Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó

Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó

Ṣé ó burú kéèyàn ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó?

“Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, . . . pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè.”—1 Tẹsalóníkà 4:3.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan gbà pé kò sí ohun tó burú nínú kí àwọn àgbàlagbà méjì tí wọn kò tíì ṣe ìgbéyàwó ní ìbálòpọ̀, tó bá ṣáà ti jẹ́ àjọgbà wọn ni. Bákan náà, láwọn ibì kan, wọ́n gbà pé kì í ṣe ohun tó burú táwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó bá ń fara rora láwọn ọ̀nà kan láti mú ara wọn gbóná.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “àgbèrè” fún oríṣi àwọn ìfararora kan láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya. Ọlọ́run sì fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ “ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni Bíbélì pe àgbèrè àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ bíi panṣágà, bíbá ẹ̀mí lò, mímu ọtí ní àmujù, ìbọ̀rìṣà, ìpànìyàn àti olè jíjà.—1 Kọ́ríńtì 6:9; Ìṣípayá 21:8.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RÀN NÁÀ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ìdí kan ni pé, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ‘Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè lẹ́jọ́.’ (Hébérù 13:4) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, tá a bá ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run pé ká yẹra fún ìṣekúṣe, ó fi hàn pé a fẹ́ràn Jèhófà Ọlọ́run lóòótọ́. (1 Jòhánù 5:3) Ọlọ́run sì máa ń bù kún àwọn tó ń pa òfin rẹ̀ mọ́.—Aísáyà 48:18.

Ṣé ó burú kí àwọn méjì tí wọn kò tíì ṣe ìgbéyàwó máa fara rora láwọn ọ̀nà tó ń mú ara wọn gbóná?

“Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín.”—Éfésù 5:3.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀ bí àwọn méjì tí wọn kò tíì ṣe ìgbéyàwó bá ń fara rora láti mú ara wọn gbóná, tí wọn kò bá ṣáà ti bá ara wọn lòpọ̀.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣekúṣe, lẹ́yìn tó mẹ́nu kan àgbèrè, ó tún sọ̀rọ̀ nípa “ìwà àìmọ́” àti “ìwà àìníjàánu.” (2 Kọ́ríńtì 12:21) Oríṣiríṣi ọ̀nà ló wà táwọn tí kì í ṣe tọkọtaya máa ń gbà mú ara wọn gbóná. Ó sì ṣe kedere pé Ọlọ́run kórìíra irú nǹkan bẹ́ẹ̀, kódà bí wọn kò bá tiẹ̀ ní ìbálòpọ̀.

Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ ni pé ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló yẹ kó ní ìbálòpọ̀. Bíbélì tún sọ pe “ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀” jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 4:5) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Àpẹẹrẹ kan rèé tó kan tọkùnrin tobìnrin: Obìnrin kan lè pinnu pé òun kò ní jẹ́ kí ọ̀rẹ́kùnrin òun ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú òun. Àmọ́, àwọn lè máa fara rora láwọn ọ̀nà míì táá máa mú ara wọn gbóná. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń ṣe ojúkòkòrò, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ohun tí kì í ṣe tiwọn dá wọn lọ́rùn. Torí náà, wọ́n jẹ̀bi “ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀.” Bíbélì sì dẹ́bi fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀.—Éfésù 5:3-5.

Báwo lo ṣe lè yẹra fún ìṣekúṣe?

“Ẹ máa sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RÀN NÁÀ FI ṢE PÀTÀKÌ

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó bá ń ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, kò ní lè bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́.—Kólósè 3:5, 6.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “máa sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ohun tí èyí sì túmọ̀ sí ni pé, bó bá ti lè ṣeé ṣe tó a gbọ́dọ̀ jìnnà pátápátá sí ohunkóhun tó lè mú ká ṣe ìṣekúṣe. (Òwe 22:3) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ máa bá a lọ láti jẹ́ oníwà mímọ́, ó ṣe pàtàkì pé ká máa yẹra fún àwọn tí kò ka ìlànà Ọlọ́run nípa ìbálòpọ̀ sí. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.

Téèyàn bá jẹ́ kí èròkérò gba òun lọ́kàn, ìyẹn náà lè mú kí onítọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìṣekúṣe. (Róòmù 8:5, 6) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká yẹra fún àwọn orin, fídíò, ìwé àti ohunkóhun tó ń ṣàfihàn ìṣekúṣe tàbí tó ń gbé irú ìbálòpọ̀ tí Ọlọ́run kórìíra lárugẹ.—Sáàmù 101:3.