Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìlú Nínéfè lẹ́yìn ìgbà ayé Jónà?
NÍ NǸKAN bí ọdún 670 Ṣ.S.K., ìjọba ilẹ̀ Ásíríà ti ń ṣàkóso ibi tó pọ̀ jù lọ láyé. Ìkànnì British Museum tó ń sọ nípa àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sọ pé: “Ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ fẹ̀ láti Sápírọ́sì ní ìwọ̀ oòrùn dé ilẹ̀ Ìráànì ní ìlà oòrùn, ó sì nasẹ̀ dé ilẹ̀ Íjíbítì láwọn ọdún kan pàápàá.” Nígbà yẹn, ìlú Nínéfè ni olú ìlú Ásíríà, òun sì ni ìlú tó tóbi jù lọ láyé. Ó ní àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé, àwọn ọgbà tó rẹwà, àwọn ààfin ńláńlá àtàwọn ilé ìkàwé tó tóbi. Àwọn ohun tí wọ́n kọ sára ògiri ìlú Nínéfè àtijọ́ fi hàn pé Ọba Aṣọbánípà pe ara rẹ̀ ní “ọba gbogbo ayé,” bí àwọn ọba Ásíríà yòókù ṣe ṣe. Nígbà yẹn, ó jọ pé kò sí ẹni tó lè ṣẹ́gun ilẹ̀ Ásíríà àti ìlú Nínéfè.
Àmọ́ nígbà tí Ásíríà di orílẹ̀-èdè tó lágbára jù lọ láyé, Jèhófà ní kí wòlíì Sefanáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “[Jèhófà] máa . . . pa Ásíríà run, á sọ Nínéfè di ahoro, á sì gbẹ bí aṣálẹ̀.” Yàtọ̀ síyẹn, wòlíì Jèhófà tó ń jẹ́ Náhúmù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹ kó fàdákà, ẹ kó wúrà! . . . Ìlú náà ti ṣófo, ó ti di ahoro, ó sì ti pa run! . . . Gbogbo ẹni tó bá rí ọ máa sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ, á sì sọ pé, ‘Nínéfè ti di ahoro!’” (Sef. 2:13; Náh. 2:9, 10; 3:7) Nígbà táwọn èèyàn gbọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má gbà á gbọ́, kí wọ́n sì sọ pé: ‘Ṣé ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ ṣá? Ṣé wọ́n á lè ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè Ásíríà tó lágbára gan-an yìí?’ Kò sẹ́ni tó lè gbà pé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀.
Síbẹ̀, wọ́n ṣẹ́gun Ásíríà! Nígbà tí ọdún 700 Ṣ.S.K. ń parí lọ, àwọn ará Bábílónì àtàwọn ará Mídíà ṣẹ́gun Ásíríà. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn ò gbé ìlú Nínéfè mọ́, ó dahoro, wọn ò sì rántí ẹ̀ mọ́! Ìwé kan tí The Metropolitan Museum of Art nílùú New York ṣe sọ pé: “Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ìlú Nínéfè ti pa rẹ́ ráúráú, inú Bíbélì nìkan la ti ń gbọ́ orúkọ ẹ̀.” Ẹgbẹ́ awalẹ̀pìtàn kan tó ń jẹ́ Biblical Archaeology Society sọ pé nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1800 S.K., “kò sẹ́ni tó mọ̀ bóyá ìlú Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú Ásíríà tiẹ̀ wà rí.” Àmọ́ nígbà tó di ọdún 1845 S.K., awalẹ̀pìtàn kan tó ń jẹ́ Austen Henry Layard bẹ̀rẹ̀ sí í walẹ̀ kó lè mọ ibi tí ìlú Nínéfè wà. Àwọn ohun tó hú jáde níbẹ̀ ló fi hàn pé ìlú Nínéfè jẹ́ ìlú olókìkí nígbà kan rí.
Bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú Nínéfè ṣe ṣẹ láìkù síbì kan jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ pé àwọn ìjọba alágbára òde òní máa pa run máa ṣẹ bákan náà.—Dán. 2:44; Ìfi. 19:15, 19-21.