Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì sọ, ẹ̀rí míì wo ló tún fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì?
Bíbélì sọ pé lẹ́yìn táwọn ará Mídíánì mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì, Jékọ́bù àti ìdílé rẹ̀ kúrò ní Kénáánì lọ sí Íjíbítì. Wọ́n wá ń gbé ní Góṣénì tó wà nílẹ̀ Íjíbítì, ìyẹn agbègbè kan tí Odò Náílì ti ya wọnú òkun. (Jẹ́n. 47:1, 6) Bíbélì sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “ń bí sí i, wọ́n sì túbọ̀ ń lágbára gidigidi.” Ìyẹn mú kí ẹ̀rù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ba àwọn ará Íjíbítì. Torí náà, àwọn ará Íjíbítì sọ wọ́n di ẹrú.—Ẹ́kís. 1:7-14.
Àwọn alárìíwísí kan lóde òní sọ pé ìtàn yìí kì í ṣe òótọ́, pé àròsọ lásán ni. Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn Sẹ́mítì * jẹ́ ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì àtijọ́.
Àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àwọn ìlú àtijọ́ kan ní apá àríwá ilẹ̀ Íjíbítì. Bí àpẹẹrẹ, John Bimson tó jẹ́ onímọ̀ nípa Bíbélì tó sì tún jẹ́ awalẹ̀pìtàn sọ pé àwọn rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ibi táwọn Sẹ́mítì gbé ní apá àríwá ilẹ̀ Íjíbítì tó ogún (20) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà, James K. Hoffmeier tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ohun ìṣẹ̀ǹbáyé Íjíbítì sọ pé: “Ní nǹkan bí ọdún 1800 sí 1540 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Íjíbítì jẹ́ ibi fífanimọ́ra táwọn Júù máa ń fẹ́ ṣí lọ.” Ó wá fi kún un pé: “Àkókò yìí bá àsìkò tí wọ́n gbà pé àwọn ‘Baba ńlá’ àwọn Júù gbé ní Íjíbítì mu, ó sì bá ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì mu.”
Wọ́n tún rí àwọn ẹ̀rí míì lápá gúúsù Íjíbítì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n rí àkájọ ìwé kan tí wọ́n fi òrépèté ṣe tó ṣeé ṣe kó ti wà ní nǹkan bí 2000 sí 1600 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nínú ìwé náà, wọ́n rí orúkọ àwọn ẹrú tí wọ́n ṣiṣẹ́ nílé kan ní apá gúúsù Íjíbítì. Orúkọ àwọn Sẹ́mítì tó ju ogójì (40) lọ ló wà níbẹ̀. Àwọn ẹrú yẹn ló ń se oúnjẹ, àwọn ló ń hun aṣọ, àwọn náà ló sì ń ṣe lébìrà. Ọ̀mọ̀wé Hoffmeier sọ pé: “Níwọ̀n bí wọ́n ti rí orúkọ àwọn Sẹ́mítì tó ju ogójì (40) lọ nínú agboolé kan ṣoṣo lágbègbè Thebaid [ní gúúsù Íjíbítì], a jẹ́ pé àwọn èèyàn náà pọ̀ gan-an nílẹ̀ Íjíbítì nìyẹn, pàápàá ní agbègbè kan tí Odò Náílì ti ya wọnú òkun.”
Awalẹ̀pìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ David Rohl sọ pé “orúkọ àwọn ẹrú tí wọ́n rí bá àwọn orúkọ tó wà nínú Bíbélì mu.” Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé yẹn wọ́n rí àwọn orúkọ tó jọ Ísákà, Áṣérì àti Ṣífúrà. (Ẹ́kís. 1:3, 4, 15) Rohl tún sọ pé: “Ẹ̀rí tó dájú lèyí jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ẹrú ní Íjíbítì lásìkò yẹn.”
Ọ̀mọ̀wé Bimson wá sọ pé: “Àkọsílẹ̀ Bíbélì tó sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ẹrú ní Íjíbítì àti pé wọ́n jáde kúrò níbẹ̀ lómìnira kì í ṣe ìtàn àròsọ, òótọ́ ni.”
^ ìpínrọ̀ 4 Àwọn Sẹ́mítì wá látinú ẹ̀yà Ṣémù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tí Nóà bí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ṣémù ni àwọn ọmọ Élámù, àwọn ará Ásíríà, àwọn ará Kálídíà ìgbàanì, àwọn Hébérù, àwọn ará Síríà àtàwọn ẹ̀yà Arébíà lónírúurú.