2. Jẹ́ Onímọ̀ọ́tótó
2. Jẹ́ Onímọ̀ọ́tótó
GẸ́GẸ́ bí dókítà oníṣẹ́ abẹ kan ṣe máa ń dáàbò bo àwọn aláìsàn tó ń tọ́jú nípa fífọ ọwọ́ rẹ̀, nípa fífi omi gbígbóná pa àwọn kòkòrò tó lè wà lára àwọn irinṣẹ́ rẹ̀, nípa mímú kí yàrá tó ti ń ṣiṣẹ́ abẹ náà wà ní mímọ́ tónítóní, ìwọ náà lè dáàbò bo ìdílé rẹ nípa ṣíṣe ìmọ́tótó ara rẹ, ilé ìdáná rẹ àti oúnjẹ rẹ.
● Máa fọ ọwọ́ rẹ.
Àjọ tó ń bójú tó ìlera ará ìlú ní orílẹ̀-èdè Kánádà, ìyẹn Public Health Agency of Canada, sọ pé: “Tó bá kan ọ̀rọ̀ àìsàn tó máa ń ranni, bí ọ̀fìnkìn àti òtútù, wọ́n díwọ̀n rẹ̀ pé èyí tí ọwọ́ dídọ̀tí máa ń kó ranni tó ìdá mẹ́jọ nínú mẹ́wàá.” Torí náà, máa fi ọṣẹ àti omi fọ ọwọ́ rẹ dáadáa kó o tó jẹun, lẹ́yìn tó o bá lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tán àti nígbà tó o bá ń se oúnjẹ.
● Jẹ́ kí ilé ìdáná rẹ wà ní mímọ́ tónítóní.
Ìwádìí kan fi hàn pé, lọ́pọ̀ ìgbà ilé ìwẹ̀ ló máa ń mọ́ tónítóní jù nínú ilé, àmọ́ “téèyàn bá ń wá ibi tí àwọn kòkòrò tó ń fa àìsàn máa ń wà jù, kéèyàn wo kànrìnkàn tí wọ́n fi ń fọ abọ́ àti aṣọ ìnuwọ́ tàbí èyí tí wọ́n fi ń nu abọ́ tó máa ń wà nílé ìdáná.”
Torí náà, máa pààrọ̀ aṣọ ìnuwọ́ lóòrèkóòrè kó o sì máa fi oògùn apakòkòrò tàbí omi gbígbóná pẹ̀lú ọṣẹ nu àwọn ibi tó yẹ nínú ilé ìdáná rẹ. Òótọ́ ni pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Kò sí omi ẹ̀rọ ni ibi tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Bọ́lá ń gbé. Ó sọ pé: “Ìṣòrò ńlá gbáà ni. Ṣùgbọ́n omi àti ọṣẹ kì í wọ́n wa rárá, kò sígbà tí kì í wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti fi fọ ilé ìdáná wa àtàwọn ibi tó yẹ nínú ilé.”
● Fi omi ṣan àwọn ohun ọ̀gbìn dáadáa.
Kó tó di pé wọ́n ta ohun ọ̀gbìn fún ẹ, ó ṣeé ṣe kí omi ìdọ̀tí, àwọn nǹkan ẹlẹ́gbin tàbí àwọn oúnjẹ míì ti yí i, tàbí kí eṣinṣin àtàwọn kòkòrò míì ti wawọ́ lé e lórí. Torí náà, rí i pé o fọ àwọn ewébẹ̀ àti èso kó o lè pa àwọn kòkòrò àrùn tó wà lára wọn, àní bó o bá tiẹ̀ ṣì máa bó èèpo wọn pàápàá. Èyí máa ń gba àkókò. Ìyá kan nílẹ̀ Brazil, tó ń jẹ Daiane, sọ pé “Tí mo bá fẹ́ ṣe sàláàdì, mi kì í fẹ́ kánjú rára, kí n lè rí i dájú pé mo fọ àwọn ewé náà dáadáa.”
● Kó ẹran tútù sọ́tọ̀.
Kí kòkòrò àrùn má bàa ti ara ẹran tútù, adìyẹ, tòlótòló àti ẹja tútù bọ́ sínú oúnjẹ míì, fi ọ̀rá tàbí bébà wé àwọn nǹkan tútù náà dáadáa, kó o sì gbé wọn sí apá kan. Orí pákó ìgé-nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kó o ti gé ẹja tàbí ẹran tútù, ọ̀bẹ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kó o sì lò, tàbí kẹ̀, lẹ́yìn tó o bá gé ọ̀kan tán, kó o fi omi gbígbóná àti ọṣẹ fọ pákó àti ọ̀bẹ náà kó o tó lò ó fún èkejì.
Ní báyìí tí ọwọ́ rẹ, àwọn ohun èlò rẹ àti àwọn èròjà oúnjẹ tó o fẹ́ sè ti wà ní mímọ́, báwo lo ṣe lè se oúnjẹ rẹ láìsí ewu?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ: “A kọ́ àwọn ọmọ wa pé kí wọ́n máa fọ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun, a sì ní kí wọ́n sọ oúnjẹ tó bá ti já bọ́ sílẹ̀ nù tàbí kí wọ́n ṣàn án kí wọ́n tó jẹ ẹ́.”—Hoi, Hong Kong