:9) Torí náà, bí ọkọ tàbí aya rẹ bá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì, o lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn ẹlòmíì kọ́ ló máa pinnu ohun tí wàá ṣe, bákan náà, àpilẹ̀kọ yìí kò ní pinnu ohun tí wàá ṣe fún ẹ. Mọ̀ pé ohunkóhun tó bá tẹ̀yìn rẹ̀ yọ, ìwọ ni wàá máa bá a yí, tórí náà ìwọ lo ni ìpinnu yẹn.—Gálátíà 6:5.
Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Torí náà, bí ìdí tó o fi fẹ́ kọ ọkọ tàbí aya rẹ sílẹ̀ bá bá Ìwé Mímọ́ mu, á dáa kó o ronú dáadáa nípa ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. (1 Kọ́ríńtì 6:12) Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ David nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àwọn kan lè máa sọ pé àwọn ò ní rò ó lẹ́ẹ̀mejì táwọn bá fẹ́ kọ ọkọ tàbí aya àwọn sílẹ̀. Àmọ́ nígbà tí èmi àti ìyàwó mi kọ ara wa sílẹ̀ ni mo wá mọ̀ pé ó yẹ kéèyàn fara balẹ̀ kó sì ro àròjinlẹ̀ kó tó ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀.” a
Jẹ́ ká wo ohun mẹ́rin pàtàkì tó yẹ kó o ronú lé. Bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn kókó náà, kíyè sí pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn tó kọra wọn sílẹ̀ tó sọ pé ìpinnu tí kò dáa lòun ṣe. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìṣòro kan máa ń jẹ yọ lẹ́yìn oṣù mélòó kan, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti kọra wọn sílẹ̀.
1 Ìṣòro Ìṣúnná Owó
Ó ti tó ọdún méjìlá tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Daniella lórílẹ̀-èdè Ítálì ti ṣègbéyàwó nígbà tó mọ̀ pé ọkọ rẹ̀ ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú obìnrin kan níbi iṣẹ́. Daniella sọ pé: “Nígbà tí mo fi máa mọ̀, obìnrin náà ti lóyún oṣù mẹ́fà fún ọkọ mi.”
Lẹ́yìn tí Daniella àti ọkọ rẹ̀ ti kọ́kọ́ pínyà fúngbà díẹ̀, Daniella pinnu láti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ó sọ pé: “Mo gbìyànjú láti yanjú ìṣòro yìí pẹ̀lú ọkọ mi kí ìgbéyàwó wa má bàa tú ká, àmọ́ ọkọ mi ò yé ṣèṣekúṣe.” Daniella ronú pé ìpinnu tó dáa lòun ṣe. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Gbàrà tá a kọ ara wa sílẹ̀, ńṣe ni ìṣúnná owó mi dojú rú. Mi kì í rí oúnjẹ alẹ́ jẹ nígbà míì, ńṣe ni màá kàn mu ife mílíìkì kan sùn.”
Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí Maria lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Ó ní: “Ọkọ mi àná ò bá wa gbọ́ bùkátà kankan rárá, ó wá gba pé kí n máa ṣiṣẹ́ àṣekára kí n lè san àwọn gbèsè tó jẹ. Mo tún ní láti kó kúrò ní ilé tó dáa tó sì tura tí mò ń gbé, mo sì kó lọ sí ilé kékeré kan tó wà ní àgbègbè eléwu.”
Bí àwọn àpẹẹrẹ yìí ṣe fi hàn, ìkọ̀sílẹ̀ máa ń mú kí ìṣúnná owó nira gan-an fáwọn obìnrin. Kódà, ìwádìí kan tí wọ́n fi ọdún méje ṣe ní ilẹ̀ Yúróòpù fi hàn pé lẹ́yìn táwọn tọkọtaya bá ti kọra wọn sílẹ̀, owó tó ń wọlé fún àwọn ọkùnrin máa ń fi ìdá mọ́kànlá nínú ọgọ́rùn-ún lé sí ti tẹ́lẹ̀. Àmọ́, owó tó ń wọlé fáwọn obìnrin máa ń fi ìdá mẹ́tàdínlógún nínú ọgọ́rùn-ún dín sí ti tẹ́lẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Mieke Jansen, tó darí ìwádìí yẹn sọ pé: “Kì í rọrùn rárá fáwọn obìnrin kan, torí pé wọ́n ní láti bójú tó àwọn ọmọ, wọ́n ní láti wá iṣẹ́, wọ́n sì tún máa ń jẹ̀rora ẹ̀dùn ọkàn tí ìkọ̀sílẹ̀ máa ń fà.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ìlú London kan tó ń jẹ́ Daily Telegraph ṣe sọ, àwọn agbejọ́rò kan sọ pé irú àwọn nǹkan báyìí “máa ń mú káwọn èèyàn túbọ̀ máa ronú dáadáa kí wọ́n tó kọra wọn sílẹ̀.”
Ohun tó lè ṣẹlẹ̀: Lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀, owó tó ń wọlé fún ẹ lè dín kù. Ó sì ṣeé ṣe kó o kúrò níbi tó ò ń gbé. Tó bá jẹ́ ọ̀dọ̀ rẹ làwọn ọmọ wà, ó lè ṣòro fún ẹ láti máa gbọ́ bùkátà ara rẹ àti tàwọn ọmọ.—1 Tímótì 5:8.
2 Ọ̀rọ̀ Ọmọ Títọ́
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jane ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ọkàn mi dà rú gidigidi nígbà tí mo mọ̀ pé ọkọ mi ti lójú síta. Bákan náà, ó máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá mi nígbà tí mo bá ronú pé ńṣe ló dìídì fi wá sílẹ̀.” Nígbà tó yá, Jane kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ó gbà pé ìpinnu tó dáa lòun ṣe yẹn, àmọ́ ó sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tí mo dojú kọ ni pé, ó wá di dandan fún mi báyìí láti máa ṣe ìyá àti bàbá fáwọn ọmọ. Èmi nìkan ni mo máa ń ṣe gbogbo ìpinnu.”
Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí Graciela obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Sípéènì nígbà tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ó sọ pé: “Ó wá di pé kí èmi nìkan máa dá tọ́jú ọmọ mi ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Àmọ́, kò rọrùn rárá láti tọ́ ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, mi ò sì mọ bí mo ṣe máa dá tọ́ ọmọ náà. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń sunkún. Mo rí ara mi bí ẹni tí kò lè ṣàṣeyọrí.”
Ó ṣeé ṣe káwọn òbí tí wọ́n ti kọra wọn sílẹ̀, àmọ́ tí wọ́n fẹ́ máa pín ọmọ tọ́ tún ní àwọn ìṣòro kan tó gbẹgẹ́, irú bíi ṣíṣètò bí ọmọ á ṣe máa lọ kí wọn, bí wọ́n á ṣe máa pèsè àwọn nǹkan tí ọmọ náà nílò àti bí wọ́n á ṣe máa bá ọmọ wí. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Christine lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí òun àti ọkọ rẹ̀ ti kọ ara wọn sílẹ̀ sọ pé: “Kò rọrùn rárá láti da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú ẹni téèyàn ń fẹ́ tẹ́lẹ̀. Èyí lè mú kéèyàn máa ní àwọn ìmọ̀lára kan. Bó ò bá sì ṣọ́ra, o lè bẹ̀rẹ̀ sí lo ọmọ rẹ láti gba ohun tó o fẹ́ lọ́wọ́ ẹnì kejì rẹ.”
Ohun tó lè ṣẹlẹ̀: Ó ṣeé ṣe kó o má fara mọ́ ohun tí wọ́n bá sọ ní ilé ẹjọ́ nípa ọ̀dọ̀ ẹni tí ọmọ á máa gbé. Bẹ́ ẹ bá jọ ń pín ọmọ tọ́, ọkọ tàbí ìyàwó rẹ àná lè má ṣe ohun tó o rò pé ó yẹ kó ṣe tó bá dọ̀rọ̀ àwọn nǹkan tá a sọ lẹ́ẹ̀kan, ìyẹn bí ọmọ á ṣe máa wá kí yín, bẹ́ ẹ ó ṣe máa gbọ́ bùkátà rẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
3 Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Lè Ní Lórí Rẹ
Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí ìyàwó ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mark nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin míì. Mark sọ pé: “Nígbà tó di ẹ̀ẹ̀kejì, ara mi kò gbà á mọ́ torí mo rò pé ó tún lè ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.” Ó kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ ṣì wà lọ́dọ̀ obìnrin náà. Mark sọ pé: “Báwọn èèyàn bá ń sọ ohun tí
kò dáa nípa ìyàwó mi, ṣe ni wọ́n máa ń rò pé àwọn ń ṣe mí lóore, àmọ́ ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń dá kún ẹ̀dùn ọkàn mi. Ìfẹ́ kì í kúrò lọ́kàn ẹni bọ̀rọ̀.”Nígbà tí David tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan mọ̀ pé ìyàwó òun ti lójú síta, ọkàn tiẹ̀ náà bà jẹ́ gidigidi. Ó sọ pé: “Ńṣe ló kọ́kọ́ dà bíi pé mò ń lálàá. Ó wù mí kí n lo gbogbo ìgbésí ayé mi pẹ̀lú ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa.” David kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ èyí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. Ó sọ pé: “Mo máa ń ronú pé bóyá ni mo lè rẹ́ni tó máa nífẹ̀ẹ́ mi dénú àti pé irú ẹ̀ tún lè ṣẹlẹ̀ bí mo bá fẹ́ ẹlòmíì. Ọkàn mi ò balẹ̀ mọ́.”
Bẹ́ ẹ bá ti kọra yín sílẹ̀, ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé onírúurú èrò á máa wá sọ́kàn rẹ. Ọkàn rẹ ṣì lè máa fà sí ẹni tí ìwọ àti ẹ̀ jọ di ara kan. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Síbẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣì lè máa dùn ẹ́ gan-an. Graciela tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, nǹkan á ṣì tojú súni, èèyàn á máa nímọ̀lára ìtìjú, á sì máa wo ara rẹ̀ bí ẹni tí kò ní ìrètí. Wàá bẹ̀rẹ̀ sí rántí àwọn ìgbà tẹ́ ẹ ti jọ gbádùn ara yín, o lè máa ronú pé: ‘Ẹni tó máa ń sọ fún mi pé bóun ò bá rí mi òun ò lè jẹ, òun ò lè mu. Ìyẹn ni pé ó ń tàn mí ni. Kí ló dé tírú èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?’”
Ohun tó lè ṣẹlẹ̀: Ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ṣe ṣì lè máa dùn ẹ́ gan-an, inú sì lè máa bi ẹ. Ìgbà míì tiẹ̀ lè wà tí wàá rí ara rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò ní alábàárò.—Òwe 14:29; 18:1.
4 Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ José lórílẹ̀-èdè Sípéènì tóun àtìyàwó rẹ̀ ti kọra wọn sílẹ̀ sọ pé: “Nǹkan burúkú gbáà ni! Ohun tó tiẹ̀ mú kó tún burú jù ni bí mo ṣe wá mọ̀ pé ọkọ àbúrò mi ló ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìyàwó mi. Ńṣe ló dà bíi pé kí ilẹ̀ lanu kó gbé mi mì.” José wá rí i pé ohun tí ìyàwó òun ṣe yìí ti nípa lórí àwọn ọmọ wọn méjèèjì, tí ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún méjì tí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin. José sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ kò yé àwọn ọmọ náà
rárá. Wọn kò mọ ìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ọkọ àbúrò mi ni ìyá wọn ń gbé, wọn ò sì mọ ìdí tí a fi lọ ń gbé pẹ̀lú ìyá mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin. Bí mo bá fẹ́ jáde, ńṣe ni wọ́n á máa béèrè pé, ‘Ìgbà wo lẹ máa dé?’ tàbí kí wọ́n sọ pé, ‘Dádì, ẹ má fi wá sílẹ̀!’”Awọn tó bá fẹ́ kọra wọn sílẹ̀ kì í sábà ro ipa tí ìgbésẹ̀ yìí máa ní lórí àwọn ọmọ. Àmọ́ bó bá jẹ́ pé ńṣe ni ọ̀rọ̀ ọkọ àti aya ò kàn wọ̀ ńkọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé ìkọ̀sílẹ̀ máa ṣe àwọn ọmọ láǹfààní kankan? Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn gbà pé ìkọ̀sílẹ̀ kò ní ṣe àwọn ọmọ láǹfààní, pàápàá tí ìṣòro àárín tọkọtaya ò bá pọ̀ jù. Ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní The Unexpected Legacy of Divorce sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún ọ̀pọ̀ tọkọtaya tí àárín wọn kò gún láti mọ̀ pé àwọn ọmọ wọn ṣì máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn, bó ti wù ó mọ. Ì báà jẹ́ pé yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Dádì àti Mọ́mì ń sùn, ìyẹn ò kan àwọn ọmọ, níwọ̀n bí ìdílé wọn bá ṣáà ti ń gbé pọ̀.”
Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ máa ń mọ̀ bí àárín àwọn òbí wọn méjèèjì ò bá gún, bí wàhálà bá sì wà láàárín ọkọ àti aya, ó lè nípa tí kò dáa lórí àwọn ọmọ. Àmọ́, ó lè jẹ́ àṣìṣe láti ronú pé ìkọ̀sílẹ̀ ló máa ṣàǹfààní jù lọ fáwọn ọmọ. Nínú ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní The Case for Marriage, tí Linda J. Waite àti Maggie Gallagher kọ, wọ́n sọ pé: “Ìgbéyàwó máa ń jẹ́ káwọn òbí lè máa fún àwọn ọmọ wọn ní ìbáwí tó yẹ, tí àwọn ọmọ náà á sì lè gbọ́ tàwọn òbí wọn, kódà, bí ìgbéyàwó náà ò bá tiẹ̀ rí bó ṣe yẹ kó rí.”
Ohun tó lè ṣẹlẹ̀: Ìkọ̀sílẹ̀ lè ní ipa bíburú jáì lórí àwọn ọmọ rẹ, pàápàá jù lọ bí o kò bá kọ́ wọn láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ọkọ rẹ tàbí aya rẹ àná.—Wo àpótí náà, “Mo Há Sáàárín Méjì.”
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti jíròrò ohun mẹ́rin tó ṣe pàtàkì pé kó o ronú lé lórí tó o bá ń ronú láti kọ ọkọ tàbí aya rẹ sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, bó bá jẹ́ pé ńṣe ni ọkọ tàbí aya rẹ lọ ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì, ìwọ lo máa pinnu ohun tí wàá ṣe. Ìgbésẹ̀ yòówù kó o gbé, ó yẹ kó o ronú nípa ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Mọ àwọn ìṣòro tó lè jẹ yọ, kó o sì múra tán láti kojú wọn.
Lẹ́yìn tó o bá gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, ó ṣeé ṣe kó o rí i pé, ó máa dáa kó o ṣe ohun táá mú kí ìgbéyàwó yín tòrò. Àmọ́, ṣé ìyẹn ṣeé ṣe?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
“Ẹ̀TỌ́ TÍ GBOGBO ỌMỌ NÍ”
“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún márùn-ún, Dádì mi àti akọ̀wé wọn gbéra wọn sùn ní ẹ̀ẹ̀melòó kan, èyí ló mú kí àwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀. Àwọn méjèèjì gbìyànjú gan-an láti tọ́jú mi débi tí òbí lè tọ́jú ọmọ dé nígbà yẹn. Wọ́n fi yé mi pé, lóòótọ́ àwọn ò fẹ́ràn ara àwọn mọ́, àmọ́ àwọn ṣì nífẹ̀ẹ́ mi. Nígbà tí bàbá mi sì lọ ń dá gbé ibòmíì, àwọn méjèèjì ṣì ń fún mi láwọn nǹkan tí mo nílò.
“Ọdún méjì lẹ́yìn náà Mọ́mì fẹ́ ẹlòmíì, a sì kúrò ní ìlú náà. Látìgbà náà, ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọdún mélòó kan ni mo máa ń rí Dádì mi. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni mo rí wọn láàárín ọdún mẹ́sàn-án tó kọjá. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọn ò mọ̀ nípa mi títí mo fi dàgbà, àyàfi àwọn nǹkan tí mo kọ sínú lẹ́tà àti fọ́tò tí mo fi ránṣẹ́ sí wọn. Wọn ò sì mọ àwọn ọmọ-ọmọ wọn, ìyẹn àwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Àwọn ọmọ náà ò sì mọ bàbá mi.
“Òótọ́ ni pé èèyàn ò lè rí àpá kankan lára mi látàrí báwọn òbí mi ṣe kọra wọn sílẹ̀. Àmọ́, nínú mi lọ́hùn-ún, inú ń bí mi, ọkàn mi dà rú, ọkàn mi ò balẹ̀, mi ò sì mọ ìdí táwọn nǹkan yìí fi ń ṣẹlẹ̀ sí mi. Mi ò fọkàn tán àwọn ọkùnrin rárá. Àfìgbà tí mo lé lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún ni ọ̀rẹ́ mi kan tó lóye dáadáa jẹ́ kí n mọ ohun tó fa ìṣòro tí mo ní yìí, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàwọn nǹkan tó máa mú kí n bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro náà.
“Báwọn òbí mi ṣe kọra wọn sílẹ̀, ṣe ni wọ́n gba ẹ̀tọ́ tí gbogbo ọmọ ní lọ́wọ́ mi, ìyẹn ìbàlẹ̀ ọkàn àti ààbò. Ìkórìíra àti ìbẹ̀rù pọ̀ láyé yìí, àmọ́ lójú tèmi, ìdílé ni ibi ààbò téèyàn lè forí pa mọ́ sí, ibẹ̀ ló yẹ kí ọmọ ti rí ìtọ́jú tó dáa kí ara sì tù ú. Bí ìdílé bá fi lè tú ká báyìí, kò sí ààbò mọ́ nìyẹn.”—Diane.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
“MO HÁ SÁÀÁRÍN MÉJÌ”
“Ọmọ ọdún méjìlá ni mí nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀. Èyí kọ́kọ́ mú kí ara tù mí díẹ̀, torí pé àlááfíà tiẹ̀ rídìí jókòó nínú ilé; ogun ẹjọ́ lónìí, ìjà lọ́la kò tún sí mọ́. Síbẹ̀, ọkàn mi gbọgbẹ́.
“Lẹ́yìn táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀, mo gbìyànjú gan-an láti máa bá tọ̀tún-tòsì wọn ṣe láìjẹ́ pé mo gbè sẹ́yìn ẹnì kan. Àmọ́, pẹ̀lú bí mo ṣe ń gbìyànjú tó, ó máa ń ṣe mí bíi pé mo há sáàárín méjì. Dádì sọ fún mi pé àwọn máa ń rò pé ńṣe ni mọ́mì ń kọ́ mi sí àwọn. Torí náà, ìgbà gbogbo ni mo máa ń fi dá wọn lójú pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọkàn mọ́mì náà ò balẹ̀ rárá. Wọ́n sọ pé ẹ̀rù máa ń ba àwọn pé mò ń fetí sí ọ̀rọ̀ tí kò dáa tí dádì máa ń sọ nípa àwọn. Nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ náà le débi pé mi kì í fẹ́ sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára mi fún èyíkéyìí lára wọn mọ́, torí pé mi ò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Torí náà, ká ṣáà sọ pé látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún méjìlá ni mi ò ti ní alábàárò, mi ò lè sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi fún wọn mọ́.”—Sandra.