Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kókó Iwájú Ìwé

Nje Bibeli Wulo Fun Wa Lonii?

Nje Bibeli Wulo Fun Wa Lonii?

‘Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí màá láyọ̀ láyé mi.’

Ọ̀GBẸ́NI kan tó ń jẹ́ Hilton gbádùn eré àwọn tó máa ń kan ẹ̀ṣẹ́, àtìgbà tó sì ti wà ní ọmọ ọdún méje ló ti n kan ẹ̀ṣẹ́ kiri! Nígbà tó wà níléèwé gíga, ńṣe lòun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń rìn kiri inú ọgbà láti wá ẹni tí wọ́n máa lù. Hilton sọ pé nígbà yẹn, “mo máa ń jalè, mò ń ta tẹ́tẹ́, mò ń wo ìwòkuwò, mo máa ń fòòró àwọn obìnrin, mo tún máa ń bú àwọn òbí mi. Ìwà mi burú débi pé àwọn òbí mi ò rò pé mo lè yíwà pa dà mọ́ láé. Nígbà tí mo jáde iléèwé, mo kúrò nílé.”

Lẹ́yìn ọdún méjìlá tí Hilton pa dà wálé, àwọn òbí rẹ̀ ṣì í mọ̀, ńṣe ló ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kò fa wàhálà mọ́, ó sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. Kí ló ran Hilton lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà yìí? Nígbà tó kúrò nílé lọ́dún náà lọ́hùn-ún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Ó wá ṣàyẹ̀wò Bíbélì kó lè rí ìrànlọ́wọ́ tó máa mú kó yíwà pa dà. Hilton sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun tí mò ń kọ́ sílò, èyí gba pé kí n jáwọ́ nínú àwọn ìwà mi àtijọ́, kí n sì máa tẹ̀ lé àṣẹ tó wà nínú ìwé Éfésù 6:2, 3 tó ni ká bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wa. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí mo ṣe ohun tó múnú àwọn òbí mi dùn, tó sì fún èmi náà láyọ̀!”

Ìtàn ráńpẹ́ tá a sọ nípa Hilton yìí fi hàn pé Bíbélì máa ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe. (Hébérù 4:12) Bíbélì lè mú ká ní àwọn ìwà rere bíi jíjẹ́ olóòótọ́, ìkóra-ẹni-níjàánu, ìfẹ́ àti ìṣòtítọ́ láàárín tọkọtaya. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn nǹkan yìí ṣe lè mú kí ayé wa dára sí i.