Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ṣé àwọn ará Róòmù máa ń gbà kí wọ́n sin òkú ẹni tí wọ́n pa sórí òpó igi, irú bí wọ́n ṣe pa Jésù?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló mọ ìtàn bí wọ́n ṣe kan Jésù mọ́gi sáàárín ọ̀daràn méjì, tó sì kú sórí òpó igi. (Mát. 27:35-38) Àmọ́, àwọn èèyàn kan ń jiyàn pé irọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ pé wọ́n gbé òkú Jésù kúrò lórí òpó igi, wọ́n fi aṣọ wé e, wọ́n sì lọ sin ín sínú ibojì.—Máàkù 15:42-46.
Àwọn tí ò gba ohun tí Ìwé Ìhìn Rere sọ máa ń jiyàn pé wọn kì í sin òkú ẹni tí wọ́n bá kàn mọ́gi bí wọ́n ṣe ń sin òkú àwọn èèyàn, irú bíi kí wọ́n sin ín sínú ibojì. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà pé nǹkan míì ló jọ pé wọ́n máa ń ṣe sí òkú àwọn ọ̀daràn náà. Akọ̀ròyìn kan tó ń jẹ́ Ariel Sabar ṣàlàyé ohun tó mú kí wọ́n ní èrò yẹn nínú ìwé ìròyìn Smithsonian, ó sọ pé: “Àwọn èèyàn burúkú ni wọ́n máa ń kàn mọ́gi. Àwọn ọ̀mọ̀wé tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí tún sọ pé àwọn ará Róòmù ò ní gbà rárá kí wọ́n sin òkú irú àwọn ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ṣe máa ń sin òkú àwọn èèyàn.” Àwọn ará Róòmù gbà pé àbùkù ńlá ló tọ́ sáwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá pa. Torí náà, wọ́n máa ń fi òkú àwọn tí wọ́n pa sílẹ̀ lórí òpó igi káwọn ẹyẹ àti ẹranko lè jẹ wọ́n. Lẹ́yìn náà, wọ́n á ju ohun tó bá ṣẹ́ kù lára òkú wọn sínú sàréè ńlá kan.
Àmọ́, egungun àwọn Júù kan tí wọ́n pa sórí òpó igi táwọn awalẹ̀pìtàn rí jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Lọ́dún 1968, wọ́n rí egungun ọkùnrin kan tí wọ́n pa sórí òpó igi nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Inú ibojì ìdílé àwọn Júù kan nítòsí Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti rí egungun náà. Inú àpótí kan ni egungun náà wà. Egungun gìgísẹ̀ wà lára àwọn egungun tí wọ́n rí. Ìṣó kan tó gùn ju ínǹṣì mẹ́rin (11.5 cm) lọ ni wọ́n fi kàn án mọ́ pátákó kan. Ọ̀gbẹ́ni Sabar sọ pé: “Nígbà tí wọ́n rí gìgísẹ̀ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Yehochanan, ó jẹ́ ká yanjú àríyànjiyàn ọlọ́jọ́ pípẹ́, ó sì jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni ohun tí Ìwé Ìhìn Rere sọ pé wọ́n sin Jésù sínú ibojì.” Torí náà, ó hàn gbangba pé, “gìgísẹ̀ Yehochanan jẹ́ ká rí i pé wọ́n kan ọkùnrin kan mọ́gi nígbà ayé Jésù, àwọn ará Róòmù sì gbà kí wọ́n sin ín lọ́nà tí àwọn Júù ń gbà sìnkú.”
Ohun tí wọ́n rí nípa egungun gìgísẹ̀ Yehochanan ti jẹ́ káwọn èèyàn ní oríṣiríṣi èrò nípa bí wọ́n ṣe kan Jésù mọ́ òpó igi. Àmọ́, ohun kan wà tó hàn kedere, ìyẹn ni pé wọ́n sin àwọn ọ̀daràn kan tí wọ́n pa, wọn ò sì gbé òkú wọn sọ nù. Torí náà, kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé wọ́n sin òkú Jésù sínú ibojì. Ẹ̀rí táwọn awalẹ̀pìtàn rí yìí ti ohun tí Bíbélì sọ lẹ́yìn pé wọ́n sin òkú Jésù sínú ibojì.
Ṣùgbọ́n ẹ̀rí tó ṣe pàtàkì jù ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ pé wọ́n máa sin Jésù sínú ibojì ọlọ́rọ̀ kan. Torí náà, kò sẹ́ni tó lè sọ pé kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má ṣẹ.—Àìsá. 53:9; 55:11.