Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ẹ Ṣe Lè Dín Wàhálà Kù Nínú Ilé

Bí Ẹ Ṣe Lè Dín Wàhálà Kù Nínú Ilé

GBOGBO ìgbà lẹ máa ń bá ara yín fa wàhálà nínú ilé. Ó sì ti wá ń ṣe lemọ́lemọ́ gan-an báyìí. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o má mọ ohun tó ń dá wàhálà ọ̀hún sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀, ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín dénú, o ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú bí ẹnì kejì.

Ó yẹ kó o fi sọ́kàn pé torí pé èrò yín yàtọ̀ síra kò túmọ̀ sí pé ìdílé yín máa tú ká. Èdèkòyédè kò lè ṣe kó máà wáyé, àmọ́ ọ̀nà tẹ́ ẹ bá gbà bójú tó o ló máa pinnu bóyá àlàáfíà máa jọba láàárín yín tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Wo díẹ̀ lára ohun tó o lè ṣe láti dín wàhálà kù inú ilé.

1. MÁ ṢE MÁA GBẸ̀SAN.

Tẹ́ni méjì bá ń bá ara wọn jiyàn, àmọ́ tí ẹnì kan nínú wọn dákẹ́, tí kò fèsì mọ́, ó máa jẹ́ kí àríyànjiyàn náà lọ sílẹ̀. Torí náà, sapá láti má ṣe gbẹ̀san nígbà tí ẹnì kejì rẹ bá múnú bí ẹ. Tó o bá kó ara rẹ níjàánu, ó máa jẹ́ kí ẹnì kejì bọ̀wọ̀ fún ẹ, wàá sì níyì lójú ara rẹ. Rántí pé, àlàáfíà inú ilé sàn ju pé kó o borí nínú àríyànjiyàn tó wáyé.

“Níbi tí igi kò bá sí, iná a kú, níbi tí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ kò bá sì sí, asọ̀ a dá.”Òwe 26:20.

2. RO BÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ ṢE RÍ LÁRA ẸNÌ KEJÌ RẸ.

Tó o bá fara balẹ̀ gbọ́ ti ẹnì kejì rẹ, tí o kò sì já ọ̀rọ̀ gba mọ́ ọn lẹ́nu, ìyẹn máa tètè paná ìbínú, á sì mú kí ẹ tètè yanjú èdèkòyédè èyíkéyìí tó bá wáyé. Dípò tí wàá fi ní èrò òdì nípa ẹnì kejì, ńṣe ni kó o sapá láti ro bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Má ṣe ronú pé ńṣe lẹ́nì kejì rẹ fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó dùn ẹ́, rántí pé aláìpé lòun náà. Tí ẹnì kejì rẹ bá sọ̀rọ̀ tó dùn ẹ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìronújinlẹ̀ tàbí ìṣòro kan tó wà lọ́kàn rẹ̀ ló fà á, kì í ṣe pé ó fẹ́ gbẹ̀san.

“Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”Kólósè 3:12.

3. ṢE SÙÚRÙ KÍ ỌKÀN RẸ LÈ RỌ̀.

Tí inú bá ti bí ẹ, ó máa mọ́gbọ́n dání kó o rọra fi ibẹ̀ sílẹ̀, títí tí ọkàn rẹ á fi rọ̀. O lè lọ sí yàrá míì tàbí kó o rìn jáde títí tára rẹ fi máa balẹ̀. Èyí kò túmọ̀ sí pé o kò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yanjú tàbí ò ń bá ẹnì kejì rẹ yodì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àkókò tó dáa láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ lẹ́mìí sùúrù, òye àti ọgbọ́n tó o máa fi yanjú ọ̀rọ̀ náà.

“Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.”Òwe 17:14.

4. FARA BALẸ̀ RONÚ LÓRÍ OHUN TÓ O MÁA SỌ ÀTI BÓ O ṢE MÁA SỌ Ọ́.

Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó máa dun ẹnì kejì lò ń ro bó o ṣe máa sọ, ìyẹn ò lè yanjú ìṣòro náà. Dípò ìyẹn, ọ̀rọ̀ tó máa pẹ̀tù sọ́kàn rẹ̀ ni kó o sọ torí pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bákan náà, ìwọ kọ́ lo máa sọ bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ náà rí lára rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ni kó ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tó o bá ti mọ bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́ gan-an.

“Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.”Òwe 12:18.

5. MÁ ṢE JÁGBE MỌ́ WỌN.

Tí ẹnì kan nínú ìdílé kò bá fara balẹ̀, ó lè tètè múnú bí àwọn tó kù. Torí náà, má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù tàbí ọ̀rọ̀ èébú láìka bínú ṣe ń bí ẹ tó. Má sì ṣe jágbe mọ́ ẹni náà. Má ṣe sọ òkò ọ̀rọ̀ tó máa dun ẹnì kejì, irú bí “O kì í rò tèmi mọ́ tìẹ rárá” tàbí “O kì í fara balẹ̀.” Dípò irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, o lè sọ fún ẹnì kejì rẹ lóhùn jẹ́jẹ́ pé ohun tó ṣe dùn ẹ́, o lè sọ pé, ‘Ó máa ń dùn mí tó o bá ṣe báyìí.’ Ìwà burúkú gbáà ni tó o bá ti ẹnì kejì rẹ, tó o gbá a létí, tó o lù ú tàbí tó o hùwà ìkà sí i lọ́nàkọnà. Kò sì yẹ kó o máa bú u tàbí kó o máa sọ̀rọ̀ burúkú sí i tàbí kó máa halẹ̀ mọ́ ọn.

“Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.”Éfésù 4:31.

6. TÈTÈ TỌRỌ ÀFORÍJÌ, KÓ O SÌ SỌ OHUN TÓ O MÁA ṢE LÁTI YANJÚ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ.

Rántí pé ńṣe lo fẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ilé rẹ, torí náà má ṣe jẹ́ kí ara rẹ gbóná kọjá bó ṣe yẹ. Má ṣe gbà gbé pé ìjà ò dọlà. Tó o bá wá àlàáfíà, ẹ̀yin méjèèjì lẹ máa láyọ̀. Torí náà, tí àríyànjiyàn bá wáyé, ńṣe ni kó o gba ẹ̀bi rẹ lẹ́bi. Kódà, tó o bá rò pé o kò jẹ̀bi, ó ṣì yẹ kó o tọrọ àforíjì pé ọ̀rọ̀ náà bí ẹ nínú, pé o fìbínú sọ̀rọ̀ tàbí pé o dá kún ọ̀rọ̀ náà. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí àjọṣe tó dáa wà láàárín yín. Torí náà, tí ẹnì kan bá ti tọrọ àforíjì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kó o ti jẹ́ kọ́rọ̀ náà tán nínú ẹ.

“Lọ, rẹ ara rẹ sílẹ̀, kí o sì bẹ ọmọnìkejì rẹ ní ẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dabọ̀.”Òwe 6:3.

Tí àríyànjiyàn náà bá ti wá tán nílẹ̀, kí lo lè ṣe tí àlàáfíà á fi pa dà wà nínú ilé? Ohun tá a máa sọ̀rọ̀ lé lórí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn nìyẹn.