ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Jèhófà Fún Wa Lókun Lákòókò Ogun àti Lákòókò Àlàáfíà
Paul: Ní November 1985, inú wa dùn gan-an bá a ṣe ń rìnrìn àjò lọ sórílẹ̀-èdè Làìbéríà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Ibẹ̀ ni ètò Ọlọ́run kọ́kọ́ rán wa lọ pé ká lọ máa ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ọkọ̀ òfúrufú tá a wọ̀ dúró díẹ̀ ní Sẹ̀nẹ̀gà. Anne sọ pé: “Tá a bá fi máa rí bíi wákàtí kan àti ìṣẹ́jú díẹ̀, àá ti wà ní Làìbéríà!” Àfi bá a ṣe gbọ́ tí wọ́n ṣèfilọ̀ nínú ọkọ̀ òfúrufú pé: “Àwọn tó bá ń lọ sí Làìbéríà gbọ́dọ̀ sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ yìí. Wàhálà ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ níbẹ̀ torí àwọn kan fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba, torí náà, ọkọ̀ òfúrufú yìí ò ní lè balẹ̀ síbẹ̀.” Ọjọ́ mẹ́wàá la fi wà lọ́dọ̀ àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní Sẹ̀nẹ̀gà, tá à ń gbọ́ ìròyìn nípa bí wọ́n ṣe ń pa àwọn èèyàn nípakúpa, tíjọba sì ṣòfin kónílé-ó-gbélé, wọ́n ní tẹ́nikẹ́ni bá jáde nílé lásìkò tí ò yẹ, wọ́n máa yìnbọn pa á.
Anne: Èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ lèmi àti ọkọ mi, a ò lẹ́mìí wàhálà. Kódà, àtikékeré ni wọ́n ti máa ń pè mí ní Annie Oníbẹ̀rù, torí ẹ̀rù máa ń tètè bà mí. Tí mo bá fẹ́ sọdá títì lásán, wàhálà ni! Àmọ́ láìka ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Làìbéríà sí, ó wù wá gan-an ká débẹ̀, ká lè ṣiṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run rán wa.
Paul: Ibi tí wọ́n bí èmi àti Anne sí ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè England ò ju kìlómítà mẹ́jọ síra wọn lọ. Léraléra làwọn òbí mi àti ìyá Anne máa ń gbà wá níyànjú pé ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà, torí náà, àwa méjèèjì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́yìn tá a jáde ilé ẹ̀kọ́ girama. Inú àwọn òbí wa dùn gan-an pé iṣẹ́ alákòókò kíkún la yàn láàyò, wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún (19), mo láǹfààní láti lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, nígbà tó sì dọdún 1982, èmi àti Anne ṣègbéyàwó, wọ́n sì ní kóun náà máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.
Anne: A fẹ́ràn iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ ó ti pẹ́ tó ti máa ń wù wá pé ká lọ sìn níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò tíì gbọ́ ìwàásù. Ní Bẹ́tẹ́lì, a ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará tó ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì rí, ìrírí àti àpẹẹrẹ wọn sì jẹ́ kó wù wá láti di míṣọ́nnárì. Ọdún mẹ́ta gbáko la fi gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ yìí lálaalẹ́, torí náà, inú wa dùn gan-an nígbà tí ètò Ọlọ́run pè wá sí kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́rin (79) ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1985! Orílẹ̀-èdè Làìbéríà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ni wọ́n rán wa lọ.
ÀWỌN ARÁ NÍFẸ̀Ẹ́ WA, ÌYẸN SÌ FÚN WA LÓKUN
Paul: Ọkọ̀ òfúrufú tó kọ́kọ́ gbéra la bá pa dà sí Làìbéríà nígbà tá a láǹfààní láti wọbẹ̀. Torí pé rògbòdìyàn yẹn ò tíì tán nílẹ̀, òfin kónílé-ó-gbélé ṣì wà. Ẹ̀rù ṣì ń ba àwọn èèyàn débi pé tí salẹ́ńsà mọ́tò bá dédé pariwo láàárín ọjà, àwọn èèyàn á tú ká. A máa ń ka Sáàmù lálaalẹ́ kí ara lè tù wá. Láìka gbogbo ìyẹn sí, à ń gbádùn iṣẹ́ wa gan-an. Anne ń ṣiṣẹ́ mísọ́nnárì, àmọ́ Bẹ́tẹ́lì ni mo ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Arákùnrin John Charuk. a Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ lára wọn, torí ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń gbé Làìbéríà, wọ́n sì mọ ohun tójú àwọn ará wa ń rí níbẹ̀.
Anne: Kí ló jẹ́ kí ara wa tètè mọlé ní Làìbéríà, ká sì máa gbádùn iṣẹ́ wa? Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Ara wọn yá mọ́ọ̀yàn, wọ́n fìfẹ́ gbà wá, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. A wá mọwọ́ ara wa débi tá a fi dà bí ọmọ ìyá. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń bá wa sọ máa ń fún wa níṣìírí ká lè túbọ̀ ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an ni. Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ ká pẹ́ lọ́dọ̀ àwọn, ká ṣáà máa bá wọn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ ọ́ dìjà mọ́ wa lọ́wọ́! Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ẹ̀ẹ́ rí i táwọn èèyàn á máa sọ̀rọ̀ Bíbélì. Ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wa láti bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá pọ̀ débi pé ó ṣòro gan-an láti máa kọ́ gbogbo wọn lẹ́kọ̀ọ́. Iṣẹ́ ìwàásù dùn ún ṣe níbí yìí o!
Ẹ̀RÙ BÀ WÁ, ÀMỌ́ JÈHÓFÀ FÚN WA LÓKUN
Paul: Lọ́dún 1989, lẹ́yìn tá a ti fi ọdún mẹ́rin gbádùn àkókò àlàáfíà, nǹkan ṣàdédé yí pa dà. Ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀ ní Làìbéríà. Ní July 2, 1990, àwọn tó ń ta ko ìjọba fìdí kalẹ̀ sí agbègbè kan tó wà nítòsí Bẹ́tẹ́lì, kò sì sẹ́ni tó lè kápá wọn. Oṣù mẹ́ta gbáko ni wọ́n fi sé wa mọ́ agbègbè yẹn, tá ò gbúròó àwọn mọ̀lẹ́bí wa àtàwọn tó wà ní orílé-iṣẹ́ wa. Rògbòdìyàn ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, oúnjẹ wọ́n, wọ́n sì ń fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀. Ọdún mẹ́rìnlá ni ogun abẹ́lé yìí fi jà, ó sì ba gbogbo nǹkan jẹ́ lórílẹ̀-èdè náà.
Anne: Àwọn ẹ̀yà kan ń bára wọn jà, wọ́n sì ń para wọn. Àwọn tó dira ogun wà káàkiri inú ìlú, wọ́n múra lọ́nà tó ṣàjèjì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tinú ilé kan bọ́ sí òmíì, tí wọ́n ń fipá gba ohun táwọn èèyàn ní. Wọ́n ń pa èèyàn bí ẹni pa adìyẹ. Wọ́n gbégi dí ojú ọ̀nà káàkiri, títí kan àwọn ibì kan nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, wọ́n sì máa ń pa àwọn tó bá fẹ́ kọjá nígbà míì, wọ́n á wá to òkú èèyàn jọ pelemọ. Wọ́n pa àwọn ará wa kan, méjì nínú wọn ló sì jẹ́ míṣọ́nnárì bíi tiwa.
Àwọn ará wa fẹ̀mí wọn wewu, wọ́n máa ń fi àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wá láti ẹ̀yà míì pa mọ́ káwọn jàǹdùkú má bàa pa wọ́n. Àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì náà fi àwọn ará wa pa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n kó àwọn ará wa kan sáwọn yàrá tó wà nísàlẹ̀, àwọn yòókù sì wà lọ́dọ̀ wa nínú àwọn yàrá tó wà lókè. Èmi àti ọkọ mi gba ìdílé kan sínú yàrá wa, èèyàn méje sì ní wọ́n.
Paul: Ojoojúmọ́ làwọn jàǹdùkú máa ń fẹ́ wọnú Bẹ́tẹ́lì kí wọ́n lè wá wò ó bóyá a fi àwọn èèyàn pa mọ́ síbẹ̀. A ṣètò àwọn ará mẹ́rin tó ń ṣe ẹ̀ṣọ́, àwọn méjì máa ń yọjú látojú wíńdò kan, àwọn méjì á sì lọ sẹ́nu géètì. Tí àwọn méjì tó wà lẹ́nu géètì bá nawọ́ síwájú, a jẹ́ pé kò síṣòro. Àmọ́ tí wọ́n bá káwọ́ sẹ́yìn, wọ́n ń fìyẹn sọ fún wa pé ọwọ́ líle làwọn jàǹdùkú yẹn ń gbé bọ̀, àwọn tó ń yọjú lójú wíńdò á tètè lọ fi àwọn ará tá a gbà sílé pa mọ́.
Anne: Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, àwọn jàǹdùkú kan tínú ń bí rọ́nà wọlé síbi tá a wà. Èmi àti arábìnrin kan sáré wọnú balùwẹ̀ ká lè fara pa mọ́, a sì tilẹ̀kùn pa. Kọ́bọ́ọ̀dù kan wà níbẹ̀ tá à ń kó nǹkan sí, àmọ́ tó ní àyè téèyàn lè sá pa mọ́ sí nísàlẹ̀. Inú àyè yẹn ni arábìnrin náà rún ara ẹ̀ mọ́. Àwọn jàǹdùkú náà wá sókè níbi tí balùwẹ̀ yẹn wà, wọ́n gbé ìbọn arọ̀jò-ọta dání. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìbínú gbálẹ̀kùn. Paul bẹ̀ wọ́n kí wọ́n má wọlé, ó ní, “Ìyàwó mi ń lo ibẹ̀ lọ́wọ́.” Kọ́bọ́ọ̀dù yẹn ń pariwo bí mo ṣe ń fi arábìnrin yẹn pa mọ́ sí àyè tó ṣófo níbẹ̀. Wọ́n sì ti ń fura torí ó pẹ́ kí n tó ṣe tán. Ara mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n torí ẹ̀rù ń bà mí. Ó ku bí mo ṣe fẹ́ jáde sí wọn tí wọn ò sì ní mọ̀ pé ẹ̀rù ń bà mí. Mo fọkàn gbàdúrà sí Jèhófà, mo ṣílẹ̀kùn, mo sì rọra kí wọn. Ọ̀kan nínú wọn bá já wọlé, ó tì mí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì lọ síbi kọ́bọ́ọ̀dù náà. Ó tú u, àmọ́ ó yà á lẹ́nu pé òun ò rí nǹkan kan. Òun àtàwọn yòókù tú àwọn yàrá tó kù àti yàrá inú àjà, àmọ́ wọn ò rí nǹkan kan.
ÒTÍTỌ́ Ń MỌ́LẸ̀ SÍ I
Paul: Ọ̀pọ̀ oṣù la ò fi rí oúnjẹ tó pọ̀ tó. Oúnjẹ tẹ̀mí ló ń gbé wa ró ní gbogbo àkókò yẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í jẹun àárọ̀, ìjọsìn òwúrọ̀ Bẹ́tẹ́lì la fi máa ń ṣe oúnjẹ àárọ̀, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ìjọsìn òwúrọ̀ yẹn máa ń fún wa lókun tá a nílò.
Tá a bá ní ká kúrò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, ká wá oúnjẹ àti omi lọ, àwọn jàǹdùkú lè pa àwọn ará wa tá a fi pa mọ́ síbẹ̀. Àmọ́ ọ̀nà tí Jèhófà máa ń gbà pèsè ohun tá a nílò fún wa lákòókò tá a nílò ẹ̀ máa ń yà wá lẹ́nu. Jèhófà bójú tó wa, ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀.
Bí nǹkan ṣe ń burú sí i ní Làìbéríà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ará wa máa ń sá kiri kí wọ́n má bàa pa wọ́n, àmọ́ ìgbàgbọ́ wọn ò yẹ̀ lásìkò yẹn. Àwọn ará kan sọ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn “ń múra àwọn sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá.” Àwọn alàgbà àtàwọn ọ̀dọ́kùnrin fìgboyà ran àwọn ará lọ́wọ́. Tí àwọn ará bá ti sá kúrò níbì kan lọ síbòmíì, wọ́n á kóra jọ, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù níbẹ̀. Wọ́n ṣètò ibì kan nínú igbó kí wọ́n lè máa ṣèpàdé. Lákòókò tí nǹkan nira yẹn, ohun tó ń fún àwọn ará níṣìírí tó sì ń jẹ́ kí wọ́n lókun ni pé wọ́n máa ń lọ sípàdé, wọ́n sì máa Mát. 5:14-16) Bí àwọn ará wa ṣe ń fi gbogbo ọkàn wọn jọ́sìn mú kí àwọn kan lára àwọn jàǹdùkú yẹn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ń wàásù. Nígbà tá à ń pín nǹkan ìrànwọ́ táwọn ará fi ránṣẹ́, ó yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ àwọn ará ló sọ pé àwọn ń fẹ́ báàgì táwọn lè máa gbé lọ sóde ìwàásù dípò aṣọ. Àwọn èèyàn tí ogun fojú wọn rí màbo yìí fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Ó yà wọ́n lẹ́nu bí wọ́n ṣe rí i táwọn ará ń láyọ̀, tí wọ́n ń fìfẹ́ hàn síra wọn, tó sì dà bíi pé wọn ò níṣòro. Àwọn ará yẹn dà bí ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn nínú òkùnkùn. (ỌKÀN WA GBỌGBẸ́, ÀMỌ́ JÈHÓFÀ FÚN WA LÓKUN
Paul: Àwọn ìgbà kan wà tó pọn dandan ká kúrò ní Làìbéríà. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta la kúrò ní Làìbéríà lọ síbòmíì fúngbà díẹ̀, ẹ̀ẹ̀méjì la sì kúrò níbẹ̀ lọ síbòmíì, tá a lo odindi ọdún kan. Arábìnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì sọ bó ṣe rí lára wa lásìkò yẹn, ó ní: “Nígbà tá a wà nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n kọ́ wa pé ká fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará níbikíbi tí ètò Ọlọ́run bá rán wa lọ, a sì ṣe bẹ́ẹ̀. Tó bá wá gba pé ká fi àwọn ará wa sílẹ̀ lọ síbòmíì lásìkò ìṣòro, ọkàn wa máa ń gbọgbẹ́ gan-an!” Àmọ́ inú wa dùn pé a lè wà láwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí Làìbéríà, ká sì máa ran àwọn ará tó wà ní Làìbéríà lọ́wọ́.
Anne: Ní May 1996, àwa mẹ́rin wọ mọ́tò ẹ̀ka ọ́fíìsì, a sì kó àwọn fáìlì pàtàkì kan dání. À ń lọ sí ìlú kan tí ò sí rògbòdìyàn tó fi kìlómítà mẹ́rìndínlógún (16) jìnnà síbi tá a wà. Bí àwọn jàǹdùkú ṣe ya wọ àdúgbò wa nìyẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn sókè. Wọ́n dá mọ́tò wa dúró, wọ́n wọ́ mẹ́ta nínú wa jáde, ó wá ku ọkọ mi nínú mọ́tò, bí wọ́n ṣe wa mọ́tò wa lọ nìyẹn. Àmọ́ àwa mẹ́ta yòókù dúró síbẹ̀, jìnnìjìnnì sì bò wá. Ṣàdédé la rí Paul tó ń rìn pa dà bọ̀ láàárín èrò, orí ẹ̀ sì ń ṣẹ̀jẹ̀. Jìnnìjìnnì tó bò wá jẹ́ ká kọ́kọ́ rò pé wọ́n ti yìnbọn fún un lórí, àmọ́ nígbà tó yá la wá rí i pé tó bá jẹ́ pé wọ́n yìnbọn fún un ni, kò ní máa rìn pa dà bọ̀ wá bá wa! Àṣé ọ̀kan lára àwọn jàǹdùkú yẹn ló ṣe é léṣe nígbà tí wọ́n ń wọ́ ọ jáde nínú mọ́tò. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó kàn rọra ṣèṣe ni, kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.
Ọkọ̀ àwọn sójà kan wà nítòsí wa, àwọn èèyàn kún inú ọkọ̀ náà, ẹ̀rù sì ń ba gbogbo wọn. La bá sáré gán ọkọ̀ náà torí a ò ráyè wọlé. Ẹni tó ń wakọ̀ náà tẹná ẹ̀ débi pé a fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣubú. A bẹ̀ ẹ́ pé kó rọra sáré, àmọ́ ẹ̀rù ń bà á gan-an. Níkẹyìn, ọkọ̀ náà débi tó ń lọ, kò sẹ́nì kankan nínú wa tó jábọ́, àmọ́ ara gbogbo wa ń gbọ̀n.
Paul: Gbogbo ohun tó kù wá kù ò ju aṣọ ọrùn wa tó ti dọ̀tí, tó sì ti ya. A wojú ara wa, ó sì yà wá lẹ́nu pé ẹ̀mí wa ò lọ sí i lọ́jọ́ yẹn. Inú pápá gbalasa kan la sùn lálẹ́ ọjọ́ yẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ hẹlikópítà kan tí ọta ìbọn ti ba ara ẹ̀ jẹ́, ọkọ̀ náà la sì wọ̀ lọ sí Sierra Leone lọ́jọ́ kejì. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó dá ẹ̀mí wa sí, àmọ́ ọkàn wa ò balẹ̀ rárá torí a ò mọ ohun táá ti ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa.
JÈHÓFÀ FÚN WA LÓKUN LÁTI FARA DA ÌṢÒRO TÓ DÉ BÁ WA
Anne: Ayọ̀ àti àlàáfíà la dé Bẹ́tẹ́lì nílùú Freetown ní Sierra Leone, àwọn ará sì tọ́jú wa dáadáa. Àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í rántí àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ ní Làìbéríà. Ojoojúmọ́ lẹ̀rù máa ń bà mí bíi pé nǹkan burúkú fẹ́ ṣẹlẹ̀, ó sì máa ń dà bíi pé àwọn nǹkan burúkú tó ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ni mò ń rí. Tó bá dòru, màá ta jí lójú oorun, òógùn á bò mí, màá sì máa gbọ̀n bíi pé nǹkan burúkú fẹ́ ṣẹlẹ̀. Mi kì í lè mí dáadáa. Ọkọ mi á wá dì mí mú, á sì gbàdúrà pẹ̀lú mi. Àá kọrin Ìjọba Ọlọ́run títí ara mi á fi balẹ̀. Ó máa ń ṣe mí bíi pé orí mi ti fẹ́ yí, bíi pé kí n fi iṣẹ́ mísọ́nnárì sílẹ̀.
Mi ò lè gbàgbé ohun tó wá ṣẹlẹ̀. A rí ìwé ìròyìn méjì gbà lọ́sẹ̀ yẹn. Ọ̀kan nínú ẹ̀ ni Jí! June 8, 1996. Àpilẹ̀kọ kan wà níbẹ̀ tí àkòrí ẹ̀ sọ pé, “Kíkojú Ìkọlù Ìpayà.” Ìgbà yẹn ni ohun tó ń ṣe mí ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé mi dáadáa. Ìwé ìròyìn kejì ni Ilé Ìṣọ́ May 15, 1996, àpilẹ̀kọ kan wà níbẹ̀ tó sọ pé, “Ibo ni Wọ́n Ti Rí Okun Wọn?” Àwòrán labalábá kan tí ìyẹ́ ẹ̀ ti re wà nínú Ilé Ìṣọ́ yẹn. Àpilẹ̀kọ yẹn wá ṣàlàyé pé bí ìyẹ́ labalábá kan bá tiẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ re tán, á ṣì máa fò, á sì máa jẹun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí Jèhófà ṣe máa ń fún àwa náà lókun láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kódà táwọn àjálù kan bá dé bá wa, tó sì mú kọ́kàn wa gbọgbẹ́. Àwọn ìwé yẹn bọ́ sásìkò gan-an, ṣe ni Jèhófà lò ó láti gbé mi ró. (Mát. 24:45) Mo wá àwọn àpilẹ̀kọ míì tó sọ nípa ọ̀rọ̀ náà, mo kó wọn jọ sínú fáìlì kan, ìyẹn sì ràn mí lọ́wọ́. Nígbà tó yá, ìṣòro àìbalẹ̀ ọkàn tí mo ní bẹ̀rẹ̀ sí í pòórá.
JÈHÓFÀ FÚN WA LÓKUN KÁ LÈ GBA IṢẸ́ TUNTUN
Paul: Inú wa máa ń dùn gan-an nígbàkigbà tá a bá pa dà sí Làìbéríà. Nígbà tó fi máa di ìparí
ọdún 2004, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo ogún (20) ọdún níbẹ̀. Ogun ò jà mọ́. Ètò Ọlọ́run ti ń múra àtikọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun. Àmọ́ ṣàdédé ni wọ́n gbé iṣẹ́ tuntun kan fún wa.Àdánwò ìgbàgbọ́ la kà á sí torí pé a ti mọwọ́ àwọn ará tó wà ní Làìbéríà gan-an débi pé wọ́n ti dà bí ọmọ ìyá wa. Kò rọrùn rárá láti fi wọ́n sílẹ̀. Àmọ́ a rántí pé ṣe la fi àwọn mọ̀lẹ́bí wa sílẹ̀ nígbà tá à ń lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó máa bù kún wa. Torí náà, a gbà láti ṣiṣẹ́ tuntun tí ètò Ọlọ́run gbé fún wa. Orílẹ̀-èdè Gánà tí ò jìnnà sí Làìbéríà ni wọ́n rán wa lọ.
Anne: A sunkún, sunkún bá a ṣe ń kúrò ní Làìbéríà. Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tí arákùnrin àgbàlagbà kan tó nírìírí, tó ń jẹ́ Frank sọ pé: “Àfi kẹ́ ẹ gbàgbé àwa o!” Ó wá ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn, ó ní: “A mọ̀ pé ẹ ò ní fẹ́ gbàgbé wa, àmọ́ ẹ gbọ́dọ̀ fi gbogbo ọkàn yín nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tó wà níbi tẹ́ ẹ̀ ń lọ. Jèhófà ló rán yín lọ síbẹ̀, torí náà, ọ̀rọ̀ àwọn ará tó wà níbẹ̀ ni kẹ́ ẹ jẹ́ kó gbà yín lọ́kàn.” Ohun tí arákùnrin yẹn sọ gbé wa ró, ó sì fún wa lókun torí pé àwọn tó mọ̀ wá níbi tá à ń lọ ò tó nǹkan, a ò sì gbébẹ̀ rí.
Paul: Kò pẹ́ rárá tí ara wa fi mọlé lọ́dọ̀ àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Gánà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pọ̀ gan-an níbẹ̀! Ìgbàgbọ́ àwọn ará wa yìí lágbára, ọ̀pọ̀ nǹkan la sì kọ́ lára wọn. Lẹ́yìn tá a lo ọdún mẹ́tàlá (13) ní Gánà, a tún gba iṣẹ́ tuntun tó yà wá lẹ́nu. Ètò Ọlọ́run ní ká lọ máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì East Africa lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àárò àwọn ọ̀rẹ́ wa láwọn ibi tá a ti sìn tẹ́lẹ̀ sọ wá, kò pẹ́ táwa àtàwọn ará ní Kẹ́ńyà fi mọwọ́ ara wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn wà níbẹ̀ tí wọn ò tíì gbọ́ ìwàásù.
OHUN TÁ A KỌ́ LẸ́NU IṢẸ́ ÌSÌN WA
Anne: Oríṣiríṣi ìṣòro tó ń bani lẹ́rù ni mo ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn yìí. A lè ṣàìsàn tàbí ká ní ẹ̀dùn ọkàn nígbà tí nǹkan bá nira tàbí tá a bá wà nínú ewu. Nírú àkókò yìí, Jèhófà lè má ṣiṣẹ́ ìyanu láti gbà wá sílẹ̀. Títí di báyìí, tí mo bá gbọ́ ìró ìbọn, àyà mi á là gààrà, ọwọ́ mi á sì kú tipiri. Àmọ́ mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí n gbára lé Jèhófà pátápátá, kó lè fún mi lókun. Jèhófà sì máa ń lo àwọn ará láti ràn wá lọ́wọ́. Mo ti rí i pé tá a bá ń ṣe àwọn ohun táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àá lè ṣiṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wa.
Paul: Àwọn míì máa ń bi wá pé, “Ṣé ẹ fẹ́ràn ibi tí ètò Ọlọ́run rán yín lọ?” Àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń rẹwà lóòótọ́, àmọ́ rògbòdìyàn lè ṣẹlẹ̀, kí ibẹ̀ sì di ibi eléwu. Àmọ́ nǹkan kan wà tá a máa ń fẹ́ràn ju orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá rán wa lọ. Àwọn ará wa ọ̀wọ́n tó wà níbẹ̀ ni, torí ọmọ ìyá ni wá. Lóòótọ́, ibi tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà yàtọ̀ síra, àmọ́ gbogbo wa la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. A máa ń rò pé bá a ṣe ń lọ síbẹ̀, àwa la máa fún wọn níṣìírí, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ló máa ń fún wa níṣìírí.
Ìfẹ́ tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé máa ń yani lẹ́nu, kò síbi tá a lọ tá ò ti láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó dà bí ọmọ ìyá. Ọmọ ìyá wa ni gbogbo àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó dá wa lójú pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, á máa fún wa lókun.—Fílí. 4:13.
a Wo ìtàn ìgbésí ayé John Charuk nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 1973. Àkòrí ẹ̀ ni “Mo Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Ọlọ́run àti Kristi.”