Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ

AMẸ́RÍKÀ

Àwọn ọlọ́pàá kan ti ń lo àwọn nǹkan ìgbàlódé tó ń mú kó túbọ̀ rọrùn láti lé àwọn awakọ̀ bá láìséwu. Ọgbọ́n kan tí wọ́n dá ni pé, ohun èlò kan tó wà ní iwájú ọkọ̀ wọn máa ń yin ẹ̀rọ kékeré kan jáde, tí á sì lẹ̀ mọ́ ara ọkọ̀ tí wọ́n ń lé. Ẹ̀rọ kékeré yìí máa ń bá ẹ̀rọ ajúwe-ọ̀nà tí àwọn ọlọ́pàá ń lò ṣiṣẹ́, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n lè máa rọra tẹ̀ lé onítọ̀hún kí wọ́n sì mú un láì sáré àsápajúdé.

ÍŃDÍÀ

Àwọn olùṣèwádìí sọ pé ó kéré tán, láàárín wákàtí kan, wọ́n ń pa obìnrin kan nítorí owó ìdána. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ti ṣòfin pé ẹni kẹ́ni ò gbọ́dọ̀ san owó yìí mọ́, kò sì gbọ́dọ̀ gbà á, síbẹ̀ lọ́dún 2012 nìkan, ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ lé ní ọgọ́rùn-ún méjì [8,200] obìnrin ni wọ́n ṣìkà pa. Ìdí tí wọ́n sì fi pa wọ́n ni pé àwọn ẹbí ọkọ tàbí ọkọ obìnrin náà yarí pé owó ìdána tí obìnrin náà san kò pọ̀ tó.

SWITZERLAND

Àwọn ẹ̀rọ-ajúwe kékeré tí wọ́n so mọ́ ara àwọn ẹyẹ olófèéèré (alpine swifts) mẹ́ta níbi tí wọ́n ń pabùdó sí fi hàn pé, àwọn ẹyẹ náà fò fún ohun tó lé ní igba [200] ọjọ́ láì balẹ̀ tàbí sinmi nígbà tí wọ́n ṣí lọ sí i lẹ̀ Áfíríkà. Tẹ́lẹ̀ wọ́n rò pé àwọn ẹran inú omi nìkan ló lè rin irú ìrìn bẹ́ẹ̀ láì sinmi lọ́nà.

ÌKÁNGUN ÌLÀ OÒRÙN ÁFÍRÍKÀ

Láàárín oṣù April ọdún 2005 sí oṣù December ọdún 2012, àwọn jàgùdà ojú omi fipá gba àwọn ọkọ̀ òkun mọ́kàndínlọ́gọ́sàn-án [179] ní etíkun ìkángun ìlà oòrùn Áfíríkà. Báńkì Àgbáyé sọ pé àwọn tó ni àwọn ọkọ̀ ojú omi náà san irínwó ó lé mẹ́tàlá mílíọ̀nù owó dọ́là [₦66,080,000,000], kí wọ́n lè gba ọkọ ojú omi wọn pa dà.