Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ṢÉ O MỌ ILẸ̀ YÌÍ?

Bá Wa Ká Lọ Sí Ilẹ̀ Kamẹrúùnù

Bá Wa Ká Lọ Sí Ilẹ̀ Kamẹrúùnù

Ó ṢEÉ ṣe kó jẹ́ pé àwọn Bákà, táwọn èèyàn tún mọ̀ sí àwọn kúrékùré ni wọ́n tẹ ilẹ̀ Kamẹrúùnù dó. Àmọ́ láàárín ọdún 1500 sí 1599, àwọn Potogí náà dé síbẹ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, àwọn Fúlàní tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí gbógun ja àríwá ilẹ̀ Kamẹrúùnù wọ́n sì ṣẹ́gun. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, tá a bá pín iye èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù sọ́nà mẹ́wàá, ìdá mẹ́rin nínú wọn ló máa sọ pé ẹlẹ́sìn Kristẹni làwọn, ìdá méjì jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, nígbà tí ìdá mẹ́rin yòókù jẹ́ ẹlẹ́sìn àbáláyé.

Àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ìgbèríko ilẹ̀ Kamẹrúùnù lọ́yàyà, wọ́n sì fẹ́ràn àlejò. Bí wọ́n bá rí àlejò, wọ́n á kí i dáadáa, wọ́n á sì ní kó wọlé kí wọ́n lè fún un ní oúnjẹ àti omi. Tí àlejò yẹn kò bá gba ohun tí wọ́n gbé fún un, wọ́n gbà pé ó ti kan àwọn lábùkù nìyẹn. Àmọ́ bó bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fi lọ̀ ọ́, inú wọn á dùn pé ó pọ́n àwọn lé.

Ìkíni ni wọ́n fi máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn. Àlejò yẹn á kí gbogbo àwọn ará ilé, á sì béèrè àlàáfíà wọn. Wọ́n tiẹ̀ tún máa ń béèrè àlàáfíà àwọn ẹran ọ̀sìn wọn pàápàá! Ọ̀gbẹ́ni Joseph tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kamẹrúùnù sọ pé: “Tí àlejò wa bá ń lọ, kì í ṣe àṣà wa pé ká kàn yísẹ̀ pa dà lẹ́nu ọ̀nà. A máa ń sin àlejò wa dé ọ̀nà. A ó sì jọ máa sọ̀rọ̀ bá a ṣe ń lọ. Tó bá wá ṣe díẹ̀, a ó kí wọn pé ó dàbọ̀, a ó sì pa dà sílé. Bí a ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún àlejò kan, ó lè máa rò pé inú wa ò dùn sóun dáadáa.”

Nígbà míì, àwọn tí wọ́n bá jẹ́ ọ̀rẹ́ máa ń jẹun pa pọ̀ nínú àwo kan náà. Ó sì lè jẹ́ ọwọ́ ni wọ́n á fi jẹun. Lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù, wọ́n ka àṣà yìí sí pàtàkì gan-an torí ó jẹ́ àmì pé wọ́n wà níṣọ̀kan. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ti fi parí ìjà láàárín àwọn kan tí ọ̀rẹ́ wọn ò wọ̀ mọ́. Ohun tí àṣà yìí túmọ̀ sí ni pé, bí wọ́n bá ti lè jọ jẹun nínú àwo kan náà, “ìjà ti parí” nìyẹn.