Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ KÍ NI OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ KÍ NI OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?

BÍ èèyàn bá ṣàṣìṣe nídìí nǹkan kan, tó sì ṣàtúnṣe tó yẹ, á kẹ́sẹ járí. Bí ò sì rí bẹ́ẹ̀, ó kéré tán, á rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, á sì gbìyànjú kí irú ẹ̀ má tún ṣẹlẹ̀ mọ́. Àmọ́ àṣìṣe ńlá ló jẹ́ fún ẹni tó kàn ń dánú ara ẹ̀ dùn pé òun ṣe àṣeyọrí tó sì jẹ́ pé ohun tó pè ní àṣeyọrí kì í ṣe nǹkan tó ní láárí. A lè pe ìyẹn ní àṣeyọrí tí kì í tọ́jọ́.

Irú àṣeyọrí bẹ́ẹ̀ lè mú kéèyàn máa gbé ara rẹ̀ gẹṣin aáyán pé ayé òun ti dáa, tó sì jẹ́ pé òf ìfo láwọn ohun tó ń pọ́n lé. Ìgbà tó bá máa yé e, ó lè ti pẹ́ jù.

Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ohun tá à ń sọ yẹ̀ wò. Jésù Kristi sọ nígbà kan pé: “Àǹfààní wo ni yóò jẹ́ fún ènìyàn kan bí ó bá jèrè gbogbo ayé ṣùgbọ́n tí ó pàdánù ọkàn rẹ̀?” (Mátíù 16:26) Ohun tó wọ́pọ̀ lónìí nìyẹn, àwọn kan ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lépa owó àti àlùmọ́nì ayé yìí. Àpẹẹrẹ ohun tá a lè pè ní àṣeyọrí tí kì í tọ́jọ́ nìyẹn. Agbaninímọ̀ràn kan tó ń jẹ́ Tom Denham sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tẹ́nì kan ń fi ọjọ́ ayé rẹ̀ lépa ni bó ṣe fẹ́ dépò ńlá, bó ṣe fẹ́ kówó àtàwọn nǹkan ìní rẹpẹtẹ jọ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè láyọ̀. Àwọn tó ń fi owó díwọ̀n àṣeyọrí kàn ń tan ara wọn lásán ni, ayọ̀ wọn kì í tọ́jọ́, irú èrò bẹ́ẹ̀ sì ń jáni kulẹ̀.”

Ọ̀pọ̀ lónìí gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn bẹ́ẹ̀. Wọ́n ní kí àwọn èèyàn kọ àwọn “ohun tí wọ́n kà sí àṣeyọrí nígbèésí ayé wọn.” Ó yani lẹ́nu pé ipò ogún ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi “owó rẹpẹtẹ” sí lára àwọn ohun méjìlélógún tí wọ́n kọ kalẹ̀. Ara ohun tí wọ́n kọ́kọ́ mú ni ìlera tó dáa, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó dán mọ́rán àti ṣíṣe iṣẹ́ téèyàn fẹ́ràn.

Èyí fi hàn pé àwọn èèyàn mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ojúlówó àṣeyọrí àti àṣeyọrí tí kì í tọ́jọ́. Ó dùn-ún sọ lẹ́nu, àmọ́ kì í rọrùn láti ṣe àwọn ìpinnu tó máa fi hàn pé ojúlówó àṣeyọrí là ń lépa.